Yinka Ayefele radio robbed: Ọwọ́ ọlọ́pàá tẹ afurasí tó dárí ikọ̀ tó ja rédíò Ayefele lólè

Yinka Ayefele

Oríṣun àwòrán, Image control

Ọwọ ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Oyo ti tẹ afurasi kan, to jẹ ọmọ ikọ adigunjale kan to kọlu ileeṣẹ redio Yinka Ayefele, Fresh FM, n'ilu Ibadan, ninu oṣù Kẹrin, ọdun 2022.

Ọjọ kẹwàá, oṣu Kẹrin ni awọn adigunjale naa yabo ileeṣẹ redio naa to wa ni agbegbe Challenge, ni idaji kutu, ti wọn si gba awọn dukia lọwọ àwọn òṣìṣẹ́.

Nigba to n jẹwọ ni agọ ọlọpaa, lọjọ Ọjọru, afurasi naa, Ayobami Erinfolami, sọ pe ẹgbẹrun lọna ogun Naira, ni ìpín ti oun gba lara àwọn nkan ti wọn jí.

Àkọlé fídíò, Nígbà tí rẹ́kọ́ọ̀dù mí lókìkí kárí ayé, ẹ̀rù bà mí, mo ń ròó pé ọjọ́ ikú mi ti dé ni - Musiliu Haruna Isola

Nibi ti kọmisanna ọlọpaa nipinlẹ Oyo, CP Ngozi Onadeko, ti fi oju rẹ han ni olu ileeṣẹ ọlọpaa to wa ni Eleyele, ni Erinfolami ti jẹwọ pe oun gba owo naa lẹyin ti àwọn tun lọ jalè ni ileewosan aladani kan ni adugbo Ring Road.

Kọmisanna ọlọpaa sọ pe "ni nkan bi aago mọkanla alẹ́, ni ọjọ kẹwàá oṣù Kẹrin, ni awọn ọdaran kan to ma n ja ile itura, ileewosan, ati awọn ibi ti eero ba pọ si lole, yabo Fresh FM, Challenge, n'ilu Ibadan.

"Wọn fi agidi wọ yàrá igbohunsafẹfẹ ileeṣẹ redio naa, wọn si fi ìbọn gba ọpọlọpọ owo, foonu olowo iyebiye, kọmputa agbeletan (laptop) ti wọn fi n gbohunsafẹfẹ, lọwọ awọn òṣìṣẹ́ ti wọn ba ni ẹnu isẹ."

Àkọlé fídíò, Tàá bá lè bá àwọn ọmọ tó pa Deborah ní Sokoto sọ̀rọ̀ pé ìwà ẹranko ni wọ́n hù, ó burú - Òṣèré Sokoti

CP Onadeko sọ pe iwadii n lọ lọwọ, ni iru idigunjale naa tun waye ni awọn ile itura kan n'ilu Ibadan.

"Bakan naa, lọjọ kẹrinlelelogun, oṣu Kẹrin, ọdun 2022, ni wọn yabo ileewosan Delight Hospital and Fertility Centre, ni Ring Road, ti wọn si ja awọn alaisan, ẹbi wọn, ati awọn òṣìṣẹ́ lole."

Àmọ́ iwadii ọlọpaa ṣe atọna bi ọwọ ṣe tẹ olori ikọ adigunjale naa, nibi to farapamọ si.

Kọmisanna ọlọpaa ṣalaye pe afurasi naa, Erinfolami, jẹwọ pe lootọ ni awọn ṣe ikọlu naa.

O ni iwadii ṣi n lọ, lati le mu àwọn ìyókù rẹ to ti salọ bayii.

Àkọlé fídíò, Wọ́n gbé Póò ìtọ̀ àti igbẹ́’ tó ti já nídìí lé mi lórí lọ dànù l’Eko, pẹ̀lú òúnjẹ́ mi lọ́wọ́ mi - Ajirebi