Body odour solution: Wo ǹkan tó ń fa 'body odour' àti bí o ṣè lè ṣẹ́gun rẹ̀

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Àwọn onimọ sọ pe ọpọ eeyan lo gbagbọ pe òógùn lo ma n mu ki ara rùn, sugbọn otitọ to wa nibẹ ni pe óògùn ara eniyan kii rùn rara.
Oorun ti ko dara ma n wa lati àwọn ẹ̀yà ara bi ẹnu ati awọn ẹ̀yà mii.
Ṣùgbọ́n ninu akọsilẹ yii, awọn òórùn to n jade lati awọ ara ni yoo jẹ afojusun wa.
Ati bi kokoro aifojuri ṣe ma n jẹyọ ninu óògùn eniyan.
- Àsìkò ti tó kí ìjọba fihàn pé kò sẹ́ni tó kọjá òfin lórí ikú Deborah- Ẹgbẹ́ Mususlumi ní Nàìjíríà
- Ẹ̀rọ ayàwòrán CCTV ṣe àkọsílẹ̀ bí àwọn ọmọ ogun Russia ṣe pa aráàlú méjì ní Ukraine
- Ṣé lóòótọ́ ní pé arábìnrin tó ní ìbálòpọ̀ pẹ̀lú ajá tí pàdánù ẹ̀mí rẹ̀?
- Ngige kọrin tuntun mi ò díje dupò aàrẹ Nàìjíríà mọ́, mo ti padà sí ọ́ọ́fíìsì mínístá tí mo wà tẹ́lẹ̀
- Orí ìpìlẹ̀ àṣeyọrí Buhari ni máa mọ lé tí mo bá fi di Ààrẹ - Fayemi
- "Ọlọ́pàá ní kí n bọra sílẹ láti mọ bóyá obìnrin ní mí torí mo ní irùngbọ̀n"
- Wo bí wọ́n ṣe ń ṣètò ìṣàkóso ní Alaàfin ìlú Oyo bóyá aáàfin wà láyé tàbí o ti papòdà
- Osinbajo,Tinubu àti àwọn míì tó ṣetán láti kojú ìgbìmọ̀ àyẹwò APC réè lẹyìn tí wọn fí fọ́ọ̀mù ṣọ̀wọ̀
Àwọn nkan to ma n fa òórùn ti ko dara 'body odour' ninu ara:
Iwe iroyin imọ iṣegun oyinbo, British Medical News Today, sọ pe oorun yii ma n bẹ̀rẹ̀ lasiko ti eeyan ba ṣẹṣẹ n bàlágà, paapaa nitori awọn ayipada to n ba àwọn ẹ̀yà ara.
Yatọ si eyi, o ṣe e ṣe ki awọn eeyan to sanra jù ati awọn to ni aisan bi itọ ṣuga ní oorun ti ko dara ninu ara wọn.
Oorun buruku ma n jade ni ara nigba ti awọn kokoro aifojuri ba n la orisirisi ipele kọja, lati darí pinpin eroja PROTEIN to wa ninu òógùn, nibi ti o ti n ri oúnjẹ.
Dokita Abubakar Mohammed, ti ileewosan Specialist Hospital, Maiduguri, sọ pe àwọn kokoro aifojuri to n gbe nibi to ba tutu ninu ara lo n fa ki òórùn buruku ma jade, kii ṣe óògùn fúnra rẹ.
Idi ree ti awọn to ma n làá gùn pupọ ṣe ma n ni 'body odour'.
Dokita Mohammed tun sọ pe jíjẹ awọn oúnjẹ bii galiiki, alubosa ati ata, le mu ki eeyan laagun ju bó ṣe yẹ.
Bi o ṣe le dena ati ọna abayọ si 'body odour'
Ọ̀pọ̀ eeyan ma n ni iriri 'body odour' ni àwọn ẹ̀yà ara wọn ti aṣọ bá bò - eyi to ma n fa óògùn ati ki aṣọ tutu.
Dokita Abubakar sọ pe ọkan gboogi lara nkan to n fa "body odour" nìyẹn.

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Lati dena rẹ, awọn ọna ti awọn onímọ̀ ilera sọ ree:
- Wiwẹ pẹlu omi to mọ ati ọṣẹ oloorun didun. Ki eeyan si fọ awọn ibi to le run bii ẹnu, abiya ati abẹ́ daadaa.
- Wiwọ aṣọ to mọ- nitori ko si bi eeyan ṣe le wẹ̀ tó, ara rẹ yoo rùn to ba wọ aṣọ to dọti. Paapaa aṣọ bi awọtẹlẹ, pátá, ibọsẹ, sikẹẹti, kọmu ati aṣọ olooru.
- Fifa irun ara - Ti irun ba kún ni àwọn ibi kan ninu ara, yoo fa óògùn, eyi to má n pada fi ààyè gba kokoro aifojuri to n fa òórùn buburu ninu ara.
Nitori naa lo ṣe yẹ ki o fa irun ni awọn ẹ̀yà ara kan, lati le dena rẹ.
- Lilo lọfinda - Lilo lọfinda loore-koore, ṣe pataki ninu igbesẹ didena oorun buburu.
Yatọ si awọn nkan ti dokita sọ, o tun le lo àwọn nkan bí omi orombo wẹ́wẹ́ (lemon) lati fi òpin si oorun buburu ninu ara rẹ. Fi omi orombo naa pa awọn ibi to ba n run, saaju ki o to wẹ.
O tun le fi alọọmu sinu omi iwẹ rẹ, to ba jẹ pe oorun ara rẹ pọ.
Ṣùgbọ́n ti o ba ṣe gbogbo nkan wọn yii, ti oorun naa ko ba dinku tabi lọ patapata, tete lọ ri dokita.
Idi ni pe ki eeyan ma laagun ju, ati ki oorun buruku ma jade ninu ara, le jẹ ami aisan bi itọ ṣuga, aisan kíndìnrín, ati bẹẹ bẹẹ lọ.


















