Hajia Dada Habi Yar'Adua: Pàtàkì wo láwọn olóṣèlú so mọ́ ṣíṣe àbẹ̀wò sí ìyá ààrẹ tẹ̀lẹ́, Umaru Musa Yar Adua

Aworan awọn oludije to n ṣabẹwo si Hajia Dada

Bi eeyan ba jẹ ẹni to n foju sunukun wo agbo oṣelu Naijiria ko ni ma ṣalai beere pe ki lo de tawọn oludije ipo aarẹ fi n ṣe abẹwo si iya arugbo kan ni ipinlẹ Katsina.

Lootọ a mọ pe bibọwọ fun agba ṣe pataki lawujọ wa amọ ko fẹẹ si obinrin naa ni inu itan oṣelu Naijiria tawọn oloṣelu maa n bọwọ fun bayi.

Ẹni to tun fẹ jọ iya yii ni gbigba ibẹwo awọn oloṣelu nla nla ni iyawo agba oloṣelu ilẹ Yoruba nii, Obafemi Awolowo ṣugbọn Mama Hanna Dideolu ko si laye mọ loni.

Ki wa lorukọ iya naa ati pe ki gaan lo mu ki iya yi ṣe pataki sawọn oloṣelu debi pe ipolongo wọn ko tiii pe ayafi ti wọn ba de ile iya yi.

Àkọlé fídíò, Nígbà tí rẹ́kọ́ọ̀dù mí lókìkí kárí ayé, ẹ̀rù bà mí, mo ń ròó pé ọjọ́ ikú mi ti dé ni - Musiliu Haruna Isola
Àkọlé fídíò, Tàá bá lè bá àwọn ọmọ tó pa Deborah ní Sokoto sọ̀rọ̀ pé ìwà ẹranko ni wọ́n hù, ó burú - Òṣèré Sokoti

Koda wọn tun gbọdo ya aworan tabi fidio ki wọn si polongo rẹ faye pe awọn ṣabẹwo si mama naa.

Ka ma deena pẹnu pupọ, iya taa n wi yi ni Hajia Dada Habi Yar'Adua,ilu Katsina si ni iya wa ni ipinl Katsina

Kini pataki idi tawọn oloṣelu fi n ṣe abẹwo si iya yi ? A beere ọrọ yi lọwọ awọn onwoye nipa ọrọ oṣelu ni Naijiria meji.

Ohun ti wọn ṣe lalaye ree:

Aworan Bukola Saraki ati Hajia Dada

Oríṣun àwòrán, Bukola Saraki

Iwoye ati ẹni taa dara pọ mọ ṣe pataki lagbo oṣelu

Ọjọgbọn Nazif Abdullahi Darma ti fasiti Abuja lorileede Naijriia ni alaye lori ọrọ yi pin si ọna meji.

O ni akọkọ ni pe lawujọ Naijiria,bibọwọ fun agba ṣe pataki ati pe iya taa nwi yi ni ilẹ ariwa jẹ ẹni tawọn eeyan bọwọ fun.

Yatọ si pe o jẹ agbalagba, Darma sọ pe ipo to wa gẹgẹ bi abiyamọ to finu gbe awọn eekan oloṣelu ni Naijiria jẹ nkan tawọn oloṣelu fi n tori rẹ maa ṣabẹwo si.

Aworan Atiku Abubakar ati Hajia Dada

Oríṣun àwòrán, Atiku Abubakar

Yoruba naa ko ko iyan agbalagba kere lawujọ.Yala abẹwo si awọn oriade ni tabi agbaagba il Yoruba iru abẹwo yi naa a maa waye lọdọ wa .

Ṣugbọn Darma ni iya yi lọdọ awọn to n fọkan tẹle oṣelu iha ariwa ṣe pataki botilẹ jẹ wi pe kii paṣẹ dari awn eeytan lori ibo didi.

Aworan Peter Obi ati Hajia Dada

Oríṣun àwòrán, Peter Obi

''Bi mo ṣe ri ọr yi, awọn to fẹ ipo aarẹ maa n wo pe iya yi bi awọn aarẹ ni il ariwa ati pe iru adisọkan oṣelu ti Sheu Musa Yar Adua ni ati Umaru Yare Adua, awn to n tẹle ṣi wa lode oni.''

''Bi eeyan ba wa fẹ itẹwọgba araalu Katsina ati awọn ilẹ miran ni il ariwa, ṣiṣe abẹwo si iya yi a maa mu anfaani wa gẹgẹ bi awọn oloṣelu ṣe gbero''

Aworan Goodluck Jonathan ati Hajia Dada

Oríṣun àwòrán, Google

Alaye to ṣe yi fẹ ẹ fi ara pẹeleyi ti onimọ Abubakar Kari ti ẹka imọ oṣelu ni fasiti Abuja naa ṣe.

Ni tiẹ, Kari ni ko si ẹri kankan to fidi rẹ mulẹ pe ẹni ba ṣabẹwo si iya yi yoo ri ibo awn eeyan ariwa gba.

''Ṣugbọn baa ṣe mọ ọrọ oṣelu si, aworan lasan le mu kawọn eeyan dari ọkan lọ si ọdọ oludije tabi ki wọn si yi kan kuro lọdọ rẹ''

O ni iya naa to ni ni taa bọwọ fun ṣugbọn kii ṣe pe Hajia Dada maa n sọ ibi tawọn oludibo yoo kọri si lasiko ibo.

''A ko le fọwọ rọ iya ṣyin nitori awn eso to jade lara rẹ lapa lorileede Naijiria. Se ti Yar Adua ni ka sọ ni tabi awọn ọmọ ọmọ iya to dipo mu labẹ ijọba?''

Aworan Nyesom Wike ati Hajia Dada

Oríṣun àwòrán, Screenshot/Nyesom Wike

Tani Hajia Yar'Adua

Hajia Aya Dada Yar'Adua, jẹ iyawo, iya iya fawọn ilumọọka oloṣelu lati igun iwọ oorun ariwa Naijiria.

Ọkọ iya yi jẹ Minisita nigba aye rẹ ti eledua si fi awọn eekan ọmọ to jẹ aarẹ ati igba keji aarẹ da mama yi lọla.

Ninu awọn ọmọ rẹ ni Gomina nigba kan ri to tun pada wa di aarẹ Naijiria,Umaru Musa Yar Adua.

Aworan igbakeji aarẹ ati Hajia Dada

Bẹẹ naa ni iya yi tun jẹ mama to bi Sheu Musa Yar Adua igbakeji aarẹ Olusegun Obasanjo laarin ọdun 1979 -1982.

Ninu awọn ọmọ ọmọ iya yi la tun ti ri Murtala Shehu Yar Adua, Minisita labẹ ijọba aarẹ tẹlẹ Goodluck Jonathan.

Ko tan sibẹ ninu awọn ọmọ ọmọ iya yi lobirin la ri awọn iyawo Gomina lawọn ipinlẹ apa ariwa Naijiria.