Olamiju Alao-Akala: Mo ṣì máa ń wo fóònù mi bíì pé bàbá mi Akala fẹ́ pe mi, gbogbo ǹkan ni mo fi ṣàárò wọn

Àkọlé fídíò, 'Ọ̀pọ̀ ìgbà l'èmí gan fẹ́ du àwọn ipò òṣèlú kan, bíì '2015, 2019' àmọ́ mo tẹ 'slow' torí bàbà mi, Akala náà ń jáde'

"Owo ti ọmọde ba kọkọ ri, ẹpa ni yoo fi ra jẹ, lootọ awọn ọrẹ kan wa ti yoo gba eeyan nimọran odi ti eeyan yoo si tẹle e".

BBC Yoruba ni ifọrọwerọ pẹlu ọmọ gbajugbaja oloṣelu to tun jẹ gomina ipinlẹ Oyo tẹlẹ ri, Adebayo Alao Akala.

Olamiju Akala kẹnu bọ ọpọ ọrọ lati ṣalaye irinajo oṣelu rẹ nigba ti baba rẹ wa laye, awọn idiwọ to koju, ati bo ṣe n baa yi lẹyin iku baba rẹ to jẹ bii ẹni to fẹyin ti ju nigba aye rẹ.