Domestic Violence: Ẹ dákun, ẹ má jẹ́ kí ọkọ mi fi lílù pamí - Ìyàwó kan rawọ́ ẹ̀bẹ̀ sí ilé ẹjọ́

Oríṣun àwòrán, Pixabay
Arábìnrin kan tí orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Uju Onyekachi ti rawọ́ ẹ̀bẹ̀ sí ilé ẹjọ́ ìbílẹ̀ kan tó wà ní ìpínlẹ̀ Eko láti tú ìgbéyàwó òun àti ọkọ òun Jude ká nítorí ìbẹ̀rù pé kí ó má lu òun pa.
Ọjọ́ Ìṣẹ́gun, ọjọ́ kẹtàdínlógún, oṣù karùn-ún ni Onyekachi sọ fún ilé ẹjọ́ wí pé gbogbo ìgbà ni ọkọ òun máa ń lu òun bí aṣọ òfì.
"Ẹ̀rù àwọn ìròyìn bí ọkọ ṣe ń lu ìyàwó wọn dójú ikú tó ń fi ojoojúmọ́ gbòde lẹ́nu ọjọ́ mẹ́ta yìí kò fi mí lọ́kàn balẹ̀, mi ò fẹ́ kí èmi náà parí rẹ̀ síbẹ̀."
- Ènìyàn mẹ́rin pàdánù ẹ̀mí wọn níbi ìbúgbàmù tó wáyé ní Kano
- Ẹ kò gbọdọ̀ mu igbó àti sìgá lẹ́nu iṣẹ́ mọ́ – Makinde kìlọ̀ fáwọn ọmọ ẹgbẹ́ onímọ́tò
- Fásitì fọwọ́ òsì júwe ilé fún akẹ́kọ̀ọ́ tó tọ̀ sórí ẹrù èkejì rẹ̀ nítorí ẹ̀yà
- Láí ṣẹ̀ láí rò, wọ́n jó Ṣọ́ọ́ṣì mi pátápátá ní Sokoto, ìrírí mi rèé - Pasitọ ìjọ Celestial
- Agbẹjọ́rò 34 táa tán nílé ẹjọ́, bí wọ́n ṣe sọ àwọn afurasí tó lọ́wọ́ nínú ikú Deborah Samuel sẹ́wọ̀n rèé
- Ta ni Ahmed Idris oluṣirò owó àgbà Nàìjíríà tó kò sí pampẹ́ àjọ EFCC lórí ẹsùn àjẹbánu N80bn
- Ìdajì ilé mi ni mo tà láti rán ọmọ mi nílé ẹ̀kọ́ àmọ́ wọ́n gbẹ̀mì rẹ̀ láìtọ́jọ́ - Bàbá Deborah Samuel
- A ò sọ pé ọmọ orílẹ̀ èdè Niger ni àwọn afurasí ta mú ní Sokoto - Iléeṣẹ́ Ọlọ́pàá
- Osun 2022: Kò sí ìjà mọ́, Adeleke àti Babayemi ṣetán láti jọ ṣiṣẹ́ papọ̀
Onyekachi, tó jẹ́ olùkọ́, tó sì ń gbé ní agbègbè Ijegun, ìpínlẹ̀ Eko fi kun pé yàtọ̀ sí lílu tí ọkọ òun máa ń na òun, ó ní lọ́pọ̀lọpọ̀ ìgbà ló máa ń sọ̀rọ̀ òdì sí òun.
Ó sọ pé ọkọ òun kò ní okoòwò kan, òun nìkan ni òun ṣiṣẹ́ tí òun sì ń gbọ́ bùkátà ilé.
"Oríṣiríṣi orúkọ tí kò da ni ó máa ń pè mí, kódà ó máa ń dúnkokò mọ́ mi, àwọn mọ̀lẹ́bí mi ti gbìyànjú láti dá sí ọ̀rọ̀ wa ṣùgbọ́n kò sí ìyàtọ̀."
"Nítorí àwọn ìwà rẹ̀ ni àwọn ẹbí mi kò ṣe kí n wá sí ilé mi mọ́, ó sì ní òun kò fẹ́ràn mi mọ́."
Ilé ẹjọ́ tú ìgbéyàwó wọn ká
Nígbà tó ń gbé ìdájọ́ rẹ̀ kalẹ̀, Ààrẹ ilé ẹjọ́ náà Adeniyi Koledoye tú ìgbéyàwó náà ká bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé Jude kò yọjú sílé ẹjọ́ láti wí tẹnu rẹ̀ lórí ẹ̀sùn tí ìyàwó rẹ̀ fi kàn án.
Koledoye ní kò tọ́ kí ènìyàn máa fi ẹnu tẹ́ḿbẹ́lú ọkọ tàbí aya rẹ̀ ni gbogbo ọ̀nà.
Bákan náà ló ní Jude kò gbìyànjú láti rọ ìyàwó láti má ṣe tẹ̀síwájú pẹ̀lú ìgbésẹ̀ kíkọ ara wọn sílẹ̀ tí obìnrin náà gbé.
Ó ní èyí túmọ̀ sí pé kò sí ìfẹ́ láàárín àwọn méjèèjì mọ́ àti pé kí Uju Onyekachi dá owó orí tí Jude san padà fun.














