Ajirebi Oluwakayode Olasehinde: Mo ru pọnpọ́n lára àwọn tó kọ́ 'Secretariat' ìlú Ilorin, ojú mi rí tó kí n tó wọ Tíátà
"Awọn ọrẹ mi ti maa n pe mi ka jọ lọ darapọ mọ awọn elere Tiata amọ mo maa n kọjalẹ".
Gbajugbaja ati agba oṣere, Oluwakayode Olasehinde ti ọpọlọpọ mọ si Ajirebi tabi Pa James ninu ọpọlọpọ ere to ti ṣe gba alejo BBC Yoruba eyi to si jẹ manigbagbe eto.
O kuro ni keremi lootọ ohun ti oju agba oṣere yii ri laye nigba to kẹnu bọ ọrọ pẹlu wa.
Ọmọ ilu Patako ni Ajirebi ni ijọba ibilẹ Ifelodun ni ipinlẹ Kwara.
O ṣalaye bo ṣe jẹ pe ilu Eko ni wọn bii si to si bẹrẹ si ni ṣe kekere amọ ninu irinajo ẹkọ rẹ fẹ jọ pe ko lọ deede mọ, awọn obi rẹ ni ko pada si ilu wọn ni ipinlẹ Kwara lati lọ tẹsiwaju ninu ẹkọ rẹ amọ itan tun yipada.
"Mo padà sílé ní Kwara láti Eko, mi ò tún eí ìwé kà mọ́ torí owó, mò ń tọ́jú aláìsàn títí tí mo ṣe sá kuro fúnra mi"