Deborah Samuel: Gani Adams tutọ́ sókè fojú gbàá lórí ìtàjẹ̀sílẹ̀ arábìnrin Deborah ní Sokoto, ohun tó sọ rèé

Aarẹ Ọna Kakanfo Ilẹ Yoruba patapata Iba Gani Adams ti dasi ọrọ iṣekupani arabinrin Deborah Samuel toi waye ni ipinlẹ Sokoto.
Gani Adams sọ pe awọn to ṣeku pa arabinrin naa n gbero lati da ogun ẹlẹyamẹya ati ẹlẹsinmẹsin silẹ ni ilẹ Yoruba ni.
O fi ọrọ yi sita gba tọwọ agbẹnusọ rẹ Kehinde Aderemi lọjọ Aiku to kọja yi.
Ninu atẹjade naa, Iba Adams ni ''ọrọ ti doju rẹ bayi ni Naijiria ati pe ti wọn ko ba wa nkan ṣe si, o le di wahala ti ipa ko ni le ka''
O kilọ pe agbegbe awọn ti gburo pe awọn alaburu kan ti n wọle si ilẹ Yoruba pẹlu erongba ki wọn dana sun ilẹ Yoruba.
O ni awọn ko ni faaye gba ipete peero wọn nitori o ṣeeṣe ki o da wahala ẹlẹsin ati ẹlẹyamẹya silẹ laarin awọn eeyan.
- Láti ìgbà tí wọ́n ti bí mi, kò sí obìnrin tí mo kọnu ìfẹ́ sí tí kò gbà fún mi -Efuoma Amos
- Àwọn ọlọ́kadà dáná sun 'Sound engineer' l'Eko lẹ́yìn àríyànjiyàn lórí ₦100
- Wo àwon ìròyìn òfégè nípa ikú Deborah Ṣamuel àti ìkọlù sí Bishop Kukah
- Àwọn Mùsùlùmí tó ṣekúpa Deborah nítori ọ̀rọ̀ ẹ̀sìn kò ní wọ párádísè - Sheikh Gumi
- Kò sí ohun tó jọọ́! A kò gbọdọ̀ rí ìwọ́de kánkan tó bá lọ́wọ́ ẹ̀sìn nínú ní Kaduna- Gómìnà
''Awọn alakatakiti ẹsin yi ni ibi ti wọn fọkan si.Ireti wọn si ni pe ki wọn da wahala silẹ ni apa iwọ oorun Guusu wa, ṣugbọn a ko ni faaye gba wọn''
O bẹnu atẹ lu isọwọ bi wọn ṣe pa arabinrin Deborah Samuel ni ipakupa to si ni awọn agbofinro tete mu awọn to wa nidi iku rẹ ki wọn si foju wina ofin ni kiakia.
Aarẹ Ọna Kakanfo ilẹ Yoruba sọ pe ko pẹ yi lawọn agbarijọpọ eleto aabo ni Ilẹ Yoruba lọgun sita lori bi awọn ajoji ti kii ṣe ọmọ Naijiria ṣe yawọ ilẹ Yoruba.
O ni awọn ke gbajare nitori pupọ awọn wọnyi lo maa n gbe ọbẹ ati nkan ija oloro mii rin kaakiri ati pe wọn ṣetan lati ṣaburu fawọn eeyan.
O tẹnu mọ pe iṣẹlẹ iṣekupani Deborah yi ṣafihan aibikita awọn alakatakiti yi.
''Wọn dawọ jọ na, wọn ṣe leṣe,wọn lu debi iku wọn si dana sun lalae kaanu rẹ''Iba Adams wa parọwa si Gomina ipinlẹ Sokoto Aminu Waziri Tambuwal lati daabo bo gbogbo araalu.
O ni ko ṣa gbogbo ipa rẹ lati ri pe ọwọ tẹ awọn to wa nidi iṣẹlẹ yi to fi mọ awọn alatilẹyin wọn.
''Ofin wa nilẹ yi to fidi idaabo araalu kọọkan mulẹ a si gbọdọ bọwọ fun iru ofin yi.Ẹnikẹni to ba tako ofin yi gbọdọ foju wina ofin ni''

















