Èyí ni díẹ̀ lára ìgbà tí Buhari àti àwọn aṣòfin gbéná wojú ara wọn

Buhari, Dogara ati Saraki

Oríṣun àwòrán, Getty Images/Yakubu Dogara

Lọjọ Iṣẹgun ni Aarẹ Muhammadu Buhari sọ pe oun ko ni ibaṣepọ to dara pẹlu ile aṣofin ikẹjọ l'orilẹede Naijiria.

Buhari sọ ọrọ naa lasiko ti oun ati awọn olori ile aṣofin naa, Bukọka Saraki ati Yakubu Dogara ṣinu aawẹ pẹlu rẹ nile ijọba l'Abuja.

Aarẹ sọ pe aigbọra ẹni ye to waye lọpọ igba laarin iṣejọba oun ati awọn aṣofin naa ṣe idiwọ fun awọn anfaani to yẹ ki awọn ọmọ Naijiria jẹ.

Buhari ati awọn olori ile aṣofin

Oríṣun àwòrán, Bashir Ahmad

Àkọlé àwòrán, Aarẹ Buhari sọ pe oun ko ni ibaṣepọ to dara pẹlu ile aṣofin labẹ Saraki ati Dogara lasiko to ṣinu aawẹ pẹlu awọn olori ile aṣofin

Eyi lo mu ki a fẹ ṣe agbeyẹwo diẹ lara awọn igba ti Aarẹ Buhari ati awọn ọmọ ile aṣofin ti jọ gbena woju ara wọn ri

Amin iyasọtọ kan

Ofẹ ẹ jẹ wi pe lati ibẹrẹ ile aṣofin kẹjọ ni aarin awọn ọmọ ile aṣofin apaọ mejeeji ati ẹka iṣakoso, paapa, aarẹ Muhammadu Buhari ko ti gún.

A le sọ pe wahala naa bẹrẹ lati ọjọ ti wọn ti yan awọn olori ile aṣofin naa. Ti ẹ ko ba gbagbe, lọjọ ti eto idibo naa waye, ọtọ ni awọn ti ẹgbẹ oṣelu All Progressives Congress to jẹ ẹgbẹ to wa ni iṣakoso, ati ẹgbẹ to ni aṣofin ju n ile fi ọwọ si.

Amọ ṣa, niṣe ni Bukọla Saraki ati Yakubu Dogara ati awọn ọmọ ẹgbẹ oṣelu PDP gba 'ọna ẹburu' lati ṣeto idibo naa laisi awọn ọmọ ẹgbẹ APC nile, botilẹjẹ pe ọmọ ẹgbẹ naa ni awọn naa jẹ.

Awọn alaṣẹ ẹgbẹ oṣelu APC pe ipade fun awọn aṣofin to jẹ ọmọ ẹgbẹ wọn lati jiroro lori bi wọn yooo ṣe yan awọn olori ile aṣofin, ti awọn ọmọ ẹgbẹ PDP si lo anfaani naa lati sẹto idibo.

Amin iyasọtọ kan

'Budget Padding'

Igba miran tun ni asiko ti Aarẹ Buhari atawọn aṣofin kọlu ara wọn ni lori aba owo iṣuna ọdun 2016.

Ohun to kọkọ ṣẹlẹ si aba owo iṣuna naa ti Aarẹ Buhari gbe lọ siwaju apapọ ile aṣofin mejeeji lọjọ kejilelogun, oṣu Kejila ọdun 2015 ni pe, ile aṣofin agba sọ pe iwe àbá naa di awati nigba ti wọn pada de lẹnu isinmi ọdun loṣu Kinni ọdun 2017.

Olori ile aṣofin naa, Bukọla Saraki fi ẹsun kan oluranlọwọ fun Buhari lori ọrọ ile aṣofin, Ita Enang pe oun lo ji iwe owo iṣuna ọhun, to si fi omiran rọpo rẹ.

Botilẹ jẹ pe ile igbimọ aṣoju-ṣofin sọ pe ẹdà iwe naa to wa lọwọ oun ko sọnu, oriṣi aba owo iṣuna meji lo wa nita.

Eyi mu ki aarẹ Buhari kọ lati buwọlu u, nitori bi awọn ileeṣẹ ijọba ṣe kọ owo iṣuna wọn pe wọn ti ṣe mago-mago rẹ.

Lẹyin gbogbo wahala naa ni alaga igbimọ to ṣagbeyẹwo owo iṣuna naa nile igbimọ aṣoju-ṣofin, Abdulmumin Jibrin tu aṣiri ọrọ sita pe lootọ ni ile igbimọ aṣoju-ṣofin ṣe mago-mago owo iṣuna naa.

Ọrọ yii da wahala sil laarin aarẹ Buhari ati awọn aṣofin, eyi to mu ki owo iṣuna naa o pẹ ki wsn to fọwọ si i.

Iroyin to jade ni pe awọn aṣofin naa yọ awọn akanṣe iṣẹ kan kuro lara awọn eyi ti ẹka alaṣẹ fẹ ẹ ṣe, ti wọn si fi awọn miran ti ileesẹ aarẹ ko ni lọkan lati ṣe.

Amin iyasọtọ kan

Bakan naa lọdun 2016, ile aṣofin agba kọ aba aarẹ Buhari lati ya owo to le ni biliọnu mọkanlelọgbọn Dọla ($29.9) lati ilẹ okeere.

Ẹwẹ, awọn aṣofin naa tun kọ lati fi ọwọ si yiyan Ibrahim Magu gẹgẹ bi alaga ajọ to n gbogun ti iwa ibajẹ, EFCC, ti wọn fi ẹsun kan pe 'oniwa ibajẹ ni.'

Titi di asiko yii, ipo adele alaga ajọ EFCCC ṣi ni Ibrahim Magu wa, ile aṣofin ko fọwọ si iyansipo rẹ bi alaga, eyi ti inu awọn aṣofin ko dun si i.

Ọpọlọpọ iyannisipo ti Buhari fẹ ẹ ṣe ni awọn aṣofin naa ko buwọlu, ti awọn miran si pẹ pupọ ki wọn to o fọwọ si i.

Amin iyasọtọ kan

Ẹwẹ, awọn aṣofin pariwo le Aarẹ Muhammadu Buhari lori lasiko to gbe aba owo iṣuna ọdun 2019 lọ siwaju apapọ ile aṣofin mejeeji lọjọ kọkandinlogun, oṣu Kejila ọdun 2018.

Buhari ni ile aṣofin apapọ

Oríṣun àwòrán, Ahmad Bashir

Àkọlé àwòrán, Diẹ lara awọn to ti ba irufẹ itiju ati ariwo idẹyẹsi bayii pade ni Donald Trump, Theresa May, Jacob Zuma ati George Bush

Bi aarẹ Buhari ṣe n ṣe alaye awọn ohun to wa ninu aba owo iṣuna naa, ati awọn aṣeyọri ti iṣakoso rẹ ti ṣe, ni awọn aṣofin kan n da ọrọ mọ ọ lẹnu, ti wọn si n ho le lori.

Ihuwasi awọn ọmọ ẹgbẹ alatako yii si fa ede aiyede laarin wọn ati awọn ọmọ ẹgbẹ oṣelu APC.

Kosi aba owo iṣuna ti Aarẹ Muhammadu Buhari gbe lọ siwaju awọn aṣofin ti ko mu rogbodiyan dani.

Lori awọn ọpọ nkan to ṣẹlẹ yii ni oun ni ireti pe oun yoo ni ajọṣepọ to dara pẹlu awọn aṣofin to n bọ.