Court sentences Dane who killed his Nigerian wife and daughter: Bí ilé ẹjọ́ ní Eko ṣe dájọ́ ikú fún ọmọ orílẹ̀-èdè Denmark tó pa ìyàwó àti ọmọ wọn

Zainab ati Peter

Oríṣun àwòrán, other

Àkọlé àwòrán, Ile ẹjọ sọ pe Zainab ko mọ pe ọkunrin naa ni iyawo ati ọmọ mẹta si orilẹ-ede abinibi rẹ

Ile ẹjọ giga kan to wa ni gbagede Tafawa Balewa Square nilu eko ti dajọ pe ki wọn o yẹgi fun ọmọ orilẹ-ede Denmark kan, nitori ẹsun pe o pa iyawo rẹ to jẹ ọmọ Naijiria, ati ọmọ rẹ.

Adajọ Bolanle Okikiolu-Ighile to gbe idajọ naa kalẹ ni ọjọ Ẹti, sọ pe Ọgbẹni Peter Nielsen jẹbi ẹsun ipaniyan, ti ijọba ipinlẹ Eko fi kan an.

Ọjọ kẹtala, oṣu Kẹfa, ọdun 2018, ji wọn kọkọ gbe ọkunrin naa lọ si ile ẹjọ, ti wọn si fi ẹsun kan an pe o pa iyawo rẹ to jẹ olorin, Zainab, ati ọmọ wọn obinrin to jẹ ọmọ ọdun mẹta, Petra.

Àkọlé fídíò, 'FUJI níkan ni ‘beat’ tó jẹ́ àṣà wa, ‘Highlife’ kìí ṣe tiwa, kò sóhun tó jọ pé àwọn ọmọ Sàtání ló ń kọ Fuji Gospel'

Ijọba fi ẹsun kan Nielsen pe o pa iyawo ati ọmọ rẹ nipa fifi nkan di wọn ni imu ati ẹnu, titi ẹmi fi bọ lara wọn, ni ọjọ karun-un, oṣu Kẹrin, ọdun 2018.

Iṣẹlẹ naa waye ni oru ọjọ naa ni nkan bi aago mẹrin ku iṣẹju mẹẹdogun, ni ile wọn to wa ni ojule kẹrin, ni Banana Island, Ikoyi.

Bawo ni ile ẹjọ ṣe mọ pe Ọgbẹni Nielsen Peter lo pa iyawo ati ọmọ rẹ?

Zainab

Oríṣun àwòrán, @officializee

Àkọlé àwòrán, Akọrin takasufe ni Zainab , ko to di oloogbe

Bo tilẹ jẹ pe o ni oun ko jẹbi, amọ ninu idajọ naa to waye fun wakati marun-un gbako, Onidajọ Okikiolu-Ighile, sọ pe awọn ẹri fihan to wa lọwọ ile ẹjọ fihan pe oun lo pa wọn.

O ni ẹyọkan lara awọn iṣẹlẹ iwa ipa ninu igbeyawo ni iṣẹlẹ naa.

"Ayẹwo DNA ti a ṣe fihan pe awọn nkankan ti wọn ba ni abẹ eekanna ọwọ Zainab tu aṣiri pe obinrin naa gbiyanju lati gba ẹmi ara rẹ la, to si tun ba ẹran ara olujẹjọ mu.

"Bakan naa ni ẹri fihan ile ẹjọ pe ija kan waye laarin oloogbe ati olujẹjọ naa."

Àkọlé fídíò, Nígbà tí rẹ́kọ́ọ̀dù mí lókìkí kárí ayé, ẹ̀rù bà mí, mo ń ròó pé ọjọ́ ikú mi ti dé ni - Musiliu Haruna Isola

Adajọ tun ṣalaye pe awọn to jẹri ninu igbẹjọ naa sọ pe awọn gbọ ti Zainab n pe orukọ ẹnikan lara awọn ọmọbinrin to n gbe lọdọ tọkọtaya naa, pe ko wa doola oun.

Wọn ni awọn tun gbọ ti o n sọ fun ọkọ rẹ pe ko yẹ foonu oun wo, amọ niṣe lo tubọ n fi nkan gba ni ori.

Lara awọn to jẹri nile ẹjọ ni aburo oloogbe, to jẹ ọmọ ọdun mẹtala lasiko naa.

O sọ fun ile ẹjọ pe ija kan ti kọkọwaye laarin tọkọtaya lọdun 2017, ti ọkọ ẹgbọn oun si dunkooko lati pa oun ti oun ba fi sọ nkan ti oun ri fun ẹnikẹni.

Bayii ni awọn oṣiṣẹ ọgba ẹwọn ṣe gbe Peter Nielsen lọ si ẹwọn lẹyin idajọ

Oríṣun àwòrán, The Punch

Àkọlé àwòrán, Bayii ni awọn oṣiṣẹ ọgba ẹwọn ṣe gbe Peter Nielsen lọ si ẹwọn lẹyin idajọ

Awọn nkan wọn yii ni ile ẹjọ ni o fihan pe olujẹjọ lo pa iyawo ati ọmọ rẹ, paapaa nitori awọn akọsilẹ to wa ni agọ ọlọpaa ni Ikoyi pe ko ṣẹṣẹ ma a lu obinrin naa.

"Obinrin naa ko mọ pe igbeyawo rẹ pẹlu Nielsen, ko fidimulẹ labẹ ofin, nitori pe ọkunrin naa ti fẹ iyawo kan si Denmark, orilẹ-ede abinibi rẹ."

Adajọ dajọ pe ki wọn o so ọkunrin naa rọ̀ ni ọrun rẹ, titi ẹmi yoo fi bọ lara rẹ.