Odunlade Adekola: Wo Aàmì èye tí Odunlade Adekola gbà ní AMVCA

Odunlade Adekola

Oríṣun àwòrán, Odunlade Adekola

Gbajugbaja oṣere tiata Nollywood to tun n gbe awo orin jade, Odunlade Adekọla ti gba ami ẹyẹ oṣere tiata ọkunrin to pegede julọ ni agbo oṣere.

Odunlade bori awọn oṣere to kopa ninu fiimu Rattle Snake, Amina, Gold Coast Lounge ati awọn miran lati gba ami ẹyẹ naa.

Ami ẹyẹ AMVCA ni wọn ma n fun awọn oṣere fiimu, awọn ti wọn jọ ṣe fiimu ati gbogbo awọn ti wọn jọ kopa ninu ẹ.

Lara awọn akẹgbẹ rẹ to gboriyin fun Adekola ni Bukunmi Oluwashina to ṣe fiimu ''Jankariwo'' to fi gba ami ẹyẹ.

Bukunmi lasiko to n gboriyin fun akẹgbẹ rẹ ni o jẹ moriya fun oun.

Odunlade Adekola

Oríṣun àwòrán, Odunlade Adekola

Bakan naa lo dupẹ lọwọ oṣerekunrin naa ti oun pe si fiimu oun to si da loun nipa fiimu rẹ ''Jankariwo'''.

''A ṣe aṣeyọri lori fiimu Jankariwo. Iwuri nla lo jẹ fun mi bi wọn ṣe darukọ fiimu mi fun igba meji ni ami ẹyẹ to gajulọ ni ilẹ Afrika.

Àkọlé fídíò, Títí ayé yóò fi parẹ́, wọ́n ó máa sọ̀rọ̀ sí Ànọ́bì ni, wọ́n ó sì máa bú Jésù ni, ẹ wá gbọ́ òótọ́ ohun tí Quaran sọ – Akeugbagold

''Ẹ ku oriire ẹgbọn mi, ti mo n pe ni ''Number 1"', ẹ se ti ẹ jẹ iwurii ninu iṣẹ ti ẹ yan laayo.''

Bakan naa ni Bukunmi dupẹ pe o gbọ ipe oun lori fiimu naa, to si gboriyin fun pe iṣẹ nla to ṣe.

''Mo dupẹ lọwọ awọn to bami ṣiṣẹ naa ti wọn si jẹ ko ṣe aṣeyọri.''

Fiimu naa gba ami ẹyẹ gẹgẹ bi fiimu Yoruba akọkọ ti wọn yoo fi orukọ rẹ lede fun ami ẹyẹ ni ọna meji.

Àkọlé fídíò, Alaafin stool: Wo ẹni tó ṣeẹṣe pé kí Aláàfin kàn lẹ́yìn ìpapòdà Oba Lamidi Adeyemi

Ami ẹyẹ Ilẹ Africa ti ''Africa Magic Viewers'Choice Awards (AMVCA), waye ni Ọjọ Kẹrinla, Oṣu Karun un, 2022.

Ami ẹyẹ naa ni awọn kan ma n pe ni ami ẹyẹ ti Oscar ti ilẹ Afrika, ti wọn ti n fun awọn oṣere fiimu, awọn to n gbe wọn jade ati awọn onimọ miran ni ẹka wọn.

Ọdun yii ni ami ẹyẹ naa tun pada si ilẹ Afrika lẹyin ti wọn ko lee ṣe ni ọdun to kọja nitori ajakalẹ aarun Coronavirus.

Àkọlé fídíò, Mathew Okotie, Driver who returned laptop: Ṣé àwọn awakọ̀ olóòtọ́ ṣi kù ní Nàìjírípa?