EFCC N80bn Ahmed Idris: Òhun táa mọ̀ rèé nípa ìròyìn oluṣirò owó àgbà tí EFCC ń wọ́ ìdí ẹ̀

..

Oríṣun àwòrán, Google

Ajọ to n gbogun ti iwa ajẹbanu lorileede Naijiria EFCC ti kede pe awọn ti mu oluṣiro owo agba ilẹ naa Ahmed Idris lori ẹsun pe o ṣe owo ọba kumọkumọ.

Iye owo ti wọn ni o lu ni ponpo gẹgẹ bi atẹjade ti wọn fi sita loju opo wọn jẹ ọgọrin biliọnu Naira.

Lọjọ Aje tii ṣe ọjọ Kẹrindinlogun oṣu Karun ni wọn lawọn mu pe ki o wa sọ tẹnu rẹ nipa ibi ti wọn dari owo yi si.

Àkọlé fídíò, Títí ayé yóò fi parẹ́, wọ́n ó máa sọ̀rọ̀ sí Ànọ́bì ni, wọ́n ó sì máa bú Jésù ni, ẹ wá gbọ́ òótọ́ ohun tí Quaran sọ – Akeugbagold

Atẹjade naa tẹsiwaju pe awọn ni ẹri to daju pe arakunrin Ahmed ṣe makaruru owo yi nipa didari owo iṣẹ agbase ati awọn owo miran gba akoto owo awọn ileeṣẹ ayederu.

Bẹẹ wọn sọ pe o lo awọn ọrẹ,mọlẹbi ati alabaṣe miran lati dari owo yi sibo mii.

Lara ọna ti ajọ naa sọ pe o gba ko owo yi pamọ ni rira awọn ile ni ilu Abuja ati Kaduna.

Ninu atẹjade naa EFCC salaye pe awọn ni lati mu ọgbẹni Ahmed nitori o kọ lọpọ igba lati yọju sawọn lẹyin ti awọn fi iwe ipe ranṣẹ si.

Labẹ ijọba aarẹ a ko fẹ ẹ ri oṣiṣẹ ijọba ti wọn fẹsun owo to to iye yi kan lẹnu lọọlọ yi.

Ajọ naa ko ṣalaye igba ti wọn yoo gbe arakunrin Ahmed lọ si ile ẹjọ

Bawo ni ipo oluṣiro owo agba ṣe pataki labẹ ijọba?

Ẹni to di ipo oluṣiro owo agba orileede Naijriia mu labẹ ofin ni aarẹ gbe aṣẹ le lọwọ lati maa ṣọ akoto owo orileede Naijiria.

Ọdun mẹrin ni iru eeyan bẹ a maa fi di ipo yi mu to si jẹ pe o gbọdo maa ṣe isiro gbogbo owo ti ijọba ba na sita ati eleyi to ba wọle fun ijọba.

Oṣu Kẹfa ọdun 2015 ni aarẹ Buhari yan Ahmed Idris si ipo oluṣiro owo agba orileede naa.

Ṣaaju iyansipo rẹ, Idris jẹ ọga agba ni ileeṣẹ to n risi ọrọ idagbasoke irin ati iwakusa.

Ọmọ bibi ilu Kano ni Ahmed Idris jẹ ti wọn si bi ni ọdun 1960.

Aarẹ Buhari tun fontẹ lu ko ṣe saa keji lọdun 2019 eleyi to ṣe pe ẹẹkan naa ni anfaani yi wa fun ẹni ba di ipo yi mu.