Deborah Samuel: Mo mọ̀ dájú pé kò sí ẹ̀sín tó fàyè gba ìpànìyàn lọ̀nà àìtọ̀ - Kayode Ajuolo gba ìjọba nímọ̀ràn

Kayode Ajulo

Oríṣun àwòrán, OTHERS

Agbẹjọro ọmọ Naijiria, Kayode Ajulo ti ni ko si ofin to kọja ofin orilẹede ti eeyan ba wa.

O n sọ eyi ni idahun si idi ti ẹgbẹ awọn agbẹjọro, NBA ṣe ni o yẹ ki ijọba apapọ ati ijọba ipinlẹ tara ṣaṣa si eto idajọ awọn to ṣekupa Deborah Samuel ni Sokoto.

O ni eyi ni yoo kọ awọn eeyan ni ẹkọ to yẹ ki wọn mọ lawujọ dipo bi ijọba ṣe n fi ọrọ naa falẹ.

"Ko si ẹsin to faye gba ipaniyan lọna aitọ bi wọn ṣe pa akẹkọbinrin Deborah ni ilu Sokoto".

Ajulọ to sọrọ lasiko to n ba BBC News Yoruba sọrọ ni iṣẹlẹ naa ko ba oju mu.

''Ati pe bi wọn ṣe pa obinrin naa ko ba ofin mu ati wi pe o da mi loju pe ko si ẹsin kankan to fayegba pipa ẹnikẹni ni ọna aitọ.''

Àkọlé fídíò, Tàá bá lè bá àwọn ọmọ tó pa Deborah ní Sokoto sọ̀rọ̀ pé ìwà ẹranko ni wọ́n hù, ó burú - Òṣèré Sokoti

''Ohun ti mo gbagbọ nipe ko si ẹsin kankan ni agbaye tabi ni Naijiria to fayegba ki wọn pa ẹnikẹni lọna aitọ eleyii ti wọn n pe ni ''extrajudicial killing''.

''Ohun to bani ninu jẹ patapata ni iṣẹlẹ to waye naa ti mo si faramọ bi ẹgbẹ awọn agbẹjọro ni Naijiria ṣe bu ẹnu atẹ lu iṣẹlẹ naa''

Bakan naa lo fikun un pe ẹgbẹ awọn agbẹjọro naa, NBA ti jẹ ki ijọba mọ pe iṣẹlẹ naa ko ba ofin mu.

Ẹgbẹ awọn agbẹjọro mọ iṣẹ wọn ni iṣẹ, ti wọn si ti kesi ijọba pe ki ijọba ki o gbe igbesẹ akin lori iṣẹlẹ naa.

Àkọlé fídíò, Wọ́n gbé Póò ìtọ̀ àti igbẹ́’ tó ti já nídìí lé mi lórí lọ dànù l’Eko, pẹ̀lú òúnjẹ́ mi lọ́wọ́ mi - Ajirebi

Kini ọna abayọ si iṣekupani Deborah ni Sokoto?

Agbẹjọro ni Naijiria, Kayode Ajulo ni ọna abayọ si iṣẹlẹ yii ni ki idajọ ododo jọba ki awọn eniyan le ni igbagbọ ninu ijọba ati eto idajọ.

Ajulọ ni gbogbo eniyan ni iṣẹlẹ naa ba wi nitori eto ijiya fun ẹṣẹ gbọdọ wa ni Naijiria.

O ni awọn ọmọ Naijiria gbọdọ kọ lati maa ṣe idajọ ni ọwọ ara wọn, ki awọn eniyan le kọ ẹkọ pe ẹlẹṣẹ ko gbọdọ lọ lai jiya ni abẹ ofin.

O fikun un pe Naijiria nilo eto idajọ to daju ki iru iṣẹlẹ bayii maṣe waye mọ.

Àkọlé fídíò, Títí ayé yóò fi parẹ́, wọ́n ó máa sọ̀rọ̀ sí Ànọ́bì ni, wọ́n ó sì máa bú Jésù ni, ẹ wá gbọ́ òótọ́ ohun tí Quaran sọ – Akeugbagold