Ohun tó wáyé tẹ́lẹ̀ ti lọ, ìfẹsẹ̀wọnsẹ̀ Tanzania ni mò gbájúmọ́ báyìí – Eric Chelle, Akọ́nimọọ̀ọ́gbá Super Eagles

Akọnimọọgba ikọ ẹgbẹ agbabọọlu Super Eagles, ilẹ Naijiria, Eric Chelle, ti sọ pe ohun pataki to jẹ oun logun lasiko yii ni pe ki ikọ Super Eagles bori awọn akẹgbẹ wọn lati orilẹede Tanzania, ninu ifẹsẹwọnsẹ akọkọ fun idije AFCON to bẹrẹ lorilẹede Morocco.
Chelle sọ eyi nigba to n da hun ibeere BBC ni ilu Fes lorilẹede Morocco, pe ohun to se koko fun oun lọwọ yii ni aṣeyori Super Eagles ninu ifẹsẹwọnsẹ pẹlu orilẹede Tanzania.
O ni ohun to sẹlẹ ṣaaju jẹ ohun ti oun ko ni akoko lati pada sibẹ mọ ṣugbọn oun gbajumọ ohun to n sẹlẹ lọwọ bayii.
"Lẹyin idije yii, a ṣe ipade lẹẹkan si ṣugbọn asiko yii ki n ṣe asiko lati sọrọ nipa bi a ṣe padanu ninu idije ife ẹyẹ agbaye ati ifẹsẹwọnsẹ to kọja rara. Ohun to ṣe koko bayii ni ifẹsẹwọnsẹ to n bọ."
Isori ẹlẹkẹta jẹ isọri ti orilẹede Naijiria, Tanzania, Uganda ati Tunisia wa.
Igba keje ree ti ikọ Super Eagles Niajiria yoo ma koju orilẹede Tanzania, to si jẹ pe wọn ko fi igba kankan lulẹ ninu awọn ifẹsẹwọnsẹ to ti kọja.
Chelle tun wọgile ọrọ kan to n lọ kiri pe aseyọri ninu idije ni yoo sọ boya yoo tẹsiwaju gẹgẹ bii Akọnimọọgba Super Eagles.
awọn oṣiṣẹ mi.
"Lẹyin idije AFCON, mo maa ni ipade pẹlu awọn ajọ ere bọọlu Naijiria lati sọrọ nipa rẹ ṣugbọn asiko yii kọ ni mo ma sọrọ nipa iyẹn.
"Ifẹsẹwọnsẹ akọkọ yii ṣe koko fun wa lati le ni ọjọ ọla rere, lati le fi agbara wa han si araye."
Chelle ni oun ni ọpọlọpọ igbagbọ ninu awọn agbabọọlu ti oun ko wa sinu idije AFCON yii bo ti lẹ jẹ pe oun ko ni anfani lati ransẹ pe awọn kan ti wọn farapa lasiko ti wọn gba bọọlu.
Ni itẹsiwaju alaye rẹ, Chelle sọ pe :
"Lọwọ ti mo wa yii, ohun ti mo gbajumọ ju ni awọn agbabọọlu mi, ifẹsẹwọnsẹ ọla ati awọn oṣiṣẹ mi.
Jijẹ Balogun tuntun fun Super Eagles ko ba mi lẹru rara- Wilfred Ndidi

Jijẹ Balogun tuntun fun Super Eagles ko ba mi lẹru rara- Ndidi
Bakan naa ni Balogun tuntun fun Ikọ Super Eagles, Wilfred Ndidi ni ẹru ko ba oun rara lori ipo to ṣẹṣẹ gba lati jẹ balogun fun ikọ Super Eagles nitori oun ni ọpọ awọn agba ọjẹ miiran ninu ikọ Super Eagles to n ran oun lọwọ.
"Ko si ẹru fun mi rara, mo ti wa nibi tiẹ, ti mo si kọ lọwọ Balogun tẹlẹ fun ikọ Super Eagles, William Troost-Ekong
"A kọ ọpọlọpọ ẹkọ ninu idije AFCON to kọja ṣugbọn a fi itan balẹ bo ti lẹ jẹ a ko ni anfani lati gba ifẹ ẹyẹ naa.
"A ni ọpọlọpọ igbagbọ ninu ara wa pe a ni ohun to yẹ lati ṣe aṣeyọri nla ninu idije yii.
"A rọ awọn ololufẹ wa lati wa sibi idije lati wa jẹ igbadun rara wọn nitori ifẹsẹwọnsẹ nla ni yoo jẹ.
Igbaradi Super Eagles fun ifẹsẹwọnsẹ pẹlu Tanzania
Ikanni BBC News Yoruba lọ sibi paapa iṣere ti ikọ Super Eagles ti n gbaradi, ti a si ba ọpọ awọn agbabọọlu naa sọrọ lori wọn sẹ n gbaradi fun ifẹsẹwọnsẹ naa
Lara awọn ti a fi oju gan ni paapa isere naa ni Balogun tuntun, Wilfred Ndidi, Victor Osihmen, Moses Simon, Dele Basiru, Ebenezer Akinsanmi, Alex Iwobi ati bẹẹ bẹ lọ.
Deede ago mẹfa ni ọjọ Isẹgun ni ifẹsẹwọnsẹ naa yoo waye pẹlu orilẹede Tanzania ni ilu Fes.














