IPOB: Abia ń gbóná jain lọ́wọ́, Kumiyi kò gbọdọ̀ wá ṣe ìpàdé gbàgede tó fẹ́ ṣe!

PASTOR W F KUMUYI

Oríṣun àwòrán, PASTOR W F KUMUYI

Ẹgbẹ to n pe fun ominira ilẹ Biafra, IPOB ti ke si adari Ijọ Deeper Life Bible Church, WF Kumuyi pe ko ma wa ṣe ipade gbagede niluu Abia.

Wọn gba Kumuyi ni imọran pe nitori agbegbe ila oorun Guusu ariwa Naijiria to gbona jainjain ni awọn ṣe gba ni imọran naa.

Ninu atẹjade ti agbẹnusọ ikọ IPOB fi lede, Emma Powerful ni wọn ti sọ pe o ṣeeṣe ki awọn agbebọn ti ko si ẹni to mọ wọn lọ iwọde naa lati fi ṣọṣẹ, ti wọn yoo si dẹbi ru ikọ IPOB.

IPOB rọ awọn adari ẹsin ati pasitọ lati gbadura fun opin si eto aabo to mẹhẹ ni Naijiria.

Bakan naa ki wọn si beere fun idajọ ododo lori iṣekupani Deborah Yakubu, ti awọn kan dana sun lẹyin ti wọn sọ pe o sọ ọrọ odi si Muhammed, to fi mọ Leah Sharibu naa to wa ni ahamọ ikọ agbesunmọmi.

''A gba Pasitọ Kumuyi ti ijọ Deeper Life Bible Church ni imọran lati woye bi eto aabo ṣe ri ni iha Ila Oorun Naijiria bo ṣe fẹ wa ṣe iwaasu ita gbangba.''

Àkọlé fídíò, Nígbà tí rẹ́kọ́ọ̀dù mí lókìkí kárí ayé, ẹ̀rù bà mí, mo ń ròó pé ọjọ́ ikú mi ti dé ni - Musiliu Haruna Isola

"Awọn to n pete pero apẹjọpọ yii gbọdọ ri pe iru nkan bẹẹ ko ṣẹlẹ nitori aabo."

"Nitori naa ni a ṣe gba a nimọran pe ko ma si ipade kankan."

"Iko IPOB ko ni gba ẹnikẹni laaye lati jẹ ki ẹmi awọn eniyan bọ lasiko ipade gbagede naa."

Bakan naa ni wọn kesi Kumuyi lati fi akoko yii gba adura fun opin si ija ati asọ to fi mọ iwa ọdaran ni agbegbe ọhun.

Àkọlé fídíò, Tàá bá lè bá àwọn ọmọ tó pa Deborah ní Sokoto sọ̀rọ̀ pé ìwà ẹranko ni wọ́n hù, ó burú - Òṣèré Sokoti