Stellenbosch university fọwọ́ òsì júwe ilé fún akẹ́kọ̀ọ́ tó gbọnsẹ̀ sórí ẹrù èkejì rẹ̀ nítorí ẹ̀yà

Oríṣun àwòrán, @TammyPetersen87
Fasiti Stellenbosch lorilẹede South-Africa ti fi ọwọ osi juwe ile fun akẹkọọ alawọfunfun to tọ si ori ijoko alawọdudu akẹgbẹ rẹ.
Ninu atẹjade ti ileẹkọ naa fi lede ni wọn ti ni camera lo ṣafihan iṣẹlẹ ti alawọ funfun naa ti tọ si ori tabili rẹ pẹlu iwe ati laptop rẹ.
Wọn ni ko si akẹkọọ kankan to laṣẹ lati fi iya jẹ akẹkọọ miran nitori ẹya.
- Ènìyàn mẹ́rin pàdánù ẹ̀mí wọn níbi ìbúgbàmù tó wáyé ní Kano
- Láí ṣẹ̀ láí rò, wọ́n jó Ṣọ́ọ́ṣì mi pátápátá ní Sokoto, ìrírí mi rèé - Pasitọ ìjọ Celestial
- Agbẹjọ́rò 34 táa tán nílé ẹjọ́, bí wọ́n ṣe sọ àwọn afurasí tó lọ́wọ́ nínú ikú Deborah Samuel sẹ́wọ̀n rèé
- Ta ni Ahmed Idris oluṣirò owó àgbà Nàìjíríà tó kò sí pampẹ́ àjọ EFCC lórí ẹsùn àjẹbánu N80bn
- Ìdajì ilé mi ni mo tà láti rán ọmọ mi nílé ẹ̀kọ́ àmọ́ wọ́n gbẹ̀mì rẹ̀ láìtọ́jọ́ - Bàbá Deborah Samuel
- A ò sọ pé ọmọ orílẹ̀ èdè Niger ni àwọn afurasí ta mú ní Sokoto - Iléeṣẹ́ Ọlọ́pàá
- Osun 2022: Kò sí ìjà mọ́, Adeleke àti Babayemi ṣetán láti jọ ṣiṣẹ́ papọ̀
- Odunlade Adekola fakọyọ níbi àmì èyẹ AMVCA, ohun tí akẹgbé rẹ̀ Bukunmi sọ rèé
- Yorùbá ẹ fúnra, àwọn tó ṣekú pa Deborah fẹ́ dá ògún sílẹ̀ ni, wọn kò gbọdọ̀ lọ láì jìyà -Gani Adams
Awọn adari fasiti naa bu ẹnu atẹ lu iṣẹlẹ naa wi pe itiju gba a lo jẹ nitori iṣẹlẹ ẹlẹyamẹya ni.
Bawo ni iṣẹlẹ naa ṣe waye?
Saaju ni awọn akẹkọọ fasiti Stellenbosch ni orilẹede South Africa ti lọ si ori ẹrọ ayelujara ti wọn bẹrẹ si ni ki fun ọkunrin alawọ funfun kan pe o tọ si ori ẹru rẹ ni Ọjọ Isinmi.
Iṣẹlẹ naa to waye ni opin ọsẹ lo mu ki awọn akẹkọọ naa ṣapejuwe iṣẹlẹ naa gẹgẹ bi idẹyẹsini nitori ẹya.
Wọn ni akẹkọọ naa to wa ni yara rẹ lo gbọ ti wọn n pariwo ni ita ilẹkun rẹ to si ṣilẹkun.
Akẹkọọ alawọ funfun naa lo ri ti o duro lẹnu ọna to si jẹ ẹni to ti mu ọti yo amọ to duro si ẹnu ọna''
''O wọ inu yara naa pe oun duro de ẹnikan, lẹyin naa ni akẹkọọ na wa ni oun gbọdọ ya fidio rẹ amọ niiṣe lo bẹrẹ si ni tọ si ori laptop ati iwe rẹ.''
Awọn fidio to wa lori ẹrọ ayelujara ṣafihan akẹkọọ alawọfunfun naa nibi to ti n tọ si ori awọn nkan rẹ, ti iyẹn si bere lọwọ rẹ pe kilo n ṣe, amọ idahun rẹ ni pe nkan ti an ṣe ṣi awọn alawọdudu niyẹn.''
Titi di asiko yii, inu ipaya ni akẹkọọ ti wọn dẹyẹ si naa wa.
Ẹgbẹ awọn akẹkọọ ati Ajọ to n pe fun idọgba laarin awọn eniyan to si n risi ọrọ awọn akẹkọọ ti ni iwadi ti bẹrẹ ni pẹrẹwu lori iṣẹlẹ naa.
Amọ ọkan lara awọn akẹkọọ lori Twitter ni awọn adari fasiti naa kan ni ki akẹkọọ ọkunrin naa tọrọ idariji lọwọ awọn eniyan ni kilasi amọ wọn ko fi iroyin naa lede nipa kikọ e-mail nipa iṣẹlẹ naa.















