Abuja-Kaduna train: Wo ìdí tí ìrìnà ọkọ̀ ojú irin kò fi ní bẹ̀rẹ̀ báyìí

Reluwe

Oríṣun àwòrán, OTHERS

Ajọ to n boju to eto ileeṣẹ ọkọ oju irin ni Naijiria ti fi aṣẹ sita lọjọ Ẹti pe awọn ti so iwọle igbokegbodo rọ ni ọna oju irin Abuja si Kaduna.

Eyi n waye laarin ohun ti ẹbi awọn to kagbako ijinigbe lọwọ awọn agbesunmọmi n wi.

Ni ọjọ kejidinlọgbọn oṣu Kẹta ni awọn agbebọ lo ohun abugbamu ti wọn ju nibi ọkọ Reluwee naa fi pa arinrinajo mẹsan, wọn ṣe awọn kan leṣe yanayana ti wọn si ji awọn bii aadọta gbe. Nibayii, ajọ NRC ti fagile irina ọkọ Reluwe lọna ọhun eyi ti ko si tii lọjọ ti yoo pari.

Ẹwẹ, ajọ naa ti kede ṣaaju lọsẹ yii pe awọn yoo bẹrẹ iṣẹ nibẹ lọjọ Kẹtalelogun oṣu Karun, eyi ko si ba awọn ẹbi awọn ti wọn ji gbe lara mu rara to bẹẹ ti wọn ni awọn ko ni jẹ ko ṣẹlẹ.

Àkọlé fídíò, 'FUJI níkan ni ‘beat’ tó jẹ́ àṣà wa, ‘Highlife’ kìí ṣe tiwa, kò sóhun tó jọ pé àwọn ọmọ Sàtání ló ń kọ Fuji Gospel'

Amọṣa ninu atẹjade kan ti agbẹnusọ ajọ NRC, Yakub Mahmood sọ, ajọ naa ni wọn yoo kede ọjọ mii laipẹ.

Wọn wa tọrọ aforiji lọwọ awọn araalu fun idaduro to ba iwọle ọkọ oju irin naa to si fi aridaju han fun awọn mọlẹbi naa pe awọn n ṣe iṣẹ kara kara lati rii pe wọn tu awọn eeyan wọn to wa nigbeku ajinigbe silẹ.

"Ajọ NRC yoo maa pawọpọ pẹlu ijọba apapọ ninu igbesẹ aiwẹhinwo rẹ lati daabo bo ọmọ Naijiria, ati ẹmi ati dukia wọn paapaa eyi to ba ti lu mọ ẹka irina oju irin".

Àwọn àgbébọn ti tú olóyún tó wà lára àwọn awakọ̀ reluwé Abuja sí Kaduna tí wọ́n jí gbé sílẹ̀

Inu ọkọ reluwe ti agbebọn bajẹ lati ji ero gbe lọ

Oríṣun àwòrán, Rotimi Amaechi/Twitter

Àwọn àgbébọn to ṣe ikọlu si ọpọlọpọ arinrinajo to wa ninu ọkọ reluwé kan tó n lọ lati Abuja si Kaduna ti tu ọkàn lára wọn ti wọn ji gbe silẹ - obìnrin alaboyun kan ti oyun rẹ ti ga gidi gan ni.

Gẹgẹ bi Akọroyin BBC ṣe jabọ, arábìnrin aboyun náà wá lára àwọn èrò inu ọkọ tí wọn ji gbe nínú Oṣù Kẹta nigba ti awọn àgbébọn ṣe ikọlu si ọkọ reluwé naa to n lọ láti olú ìlú orileede yìí, Abuja lọ sí ìlú Kaduna.

Obìnrin ọhun ṣàlàyé pe awọn àgbébọn náà sọ fún òun pé àwọn dáa silẹ torí awọn kan ṣàánú rẹ ni.

Ẹwẹ, awọn aláṣẹ ni Kaduna ti ni wọn yoo seranwo itọju ìlera rẹ.

Ní oṣù to kọja bakan naa ni wọn tu oludari banki kan silẹ àmọ́ ti iroyin ni lẹyin sísan owo ni.

Àmọ́ṣá, ó ṣì lè ni eeyan ọgọ́ta to ṣi wa ni ahamọ àwọn àgbébọn ọhun.

Lasiko ti wọn ṣe ikọlu náà, wọ́n ju nkan abugbamu si oju ọna ọkọ reluwé naa eyi to mu ki ọkọ naa duro lojiji. Nigba naa ni wọn ṣi iná ìbọn b'olẹ̀ ti wọn si pa o kere tan, eeyan mẹsan.

Ìjọba Naijiria ti da ẹbi ikọlu naa ru ikọ agbesunmomi Boko Haram ti wọn ni wọ́n ń pawọ́ pọ̀ mọ́ àwọn ajinigbe lati maa gba owó lọ́wọ́ àwọn ènìyàn.

Àmọ́ ni ti eleyi, ohun ti wọn n beere fun ni ṣíṣe pasiparọ àwọn tó wà lọ́wọ́ wọn pẹlu awọn ẹlẹ́wọ̀n kan tó wà lọwọ ijoba ìyẹn awọn ọmọ ẹgbẹ́ wọn tó wà latimole Ọlọpaa.