Sound engineer lynched: Láìpẹ́ yìí la ó gbè àwọn afurasí lọ sílé ẹjọ́ - Iléeṣẹ́ ọlọ́pàá ìpínlẹ̀ Eko

Oríṣun àwòrán, Screenshot
Iléeṣẹ́ ólọ́pàá ìpínlẹ̀ Eko ní àwọn ti nawọ́ gán àwọn afurasí mẹ́fà tí wọ́n lọ́wọ́ nínú ikú arákùnrin, David Sunday tó jẹ́ Sound Engineer tí àwọn kan ṣekúpa ní agbègbè Lekki ní bí ọjọ́ mélòó sẹ́yìn.
Kọmíṣọ́nà ọlọ́pàá ìpínlẹ̀ Eko, Abiodun Alabi, nígbà tó ń fojú àwọn afurasí náà hàn ní David pàdé ọlọ́jọ́ rẹ̀ nígbà tí wọ́n pè é láti wá dá sí ìjà tó bẹ́ sílẹ̀ láàárín àwọn afurasí náà tó jẹ́ ọlọ́kadà àti àwọn èrò méjì tó gbé.
Alabi ṣàlàyé pé lọ́jọ́ kejìlá, oṣù karùn-ún, ní nǹkan bí aago mẹ́fà àbọ̀ ìrọ̀lẹ́, ní agbègbè Lekki ni ọlọ́kadà kan tí orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Dahiru ní gbólóhùn asọ̀ pẹ̀lú àwọn èrò rẹ̀ méjì Frank Olatunji àti Philip Balogun lórí iye tí wọ́n yóò san fún ọ̀kadà.
- Àwọn ọlọ́kadà dáná sun 'Sound engineer' l'Eko lẹ́yìn àríyànjiyàn lórí ₦100
- Ìjọba Eko fún àwọn ọlọ́jà Alaba Rago ní gbèdéke láti fi ibẹ̀ sílẹ̀ fún àtúnṣe
- Àwọn òṣìṣẹ́ DSS gbìyànjú láti dóòlà Deborah, àmọ́ ọ̀pọ̀ èèrò borí wọn - Gómìnà Tambuwal
- Ọmọ orílẹ̀-èdè Denmark pa ìyàwó rẹ̀ ọmọ Naijiria àti ọmọ wọn l'Eko, ìjọba dájọ́ ikú nípa yíyẹgi fún un
- Látilẹ̀ ni mo ti fẹ́ràn orin ìjọ Kérúbù àmọ́ ẹlẹ́sìn mùsùlùmí àti krìstẹ́nì ni mí - Qdot
- A kò fẹ́ kí Kumuyi wá ṣe ìsọjí ìta gbangba nílùú Abia – IPOB
- Mo ti ṣetán láti gba ìjọba lọ́wọ́ Makinde lọ́dún 2023 - Adebayo Adelabu
- Lẹ́yìn wákàtí díẹ̀ tí wọ́n sin òkú n'Ibadan, àwọn afurasí olóogùn owó gé orí rẹ̀ lọ
- "Láti àkókò yìí lọ, àwọn obìnrin gbọ́dọ̀ máa bo ojú wọn lórí tẹlifíṣọ̀nù"
- A kò fi ti gbèdéke June 1 ṣe, a ti fòfin de ọ̀kadà, kèké ní Eko
"Bí gbólóhùn asọ̀ náà ṣe ń le ni wọ́n pe David láti báwọn dá sí ọ̀rọ̀ náà ṣùgbọ́n ọ̀rọ̀ bẹ́yìn yọ nígbà tí Dahiru àti àwọn ẹmẹ̀wà rẹ̀ kojú oro sí David tí wọ́n sì lù ú pa kí wọ́n tó dáná sun-ún."
Bákan náà ló fi kun pé àwọn afurasí mẹ́fà tí ọwọ́ àwọn ti tẹ̀ ni Dahiru Ayuba, Susan Moses, Christopher Dauda, Joseph Tella Chigozie Anthony àti Sunday Azi.
Ó fi kun pé láì pẹ́ ni àwọn yóò tarí àwọn afurasí náà sílé ẹjọ́ ní kété tí àwọn báti parí ìwádìí àwọn.

Oríṣun àwòrán, Other
Àwọn ọlọ́kadà dáná sun 'Sound engineer' l'Eko lẹ́yìn àríyànjiyàn lórí ₦100
Ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Eko ti fi ṣikun ofin mu awọn eeyan kan ti wọn ṣekupa okunrin kan to ṣiṣẹ ohun elo orin niluu Eko ti orukọ rẹ n jẹ David.
Gẹgẹ bii ohun ti a mọ, awọn mẹta ni awọn eeyan dawọjọ lati lu nilu bara amọ David nikan lo ba iṣẹlẹ naa lọ nigba ti awọn akẹgbẹ rẹ moribọ, bo tilẹ jẹ wọn farapa yanayana.
Ṣaaju ni ni fidio bi awọn eeyan ṣe dawọjọ lu awọn eeyan naa ti kọkọ milẹ titi lori ayelujara, fidio ọhun tun ṣafihan bi wọn ṣe dana sun ọkan lara wọn, iyẹn David.
