Aláàfin of Oyo's Palace Administration: Àwọn nǹkan tí o kò mọ̀ nípa ààfin ìlú Oyo nìyí

Ààfin ìlú Oyo

Oríṣun àwòrán, Screenshot

Báyìí ni à ń ṣe ní ilé wa èèwọ̀ ibòmíràn.

Ní ilẹ̀ Yorùbá, ohun gbogbo ló ní ètò àti ọ̀nà tí wọ́n ń gbà ṣe ètò inú ilé àti ọ̀dẹ̀dẹ̀ tí èyí kò sì yọ ààfin ìlú Oyo sílẹ̀.

Ní Ààfin ìlú Oyo, òjò tàbí oòrùn kìí pa Aláàfin nítorí wọ́n ti ṣètò ibi tí Ọba Aláàfin yóò máa gbà tí oòrùn tàbí òjò kò fi ní kàn án lára.

Aláàfin nìkan ló ní àǹfàní láti gba ọ̀nà yìí gẹ́gẹ́ bí ọ̀rọ̀ Ọba Adeyemi kẹta nígbà tí Baba ń bẹ lókè eèpẹ̀.

Ní Ààfin, Aláàfin nìkan ni àǹfàní wà fún láti wọ bàtà tí ẹnikẹ́ni kò sì gbọdọ̀ gbìyànjú láti tàpá sí òfin yìí.

Àkọlé fídíò, Alaafin stool: Wo ẹni tó ṣeẹṣe pé kí Aláàfin kàn lẹ́yìn ìpapòdà Oba Lamidi Adeyemi

Bí àjòjì tàbí ẹnikẹ́ni bá gbìyànjú láti ṣe bí Aláàfin, tó fẹ́ yọ bàtà wọ̀, àwọn ẹ̀ṣọ́ ti wà ní sẹpẹ́ láti fi póró òfin gbé ẹni náà nítorí kò sí bí ènìyàn ṣe fẹ́ ṣe bẹ́ẹ̀ tí àwọn ẹ̀ṣọ́ náà kò ní mọ̀.

Bákan náà ní àwọn ènìyàn tó máa ń wà ní Ààfin ní ìgbà kan kìí dín ní ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀ta (500) tí gbogbo wọn sì ní ojúṣe kan tàbí òmíràn tí wọ́n ń ṣe nínú ààfin.

Àkọlé fídíò, Èmi nìkan ni ikú Alaafin dùn jù ní gbogbo ayé yìí torí èmi nìkàn ṣoṣo ni mo mọ̀ ǹkan ... - Baba Kekere

Ọba Adeyemi ní gbogbo àwọn olorì tó wà ní Ààfin kọ́ ni ó jẹ́ aya tí ọba fẹ́ fúnra rẹ̀ nítorí àwọn tí Ọba jogún nígbà tí ọba kan bá gbésẹ̀ wà nínú ààfin.

Àwọn ìyàwó tí Aláàfin bá mú wá, nǹkan tí wọ́n ń ṣe ní ààfin, wọn kò ní mọ̀, àwọn ni wọn yóò máa kọ́ àwọn ìyàwó wọ̀nyẹn ní ẹ̀kọ́; báwo ni a ṣe ń tọ́jú Aláàfin àti oúnjẹ rẹ̀?

Àkọlé fídíò, Ó yẹ kí a wádìí ikú tó pa Oba Lamidi Adeyemi, Baba gbọ́dọ̀ padà- Sat Guru Maharaj-ji

Ìyá Ilé Orí ní láti wà, Ìyá Káà Ọba, Ìyá Ayé Kalẹ̀, Ìyá Kòlárá, Ìyá Kòlárá Kékeré, Káà ọ̀dẹ̀.

Kòlárá Kékeré ni wọ́n ti ń gún iyán, gbogbo ẹni tó bá wà ní ààfin kò gbọ́dọ̀ lọ sí ìta ra nǹkan.

Àkọlé fídíò, Agbẹjọ́rò Abdullateef Lanre Abdullahi sọ pàtàkì ìbálòpọ̀ àti ìmọ́tótó láàrin lọ́kọláya

Ẹni tí ó máa gùn iyán ọ̀sán tí wà ní ààfin.

Káà Ilé Ẹyẹ wà, ibi tí wọ́n tí ń bọ̀ orí Aláàfin wà, ilé Ṣàngó wà.

Ìyàrá kan wà, ibẹ̀ ni wọ́n máa ń kó gbogbo adé sí, iná gbọ́dọ̀ wá níbẹ̀ ni gbogbo ìgbà.

Moyọ̀ àti Àlàbá ni máa ń tọ́jú adé, ìlẹ̀kẹ̀ tí Aláàfin máa fi sì ọwọ́, lọ́dọ̀ wọn ló wà, wọ́n níláti ṣe nńkan sí i.

"Ìlẹ̀kẹ̀ ti ọrùn náà kò gbọ́dọ̀ wà lọ́dọ̀ Aláàfin, Kò sí adé lọ́dọ̀ mi, kò sí ìlẹ̀kẹ̀ lọ́dọ̀ mi."

Àkọlé fídíò, Ó gbé owó fún mi, ó tún ra fóònù ńlá fún mi - Bàbá Onílù Ibadan sọ bó ṣe pàde Àgùnbánirọ̀ tó dáa lọ́lá

Àwọn ìyá méjì ló máa ń pín iṣẹ́ àti ètò ṣe ní ààfin, olorì àgbà tó wà ní ìkápá gbogbo àwọn ọmọ àti àwọn olorì yòókù.

Ẹnìkejì ni Iya Naso tó wà ní ìkápá ètò tó ní ṣe pẹ̀lú Sango àti gbogbo àwọn òṣìṣẹ́ àwọn ààfin yòókù.

Àkọlé fídíò, 'Mo fara da ìsòro gan láwùjọ́ torí àwọn òbí mi di létí'