Abdulmumin Jibrin dumps Tinubu Campaign: Lẹ́yìn ọ̀pọ̀lọ̀pọ̀ ọ̀rọ̀ tó bá mi sọ lórí fóònù láti rọ̀ mi padà, ohun tí mo ṣe rèé

Jibrin ati Tinubu

Oríṣun àwòrán, Jibrin's Facebook

Eekan apolongo idibo fun oloye ẹgbẹ oṣelu All Progressive Congress, Asiwaju Bola Tinubu iyẹn Abdulmumin Jibrin ti iroyin rẹ gbode kan lẹnu ọjọ diẹ sẹyin pe o ja Tinubu ju silẹ gẹgẹ bi adari ipolongo ti jade wa sọ ohun to ri lọbẹ to fi waro ọwọ.

Ninu ọrọ kan to fi sita lọjọ Abamẹta, Jibrin sọ pe ko si ṣiṣe ko saiṣe, afi koun ṣaa fi ipolongo fun Tinubu silẹ ni lẹyin ti oun ti kuro ni ẹgbẹ oṣelu APC lọ si ẹgbẹ oṣelu New Nigeria People's Party eyi ti gomina ipinlẹ Kano tẹlẹ to tun jẹ oludije fun ipo aarẹ ni NNPP, Rabiu Kwankwaso n dari.

Ki lo mu tirela gba aarin Jibrin ati APC?

Abdulmumin Jibrin

Oríṣun àwòrán, Abdulmumin Jibrin

Ọmọ ile igbimọ aṣoju-ṣofin tẹlẹri yii ti wa sọ pe kii ṣe pe wahala kankan ṣẹlẹ laarin oun ati Tinubu o bi ko ṣe pe Gomina Abdullahi Ganduje ti ipinlẹ Kano ni oun n ba fa wahala.

Àkọlé fídíò, Títí ayé yóò fi parẹ́, wọ́n ó máa sọ̀rọ̀ sí Ànọ́bì ni, wọ́n ó sì máa bú Jésù ni, ẹ wá gbọ́ òótọ́ ohun tí Quaran sọ – Akeugbagold

Ninu ọrọ rẹ, Jibrin ṣalaye bi igbe aye oṣelu rẹ ṣe n foju wina iṣoro nla lati ọdun meje sẹyin to si ni ko ni ipa rere kankan koda to fi di pe iṣẹ ti oun ti n to fun gbogbo aye oun fẹrẹ sunmọ oko ibajẹ gbaa.

"Ibanujẹ ati ijakulẹ to kun inu dun meje sẹyin ninu iṣẹ oṣelu mii rọ mọ eeyan kan yii to ti pinu lati ba aye ẹnikẹni ti oju rẹ ba ti la pe wọn fọwọ rọ oun sẹyin jẹ. Lootọ o lee dabi ọrẹ to fẹni loju amọ oun n ṣe awọn eeyan rẹ yii ni ibi bii awọn alawọdudu ti iya jẹ ni apa ibi kan lorilẹede South Africa".

Abdulmumin Jibrin

Oríṣun àwòrán, Abdulmmin Jibrin

Mo ko gbogbo ifarajin mi le ifẹ arakunrin yii, ṣugbọn gbogbo igba ni kii to o. Nkan naa di ohun itiju gan ni ti mo ni lati tadi mẹhin ronu bi mo ṣe le tun ara mi ṣe. Iyatọ wa laarin sinsin awọn eeyan fun didara ati wiwa ki awọ́n eeyan maa bọ ẹ bii Ọlọrun. A o gbudọ laye da ifarajin pọ mọ ṣiṣe ẹ.

Gbogbo eleyi jẹ gẹgẹ bi iwe iroyin Punch ṣe gbe e jade lọjọ Abamẹta. Jibrin tun sọ siwaju nipa bo ṣe ni Gomina Abdullahi mu oun la ironu ọpọlọ kọja titi ti oun fi ni lati yẹba kuro ninu awọn ipinu oun fun oṣelu to si ni ko ya oun lẹnu pe gbogbo awọn to n sasugbaa rẹ ninu oṣelu ti n fii silẹ lọ.

