Girl killed in Sokoto: Ọdún yìí ló yẹ kí Deborah parí ẹ̀kọ́ rẹ̀ kí wọ́n tó gbẹ̀mí rẹ̀ - Bàbá olóògbé

Deborah Samuel

Baba Deborah Samuel, ti awọn alakakiti ẹsin ṣekupa ni Sokoto lori ẹsun pe o sọrọ abuku nipa Anọbi ti sọ pe idaji ile oun lohun lu ni gbanjo lati ran ọmọ naa lọ sile ẹkọ, oun si ti n reti ọjọ ti yoo pari ẹkọ naa ki wọn to ge ẹmi rẹ kuru.

Emmanuel Garba lo sọ ọrọ naa ninu ifọrọwerọ pẹlu BBC lọjọ Aje.

O ni "Ọmọ meje ni mo bi, Deborah si ni ọmọ mi keji."

"Ọrọ ẹkọ rẹ kami lara gidi to bẹẹ ti mo fi lọ ta idaji ile mi lati ran ọmọ naa lọ nilẹ ẹkọ."

"Ọdun yii lo yẹ ko pari ẹkọ rẹ, mo si ti n foju sọna fun ọjọ naa ki aburo mi to pe mi lati Sokoto, to si ṣalaye ohun to ṣẹlẹ si ọmọ naa fun mi."

"Lootọ ni mo gbọ pe ọwọ ọlọpaa ti tẹ awọn kan lara awọn to lọwọ ninu iku rẹ, amọ mo ti fa gbogbo rẹ le Ọlọrun lọwọ."

Àkọlé fídíò, Títí ayé yóò fi parẹ́, wọ́n ó máa sọ̀rọ̀ sí Ànọ́bì ni, wọ́n ó sì máa bú Jésù ni, ẹ wá gbọ́ òótọ́ ohun tí Quaran sọ – Akeugbagold

Baba oloogbe naa, to jẹ agbẹ sọ pe kii ṣe owo kekere ni oun na lati gbe oku ọmọ naa pada lọ si ilu awọn, ati pe oun tun jẹ ọpalanba iya lati gbe oku rẹ wale.

O ni "Owo ti mo na lati gbe oku rẹ wa si ipinlẹ Niger ko din ni 100,000, yatọ si awọn owo ti mo na ni ọọfisi ajọ DSS lati ṣeto bi mo ṣe gbe oku rẹ ọhun."

Deborah Emmanuel

Wọn ti sin oku Deborah

Awọn mọlẹbi oloogbe naa ti sin oku rẹ ni ilu Tunga, to wa ni ijọba ibilẹ Rijau, ni ipinlẹ Niger pẹlu omije loju.

Patrick Emmanuel, to jẹ ibatan oloogbe naa sọ pe awọn sin oku rẹ lẹyin ti awọn ọdọ atawọn agbagba abule wọn kọkọ kọ jalẹ pe ki wọn ma sin oku naa nitori bo ṣe jade laye.

Deborah Emmanuel

O ni awọn agbagba naa woye pe niwọn igba o jẹ pe ile ẹkọ rẹ ni wọn ti pa, ijọba lo yẹ ko sin oku naa.

Gẹgẹ bii ohun to sọ, awọn eeyan ilu naa ni ki wọn gbe oku rẹ lọ sile igbokupamọ si, amọ lẹyin ọpọ ẹbẹ, wọn gba pe ki wọn sin ọku rẹ sinu ilu naa.

Àkọlé fídíò, Alaafin stool: Wo ẹni tó ṣeẹṣe pé kí Aláàfin kàn lẹ́yìn ìpapòdà Oba Lamidi Adeyemi