2023 Election: Wo àwọn mínísítà tó dágbére fún Ààrẹ Buhari pe àwọn fẹ́ lọ dù ipò ní ọdún 2023

Aworan aarẹ Buhari ati awọn Minisita rẹ

Oríṣun àwòrán, Nigerian Presidency

Aarẹ Muhammadu Buhari ti ṣe ayẹyẹ idagbere fawọn Minisita rẹ to kọwe fipo sil lati dije dupo ninu idibo ọdun 2023.

Lọjọ Ẹti lasiko ti idagbere yi waye, aarẹ sọ pe oun ni igbagbo pe pupọ wọn lo ni ikapa lati ṣe ilede lẹyin oun.

''Ko si iye meji pe aarẹ wa ninu awọn Minisita yi. Wọn kajuẹ lati se isẹ takuntakun fun anfaani araalu''

''Ohun manigbagbe ree taa fi sil ninu itan orileede Naijiria''

Ṣaaju ni aarẹ Buhari ti sọ pe ki awọn minisita, olori ileeṣẹ ijọba ati awọn mii ti o ba f dije dupo kọwe fipo sil ko to di ọjọ Aje to n bọ.

Ninu awọn Minisita to dagbere fun aarẹ lọjọ Ẹti ni Minisita eto idajọ Abubakar Malami ti a gbọ pe o n dije du ipo Gomina ni ipinlẹ Kebii.

Awọn minisita miran to kọwe fipo silẹ dagbere o digba fun aarẹ Buhari ree:

  • Minisita eto idajọ Abubakar Malami
  • Minisita feto irinna Rotimi Amaechi
  • Minisita feto igbanisiṣẹ Chris Ngige
  • Minisista feto epo rọbi Timpre Sylva
  • Minisita agbegbe Naija Delta Godswill Akpabio
  • Minisita feto imọ Sayẹnsi ati imọ ẹrọ Ogbonnaya Onu
  • Minisita feto ọrọ awọn obinrin Pauline Tallen
  • Minisita keji fun ọrọ alumọni Uche Ogah

Aarẹ Muhammadu Buhari to de ori oye lọdun 2005 yoo pari saa rẹ ẹlẹẹkeji ni oṣu Karun ọdun 2023 ti idibo yoo si waye ni oṣu Keji ọdun 2023

Awọn ẹgbẹ oṣelu yoo seto idibo abẹnu wọn ni ọjọ Kẹta oṣu Kẹfa ọdun 2022