Video of student burnt in sokoto: Ìjọba Sokoto kéde òfin kóníléógbélé lẹ́yìn ìfẹ̀hónúhàn tó wáyé níbẹ̀

Sokoto

Oríṣun àwòrán, Imam Abubakar

Ijọba ipinlẹ Sokoto ti kede ofin konile-o-gbele oni wakati mẹrinlelogun lẹyin ti ogunlọgọ awọn Musulumi gunle ifẹhonuhan lọjọ Satide.

Awọn olufẹhonuhan naa n bere pe ki ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ ọhun tu awọn afurasi meji ti wọn fi ṣikun mu lori iku akẹkọọ ti wọn ṣekupa lẹyin ti wọn sọ pe o sọrọ abuku nipa ẹsin Islam silẹ.

Awọn olufẹhonuhan ọhun, ti okunrin, obinrin atawọn ọmọde wa lara wọn kan lu igboro, wọn dana sun taya, wọn tun ba ọpọ ṣọọbu jẹ.

Lara awọn eeyan naa tun korajọ siwaju ọọfisi ijọba ipinlẹ ọhun.

Awọn ti ọrọ naa ṣoju wọn sọ pe awọn ọlọpaa yin gaasi tajutaju si awọn oluwọde ọhun lọna ati tu wọn ka, nibi ti eeyan meji ti farapa lara wọn.

Ijọba ipinlẹ ọhun ti wa da awọn ọmọ ogun si igboro bayii lọna ati le mu ki awọn olufẹhonuhan naa tẹlẹ aṣẹ konile-o-gbele to pa.

Oṣojumikoro tun sọ pe awọn olufẹhonuhan naa ya bo aafin Sultan ilu Sokoto, lẹyin to bu ẹnu atẹ bi wọn ṣe ge ẹmi oloogbe naa, Deborah Samuel, kuru.

Ọpọ awọn ọmọ Naijiria lo ti bu ẹnu atẹ lu bi wọn ṣe ṣekupa akẹkọọ naa.

Lara awọn to bu ẹnu atẹ lu iṣẹlẹ ọhun ni ọmọlẹyin Kristi ati Musulumi wa.

Ki lo ti ṣẹlẹ ṣeyin?

Ìfẹ́hónúhàn bẹ́ sílẹ̀ ní Sokoto lórí bí ọlọ́pàá ṣe mú àwọn to pa Deborah Samuel

Sokoto

Oríṣun àwòrán, Murtala ST

Ifẹhonuhan ti bẹrẹ niluu Sokoto lori bi ileeṣẹ ọlọpaaa ṣe fi ṣikun ofin mu awọn afurasi to dana sun akẹkọọ ti wọn ni o sọrọ odi si anọbi Muhammad.

Awọn olufẹhonuhan naa ni awọn n fẹ ki ileeṣẹ ọlọpaa Sokoto tu awọn meji ti wọn fi satimọle lori iku akẹkọọ naa silẹ.

Ṣaaju ni awọn akẹkọọ kan ti kọkọ gbẹmi akẹkọọ naa, Deborah Samuel, to jẹ akẹkọọ ile ẹkọ Shehu Shagari College of Education, lẹyin ti wọn ni o sọrọ abuku nipa Anọbi.

Awọn olufẹhonuhan kọlu aafin Sultan Sokoto

Awọn ọdọ naa, ti okunrin ati obinrin wa ninu wọn, ti bẹrẹ si n sun taya laarin igboro, bẹẹ naa ni wọn kọlu aafin Emir Sokoto, Alhaji Sa'ad Abubakar kẹta.

Bẹẹ naa ni wọn tun korajọ siwaju ile ijọba ipinlẹ ọhun.

Nigba ti ileeṣẹ iroyin BBC kan si ileeṣẹ ọlọpaa Sokoto, wọn kọ lati sọ ohunkohun lori iṣẹlẹ ọhun.

Iroyin ni, ifẹhonuhan naa kọkọ n lọ ni pẹlẹkutu ko to di iṣu ata yan-yan ti wọn si bẹrẹ si n sọ okuta niwaju aafin Sultan.

Àkọlé fídíò, Mothers day: Lẹ́yìn Olorun, Ìyá mi ló kù- Papa Ajasco, Abiodun Ayeyinka

Ẹnikan ti ọrọ naa ṣoju rẹ lagbegbe aafin Sultan naa ṣalaye fun BBC pe awọn agbofinro ko jẹ ki awọn olufẹhonuhan naa wọ inu aafin Sultan.

O ni "Awọn olufẹhonuhan n binu si Sultan lori pe o ṣatilẹyin fun ọmọ ti wọn ṣekupa."

O fi kun pe awọn ọlọpaa atawọn ọmọ ogun yin gaasi tajutaju si awọn olufẹhonuhan ọhun lati fi tu wọn ka, wọn si ti yinbọn pa meji ninu wọn.

Àkọlé fídíò, Alaafin stool: Wo ẹni tó ṣeẹṣe pé kí Aláàfin kàn lẹ́yìn ìpapòdà Oba Lamidi Adeyemi

Oṣojumi koro naa sọ siwaju si pe awọn ọlọpaa atawọn eeyan naa ṣi n kọju ija si ara wọn lasiko ti a n ko iroyin yii jọ.

Gẹgẹ bii ohun to sọ,, awọn ọlọpaa tun fi ṣikun ofin mu diẹ lara awọn eeyan naa.

Ti ẹ ko ba gbabe, ọjọbọ ni ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Sokoto sọ ni u atẹjade kan pe ọwọ awọn ti tẹ meji ninu awọn eeyan to ṣekupa Deborah.

Àkọlé fídíò, Agbẹjọ́rò Abdullateef Lanre Abdullahi sọ pàtàkì ìbálòpọ̀ àti ìmọ́tótó láàrin lọ́kọláya