Kano Explosion: Ènìyàn mẹ́sàn-án pàdánù ẹ̀mí wọn níbi ìbúgbàmù tó wáyé ní Kano

Iléeṣẹ́ ọlọ́pàá Ìpínlẹ̀ Kano ti fìdí rẹ̀ múlẹ̀ wí pé ènìyàn mẹ́sàn-án ló bá ìṣẹ̀lẹ̀ afẹ́fẹ́ gáàsì tó bú gbàmù ní Sabon Gari lọ.
Ní òwúrọ̀ ọjọ́ Ìṣẹ́gun, ọjọ́ kẹtàdínlógún, oṣù karùn-ún, ọdún 2022 ni ìbúgbàmù náà wáyé tí ó sì ba ilé kan jẹ́ ní agbègbè náà.
Kọmíṣọ́nà Ọlọ́pàá Ìpínlẹ̀ Kano, Sam'ila Dikko nígbà tó ń fìdí ìṣẹ̀lẹ̀ náà múlẹ̀ ní kìí ṣe àdó olóró ló bú gbàmù bíkòṣe agolo afẹ́fẹ́ gáàsì.

Oríṣun àwòrán, OTHERS
Dikko ní àwọn mọ èyí nítorí ọkàn lára àwọn tó lùgbàdì ìṣẹ̀lẹ̀ náà ló jẹ́ wẹ́dà.
Ó fi kun pé ọkùnrin mẹ́ta àti obìnrin kan ni àwọn le fìdí rẹ̀ múlẹ̀ báyìí wí pé wọ́n ti bá ìṣẹ̀lẹ̀ náà rìn lowurọ amọ nigba ti yoo fi di irọlẹ iye wọn tun ti le sii.
Ṣaájú ni Ààrẹ àwọn ọlọ́jà Sabon Gari, Nafi'u Nuhu Indabo sọ fún BBC News Hausa pé ìṣẹ̀lẹ̀ náà ṣe àkóbá fún ọ̀pọ̀lọpọ̀ ènìyàn tó fi mọ́ àwọn ọmọ ilé ẹ̀kọ́ tó wà ní agbègbè náà.
- Ènìyàn mẹ́rin pàdánù ẹ̀mí wọn níbi ìbúgbàmù tó wáyé ní Kano
- Fásitì fọwọ́ òsì júwe ilé fún akẹ́kọ̀ọ́ tó gbọnsẹ̀ sórí ẹrù èkejì rẹ̀ nítorí ẹ̀yà
- Agbẹjọ́rò 34 táa tán nílé ẹjọ́, bí wọ́n ṣe sọ àwọn afurasí tó lọ́wọ́ nínú ikú Deborah Samuel sẹ́wọ̀n rèé
- Ta ni Ahmed Idris oluṣirò owó àgbà Nàìjíríà tó kò sí pampẹ́ àjọ EFCC lórí ẹsùn àjẹbánu N80bn
Ìjọba Kano fìdí òótọ́ múlẹ̀ lórí ìbúgbàmù Sabon Gari
Ìjọba ìpínlẹ̀ Kano ti sọ àfọ̀mọ́ ọ̀rọ̀ wí pé Ìbúgbàmù tó wáyé ní agbègbè Sabon Gari kò wáyé nínú ilé ẹ̀kọ́.
Kọmíṣọ́nà fétò ìròyìn ìpínlẹ̀ Kano, Mallam Muhammad Garba ní inú ọgbà kan tí wọ́n ti ń ta oúnjẹ àwọn ẹranko tó kọjú sílé ẹ̀kọ́ aládani kan tó wà ní Sabon Gari, ìjọba ìbílẹ̀ Fagge ni ìṣẹ̀lẹ̀ láabi náà ti wáyé.
Mallam Garba rọ àwọn olùgbé agbègbè náà láti fọkàn balẹ̀ bí ìjọba ṣe ń ṣiṣẹ́ pẹ̀lú àwọn àjọ tí ọ̀rọ̀ kan láti wádìí ohun tó ṣokùnfà Ìbúgbàmù ọ̀hún.
Bákan náà ló sọ àrídájú rẹ̀ wí pé àwọn yóò máa bun ará ìlú gbọ́ lórí gbogbo ìgbésẹ̀ àwọn lórí ìṣẹ̀lẹ̀ náà.
Bẹ́ẹ̀ náà ló ṣèkìlọ̀ fún àwọn ènìyàn láti yé gbé ìròyìn òfégè lórí ìṣẹ̀lẹ̀ yìí

Ìṣẹ̀lẹ̀ ìbúgbàmù naa wáyé ní òwúrọ̀ yìí ní agbègbè Sabon Gari, ìpínlẹ̀ Kano gẹgẹ bi akọroyin wa ṣe jabọ.
Ìbúgbàmù náà gẹ́gẹ́ bí àwọn tí ìṣẹ̀lẹ̀ náà ṣojú wọn ṣe sọ ṣe àkóbá fún ilé kan ní agbègbè náà.
Ní àkókò tí a fi ń kó ìròyìn yìí jọ, a kò tíì lè fi ohun tó ṣokùnfà Ìbúgbàmù náà múlẹ̀ ṣùgbọ́n àwọn kan ń sọ wí pé àdó olóró ló bú gbàmù.
Ààrẹ àwọn ọlọ́jà Sabon Gari, Nafi'u Nuhu Indabo sọ fún BBC News Hausa pé ìṣẹ̀lẹ̀ náà ṣe àkóbá fún ọ̀pọ̀lọpọ̀ ènìyàn tó fi mọ́ àwọn ọmọ ilé ẹ̀kọ́ tó wà ní agbègbè náà.
A kò tíì fìdí rẹ̀ múlẹ̀ bóyá ẹnìkankan bá ìṣẹ̀lẹ̀ náà lọ.
A o maa mu ẹkunrẹrẹ iroyin naa wa fun yin laipẹ.