Àkọlé fídíò, Mothers day: Lẹ́yìn Olorun, Ìyá mi ló kù- Papa Ajasco, Abiodun Ayeyinka

"Nigba to gbiyanju ati pe mi pada sinu ẹgbẹ lori foonu lọjọ diẹ sẹyin ti a sọrọ fun ọpọlọpọ akoko, mo beere ibeere kan lọwọ rẹ lati ru ọrọ soke lori iwa ibajẹ rẹ si bibanilọkan jẹ, mo bii pe 'gẹgẹ bii baba, ṣe o lee jẹ ki awọn mii huwa si awọn ọmọ rẹ ni ọna ti o n huwa si awa asugbaa rẹ ninu oṣelu atawọn amugbalẹgbẹ rẹ. Nigba ti akoko ba to, mo pinu lati ṣi aṣọ lẹkunrẹrẹ loju aburu arakunrin yii". O fi kun un.

'Oun ti kikuro ni ẹgbẹ APC tumọ si niyi'

Abdulmumin Jibrin

Oríṣun àwòrán, Jibrin's Facebook

Ẹwẹ, o tẹsiwaju pe "kikuro ni ẹgbẹ oṣelu APC fun mi naa tumọ si pe mo gbudọ kuro ninu ikọ ipolongo Alhaji Bola Ahmed Tinubu. Ohun to ṣe pataki ni pe ko si eeyan kan pato to jẹ ko ṣee ma ni ti iyọkuro rẹ yoo pa ipolongo idibo Asiwaju lara, Ihamọra nla ni ipolongo Tinubu gbe wọ ti wọn si ṣeto rẹ lati bori ni koda lai si emi nibẹ.

Lori ifarajin ati gbogbo akitiyan ti ikọ naa ti dokoowo rẹ sinu erongba Asiwaju, Asiwaju funra rẹ gan ko le da iponlongo rẹ duro ka ma wa sọ Abdulmumin Jibrin".

O wa ni oun n rọ gbogbo araalu lati ma gbe oun gẹ gẹ gẹ ju bo ti yẹ lọ ati pataki oun ninu ikọ naa ki wọn si yee gbe iroyin ofege kiri toun ti gbogbo fabu ti wọn pa kiri lori ọrọ yii.

"Lootọ mo ni iyi gidi amọ ko lee mu ohunkohun kuro ninu aato ti mo ri to wa fun ìpolongo BAT.

'Ifẹ ti Asiwaju ni fun mi ko lẹgbẹ'

Abdulmumin Jibrin

Oríṣun àwòrán, Abdulmumin Jibrin

"Fun awọn to n ṣe iye meji, ẹ jẹ ki n tun fi yee yin pe mi o ni ìṣòro kankan pẹlu Asiwaju. A o figba kankan ni ìṣòro ri. Ìṣòro temi jẹ abẹ́nú to si ni ṣe pẹlu òṣèlú.

Asiwaju fi ifẹ rẹ han si mi o si fun mi ni aaye lati kopa bi mo ṣe fẹ ninu ipolongo rẹ bẹẹ si ni bi mo ṣe kúrò nínú ẹgbẹ́ APC ko din ọwọ ti mo ni fun un ku àti igbagbọ mi nínú ipa rẹ láti mu ayipada ba Naijiria".

Ó tún ṣàlàyé pé Asiwaju ṣe akitiyan ki oun ma fi ẹgbẹ́ silẹ. O ni "kii ṣe tori pe yoo pa ìpolongo rẹ lara àmọ́ tori ifẹ òtítọ́ to ni si mi".

O ni Asiwaju ṣe akitiyan to yẹ lati da si ọrọ ki oun ma kuro lẹgbẹ wọn amọ "Ọkunrin to wa nidi ki iṣẹ ire mi bajẹni mo ro ero pe ki n sa fun nitori abo ipo oṣelu mi. Mi o le fara da aburu si mi mo si fẹ lo asiko yii lati tọrọ aforijin lọwọ gbogbo ẹbi BAT jakejado Naijiria fun gbogbo idojuti ti mo ba ko ba wọn pẹlu iru pajawiri ti mo kuro ninu ẹgbẹ APC.

Mo ti lọ ba Asiwaju lati tọrọ aforijin, yoo si tẹsiwaju lati jẹ baba fun mi, ile rẹ si jẹ ile mi".