Al Mustapha kéde èròngbà láti du ipò ààrẹ, wo nkán tó ní òun yóò fojú Boko Haram rí láàrin oṣù mẹ́fà

Oríṣun àwòrán, OfficialHamzaAlMustapha
Ọgagun tẹlẹ ri labẹ ijọba ologun Sani Abacha Hamza Al Mustapha sọ pe bi oun ba di aarẹ Naijiria, oṣu mẹfa pere loun yoo lo lati fi mu opin ba igbesunmọmi Boko Haram.
Al Mustapha sọ pe oun yoo lọ si igbo Sambissa nibi ti Boko Haram sodo si fọsẹ kan lati gbe gbogbo igbesẹ to yẹ nipa mimu opin ba ikọ agbesunmọmi yi.
O fi kun pe bi oun ba di aarẹ, oun yoo mu aṣẹ Ọlọrun ṣẹ ati pe oun ko ni wo oju ẹnikankan nitori oun ko fẹ ki orileede koju inira.
- Abacha àtàwọn ọba àlàyé ló jọ pinnu láti kó owó pamọ́ sókè òkun - Al Mustafa
- Alága ẹgbẹ́ ADP l’Ekiti ní òun kò ṣe ẹgbẹ́ mọ́ ṣáájú ìbò gómìnà l'óṣù Kẹfà
- Kudirat Abiola: Akọni obìnrin tó jẹ́ ọ̀wọ̀n ìrántí fún àyájọ́ ìjọba alágbádá
- Ǹjẹ́ ìwọ mọ Oloye M K O Abiọla dáadáa?
- Ki láwọn olóṣèlú Nàìjíríà rí tí wọ́n fi ń ṣé àbẹ̀wò sí ìyá arúgbó yìí ní Katsina?
Amugbalẹgbẹ ati wọle wọde olori ijọba ologun tẹlẹ Sani Abacha yi fi ọrọ yi lede ninu ifọrọwerọ kan to ṣe pẹlu ileeṣẹ iroyin BBC.
Ninu ifọrọwerọ yi lo ti kede erongba rẹ lati dije dupo aarẹ Naijiria labẹ asia ẹgbẹ oṣelu Action Alliance.
O fi aidunnu rẹ han si bi awọn ọmọ ogun Naijiria ti ṣe ya lẹ ti wọn ko duro wamuwamu mọ.

Oríṣun àwòrán, OfficialHamzaAlMustapha
O sọ pe''Awọn ọmọ ogun Naijiria bi ọga mi ṣe foju wo wọn nigba naa wọn dabi ọlọpaa ni. Awọn ọlọpaa yi si ni wọn fẹran ajẹbanu.''
''Iṣẹ wa ti mo maa ṣe laarin oṣu mẹfa. Bi o ba gbọ nkan taa ṣe, ẹru yoo ba o ṣugbon ododo ọrọ ni''
O ni laarin oṣu mẹfa yi, oun yoo mu ayipada ba ileeṣẹ ologun. O ni o lera nira diẹ ṣugbọn ohun ti eeyan gbọdọ ṣe ni ki ileeṣẹ ologun le pada sipo rẹ.
Ni apẹrẹ lori ọrọ Boko Haram yi, mo maa sọ fun wọn pe bi wọn ko ba fopin si Boko Haram ti wọn si n gba owo,gbogbo awọn ọga ni mo ma yọ kuro wọn o si jabọ owo taa fun wọn''
''Mo maa ṣe iwadii wọn, Laarin oṣu mẹfa mo maa lọ si Sambissa, mo maa koju wọn, mo maa lo ọsẹ kan nibẹ lati mọ boya nkankan le fọwọ kan mi''
Al Mustapha sọ pe asiko tito bayi ki oun darapọ mọ oṣelu. O ni awọn ọrẹ oun kan lo dawojọ gba fọọmu ti wọn si tọka ẹgbẹ ti yoo dije labẹ rẹ.
O ni oun ko lọ sawọn ẹgbẹ oṣelu nla nitori awọn wọnyi lo n ba ilu jẹ.
O ni lati kekere loun ti mọ aarẹ Buhari ṣugbọn awọn to rọyika rẹ jẹ alajẹbanu eeyan.
''Bi o ba gbe awọn aburu ti wọn ṣe lori agbelewọn, o maa ri pe ọjọ n bọ loluwa wi.''
















