Sokoto Blasphemy Killing: Wo ìdí tí ìjọba Kaduna fi fòfin de ìwọ́de èyíkéyìí tó bá lọ́wọ́ ẹ̀sìn nínú ní ìpínlẹ̀ wọn

Oríṣun àwòrán, Facebook/nasirelrufai
Ijọba ipinlẹ Kaduna ti kede pe awọn ko ni faaye gba iwọde kankan to ba lọwọ ẹsin ninu ni ipinlẹ naa
Agbẹnusọ Gomina Nasir El Rufia Samuel Aruwan lo fi ọrọ yi sita ninu atẹjade kan.
O ni awọn gbe igbesẹ yi lẹyinti awọn se ijiroro pẹlu awọn agbofinro ni ipinlẹ naa labẹ aṣẹ igbimọ alaabo ijọba Kaduna.
- Ìjọ Kátólìkì ní Sokoto fèsì sí ikọlù s'àwon ilé ìjósìn,wo ohun tí Kukah sọ
- Ìjọba Sokoto kéde òfin kóníléógbélé lẹ́yìn ìfẹ̀hónúhàn lórí bí ọlọ́pàá mú àwọn tó pa Deborah Samuel
- Ìtàn àkọ̀ròyìn Al Jazeera tí wón pa ní Israel rè é
- Bóo bá ma ń la ẹnu kalẹ̀ lójú oorun, wo ìpèníjà tí o lè ní
- Àwọ̀n ènìyàn rò pé wèrè, ajínigbé ni mí, àmọ́ mo ti kọ́ ilé janturu, fẹ́ ìyàwó mẹ́sàn àn , bí ọmọ 35 – Alfa to n ṣa irin ni atan
Aruwan tẹsiwaju pe ẹnikẹni to ba bọ sita se iwọde yala ni atilẹyin tabi ni itako nkan to n sẹlẹ ni ipinlẹ kan lapa kan orileede Naijiria yoo jẹ iyan rẹ niṣu.
Apa orileede Naijiria ati iṣẹlẹ to n mẹnu ba yi ni ipinlẹ Sokoto nibi ti awọn ọdọ musulumi kan ti dana sun akẹkọbirin Kristẹni akẹgbẹ wọn lori ẹsun pe o sọrọ odi si Anọbi Muhammad.
''Aṣẹ yi di dandan nitori kurukẹrẹ tawọn alaburu kan ti bẹrẹ si ni ṣe lati korajọ ṣe iwọde ni itako ati ni atilẹyin si nkan to ṣẹlẹ ni ọ́kan ninu awọn ipinlẹ ilẹ Ariwa Naijiria''
''Wọn ti fi ọrọ yi to Gomina El Rufaileti to si ti ni kawọn agbofinro ri pe wọn tẹle aṣẹ ma jade si iwọde to ni ọwọ ẹsin ninu yi ni ipinlẹ Kaduna.''
Ninu awọn ipinlẹ ti o n koju wahala ẹlẹsinmẹsin ati ẹlẹyamẹya ni ipinlẹ Kaduna wa ni Naijiria.
Bi wahala ba si bẹ silẹ ni Kaduna ohun to sunmọ ni ki o tan kaakiri de awọn ipinlẹ miran ti eleyi si le da rugudu silẹ ni Naijiria.

Ọrọ to ba jọ mọ ẹsin tabi ẹya jẹ nkan to mumu lọkan awọn eeyan ni Naijiria ni paapa lawọn ilẹ Ariwa ti ija musulumi ati awọn Kristẹni kii so eso rere.
Iṣẹlẹ to waye yi jẹ ọkan ti yoo jẹ bi idanwo fawọn alaṣẹ lati le mọ bi wn yoo se petu si eyikeyi aawọ tole tẹyin rẹ wa.