- Kà nípa àwọn mínísítà mẹ́wàá tó kọ̀wé fipò sílẹ̀ lábẹ ìjọba Ààrẹ Buhari
- Wo àwon ìròyìn òfégè nípa ikú Deborah Ṣamuel àti ìkọlù sí Bishop Kukah
- Tọkọtaya gbé ọmọ wọn lọ sílé ẹjọ́ torí àì bímọ lẹ́yìn ìgbéyàwó
- Àwọn àgbébọn ti tú olóyún tó wà lára àwọn awakọ̀ reluwé Abuja sí Kaduna tí wọ́n jí gbé sílẹ̀
- Bóo bá ma ń la ẹnu kalẹ̀ lójú oorun, wo ìpèníjà tí o lè ní
- Kò sí ohun tó jọọ́! A kò gbọdọ̀ rí ìwọ́de kánkan tó bá lọ́wọ́ ẹ̀sìn nínú ní Kaduna- Gómìnà
- Ìjọ Kátólìkì ní Sokoto fèsì sí ikọlù s'àwon ilé ìjósìn,wo ohun tí Kukah sọ
- Mo ti túbá lọ́wọ́ Asiwaju, àmọ́ ìdí gaan tí mo fi kọ̀wé fipo sílẹ̀ gẹ́gẹ́ bí adarí ìpolongo ìbò Tinubu rèé
Wahala naa bẹrẹ laarin awọn ọdọkunrin ọhun atawọn ọlọkada kan lori ariyanjiyan ọgọrun naira pere.
Agbẹnusọ ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Eko, Benjamin Hundeyin ni ọwọ awọn ti tẹ eeyan mẹrin ti wọn funra si pe wọn lọwọ ninu isẹlẹ naa.
Ki ni ohun to ṣelẹ gan?
Ọjọ kejila, oṣu Karun un, ọdun 2022 yi ni isẹlẹ naa waye lagbegbe Admiralty, ni Lekki, nilu Eko.
Timothy, to jẹ ọrẹ awọn eeyan naa, ti ọrọ naa ṣoju rẹ ṣalaye fun BBC pe ariyanjiyan ọgọrun naira owo ọkada lo mu iṣelẹ naa waye.
Gẹgẹ bii ohun to sọ, o ni "Awọn ọre mi fẹ lọ ṣere lalẹ ọjọ naa ni, nitori ibi meji ni wọn ti fẹ lọ ṣere, wọn gbe igbesẹ lati gun ọkada ki irin naa le ya."
"Nigba ti wọn de ọkan lara ibi ti wọn n lọ ni ariyanjiyan bẹ silẹ laarin Philip ati ọkan lara awọn ọlọkada to gbe wọn nitori ọgọrun naira to owo ọkọ, eyii lo mu ko fun ọkan lara awọn ọlọkada naa ni ikuku, ti ọlọkada ọhun si ṣubu lulẹ."
"Ọlọkada keji to gbe Frank to jẹ ẹnikeji ba ke gbajare pe Philip ti fi oogun abẹnu gọngọ gba ọrẹ oun lo jẹ ko ṣubu lulẹ, ka to wi ka to fọ, awọn ọlọkada ẹgbẹ rẹ ti pe jọ ti wọn si bẹrẹ si n na Philip ati Frank ti wọn jẹ ọrẹ mi."
"Enikẹta wọn to jẹ David ti wọ inu gbọgan ti wọn ti fẹ ṣere naa lọ, amọ ariwo to n gbọ lo mu ko sare jade si wọn, bo ṣe jade bayii naa ni wọn tun bẹrẹ si n lu oun naa."
'Wọn dana sun David lẹyin ti wọn na tan'
Fidio ti ileeṣẹ ọlọpaa ṣi n ṣayẹwo rẹ lọwọ yii ko sọ iye awọn to lọwọ ninu iṣẹlẹ laabi naa.
Amọ fidio ọhun ṣafihan David nilẹ, ti wọn ti gbe taya si lọrun.
Fidio naa tun ṣafihan bi okunrin kan ṣe n da nnkan to fara jọ epo bẹntiro si ara David ki wọn ṣana si.
Ki ni ọlọpaa sọ?
Ẹwẹ, Benjamin Hundeyin to n gbẹnusọ fun ileesẹ ọlọpaa l'Eko ti sọ pe iṣẹlẹ naa iba buru ju bẹẹ lọ amọ ọlọpaa tete pana rẹ.
O ni awọn mẹrin ti wa ahamọ awọn fun ipa ti wọn ko ninu iṣẹlẹ naa.
O ni "A ni ireti pe a mu awọn to ku to lọwọ ninu iṣẹlẹ naa laipẹ, paapaa okunrin to wa ninu fidio to n da epo bẹntiro si David lara."
"Okunrin yẹn gan ni a n wa bayii, a gbọ pe o n ṣowo lagbegbe ti iṣẹlẹ naa ti waye amọ ko tii yọju sibẹ lati igba ti iṣẹlẹe ọhun ti waye."
























