Deborah Samuel: "Kuran ni aṣáájú Hadith", bí ọ̀rọ̀ bá dàrú, Akeugbagold sọ ohun tí àá padà sí
"Lóótọ́, awọn aayaa igba ogun kan wa ti Hadith wọn sọkalẹ fun awọn Musulumi nigba naa lati ran wọn lọwọ, amọ ogun yẹn ti tan, Hadith ti alafia lo yẹ kẹẹ maa lo bayii".
Gbajumọ oniwaasi nilu Ibadan, Sheikh Akeugbagold n sọ eyi lati da si ọrọ Deborah Samuel ti wọn sọ ni oko pa ti wọn tun dana sun laipẹ yii ni ilu Sokoto.
"Mo ti ṣe waasi kan ninu eyi ti mo ti sọ awọn aaya to pọ lati fi jẹ kawọn eeyan mọ pe ko si ibi ti Ọlọhun ti sọ pe ki wọn sọ eeyan ni oko pa".
O tọka awọn eeyan si apa ibi kan ninu Kuran to ti ni Ọlọhun ni "Anọbi, oo mọọ gbọ ohun ti yoo ba ọ ninu jẹ o, ṣe suuru gẹgẹ bi awọn ti wọn ti lọ si waju ṣe ṣe".
Bakan naa lo tun ka ibomii, to tun ka ibomii, to si tun ka ibomii, to ni "nkankan naa ni Ọlọhun sọ nibẹ pe Anọbi yoo maa gbọ ohun ti yoo ba a ninu jẹ ni.

Oríṣun àwòrán, OTHERS
"Kurani ni 'Primary, Hadith ni Secondary', tọrọ ba daru, Kuran laa pada si"
O ni nkan ti awọn kan n sọ ninu itan pe Anọbi dajọ iku fun arakunrin kan to bu u ri, "ti Anọbi ba ṣe bẹẹ, a jẹ pe Anọbi tako Kuran ni, Anọbi ko si ki n ṣe ika".
O ni ẹnikan ti dojukọ Anọbi ri pe "Were" ni amọ ti Anọbi daa lohun lọna to tọ ninu Kuran.
Akeugbagold ni Islam kii ṣe ẹsin ika ko si si ninu Kuran rara iwa ti awọn kan hu nilu Sokoto.
O ni ki wọn lọ wadi ohun ti Arabinrin Deborah sọ daadaa, iwa ika bii pe awujọ ẹran la n gbe ni wọn hu gbaa.
"Ẹ ma sọ Islam lorukọ ti ko jẹẹ".


