Corruption in High Places: Wo àwọn èèkàn ìjọba márùn ùn tí wọ́n fẹ̀sùn àjẹbánu kàn lábẹ́ ààrẹ Buhari

Aworan awọn ti EFCC gbamu fẹsun ajẹbanu lasiko ijọba Buhari

Iroyin pe ajọ EFCC to n gbogun ti iwa jẹgudujẹra ni Naijiria mu oluṣiro owo agba Naijiria, Ahmed Idris, leleyi taa tun ba ji lati owurọ ọjọ Iṣẹgun ọsẹ yii.

Bo ti lẹ jẹ wi pe ajọ naa fi atẹjade sita nirọlẹ ọjọ Aje tii ṣe ọjọ Kẹrindinlogun oṣu kaarun ọdun 2022, pupọ ni ko ribi ka iroyin yi titi di ọjọ Keji.

Ohun to tẹle iroyin yi ni bawọn ọmọ Naijiria ṣe n ṣeemọ lori iye owo ti wọn ni alamojuto akoto owo ilẹ naa lu ni ponpo.

Àkọlé fídíò, 'Ọ̀pọ̀ ìgbà l'èmí gan fẹ́ du àwọn ipò òṣèlú kan, bíì '2015, 2019' àmọ́ mo tẹ 'slow' torí bàbà mi, Akala náà ń jáde'

Ninu akọsilẹ eleyi taa ṣi ranti lẹnu igba ti ijọba aarẹ Buhari dori oye, ko fẹ ẹ si ẹsun ajẹbanu ti wọn fi kan oṣiṣẹ ijọba to to biliọnu ọgọrin Naira.

Ajọ EFCC si n gbiyanju nipa kikede awọn to ṣe aṣemaṣe nidi afọkantan ti araalu gbe le wọn lọwọ.

BBC Yoruba gbiyanju lati wo awọn ti wọn fsun ajẹbanu kan lẹnu igba ti ijọba aarẹ Buhari wa lori oye ni paapa awọn to di ipo kan tabi omiran mu ninu ijọbva.

Diẹ ta ri ko jọ ninu wọn ree:

Winifred Oyo-Ita

Olori oṣiṣẹ orileede Naijriia ni arabinrin Winifred Oyo-Ita jẹ ki wọn to fẹsun ajẹbanu kan.

Lẹyin ọjọ mẹrin tawọn oṣiṣẹ ajọ naa fọrọ wa lẹnu,a gbọ pe o pada kangun si ile iwosan.

Aworan olori oṣiṣẹ ijọba apapọ Naijria tẹlẹ

Oríṣun àwòrán, OHSF

Nigba naa lọdun 2019 wọn fẹsun kan pe wọn ri owo to fẹẹ to miliọnu ẹgbẹta Naira ninu akoto owo awọn alabaṣe rẹ kan.

EFCC gbaṣẹ lati gbẹsẹ le akoto owo yi,aarẹ Buhari si da duro lẹnu iṣẹ.

Titi di asiko taa wa yi, ẹjọ naa ko ti ribi niyanju nitori adajọ to n gbẹjọ naa sọ pe awọn ko ni tẹsiwaju pẹlu igbẹjọ naa ayafi ti EFCC ba ṣe ohun to yẹ ko ṣe.

Àkọlé fídíò, Títí ayé yóò fi parẹ́, wọ́n ó máa sọ̀rọ̀ sí Ànọ́bì ni, wọ́n ó sì máa bú Jésù ni, ẹ wá gbọ́ òótọ́ ohun tí Quaran sọ – Akeugbagold

Andrew Yakubu

Olori ileeṣẹ to n risi ọrọ epo rọbi ni Naijiria NNPC nigba kan ri Andrew Yakubu naa wa lara awọn ti wọn fẹsun ajẹbanu kan to si jẹ pe igbẹjọ rẹ bẹrẹ labẹ ijọba aarẹ Buhari.

Ọdun 2017 ni eeyan kan ta awọn agbofinro lolobo pe o ko owo pamọ si ile rẹ kan to wa ni adugbo Sabon Tasha ni ilu Kaduna.

Awọn agbofinro tu ile naa ti wọn si ba miliọnu mẹsan dọla le diẹ ni ile naa.

Aworan ọga agba NNPC tẹlẹ labẹ ijọba Goodluck Jonathan

Oríṣun àwòrán, Nnpc

Ajọ EFCC gbe lọ siwaju adajọ Ahmed Mohammed ni ile ẹjọ giga Abuja lọjọ Kẹrindinlogun oṣu Kẹta ọdun 2017 lori ẹsun onigun mfa ṣisẹ fayawọ owo.

Amọ ile ẹjọ kotẹmilọrun pada gbe idajọ kalẹ pe EFCC ko ribi fidi ọrọ mulẹ pe loot lawọn owo yi jẹ owo to ji pamọ lati le ṣe fayawọ rẹ.

Andrew Yakubu sọ pe owo ẹbun tawọn ọrẹ ati alabaṣe fun oun ni nigba to wa ni ipo adari NNPC.

Ile ẹjọ pada ni ko maa lọ pe ko lẹjọ lati jẹ lori ẹsun yi

Abba Kyari

Ọga ọlọpaa yi jẹ ilumọọka lori bo ti ṣe maa n mu awọn ọdaran ajinigbe ati ọdaran miran ṣaaju ki wn to ka mọ idi aṣemaṣe.

Ọrọ aṣemaṣe rẹ ko si ṣẹyin pe ajọ to n gbogun ti lilo oogun oloro NDLEA ṣafihan fọnran fidio ibi to ti fẹ lẹdi apo pọ pẹlu oṣiṣẹ NDLEA lati ta oogun oloro.

Ṣaaju asiko yi ni iroyin kan ti jade nibi ti iwadii ileeṣẹ ọtẹlẹmuyẹ FBI lorileede Amẹrika to naka alebu si wi pe o ni ajọṣepọ pẹlu gbajuẹ ilumọọka nii, Huspuppi.

Abba Kyari

Ni bayi, wọn ti ni ki Abba Kyari lọ rọọkun nile ti igbẹjọ rẹ si ti bẹrẹ lori awọn aṣemaṣe ti wọn fi kan an niwaju ile ẹjọ giga to wa ni Abuja.

Kyari ti kuro lẹni a pọnle gẹgẹ tawọn agbofinro si ti bẹrẹ si ni tọ pinpin rẹ.

Willie Obiano

Gomina nipinlẹ Anambra tẹlẹ ni Willie Obiano to si jẹ pe oun naa n ba EFCC fa ẹjọ lori ẹsun ajbanu.

Wọn nawọ gan Obiano ni papakọ ofurufu Murtala Muhammad lẹyin to pari saa rẹ keji gẹgẹ bi Gomina ipinlẹ Anambra.

Gẹgẹ baa ṣe gbọ, awọn ikọ ọtẹlẹmuyẹ EFCC gbe lọ si ọfisi wọn ni Abuja nibi ti wọn ti ṣe ifọrọwanilẹnuwo pẹlu rẹ lori awọn ẹsun kọọkan.

Chief Willie Obiano

Oríṣun àwòrán, Facebook/Chief Willie Obiano

Ninu rẹ la gbọ eleyi to ni ṣe pẹlu bo ti ṣe ṣe owo biliọnu mẹtadinlogun Naira Paris Fund ti wọn da pada kumọkumọ .

Eyi nikan kọ, EFCC beere ọrọ lọwọ rẹ lori bo ṣe na owo idaabo Security Vote ti o gba lasiko to wa lori ipo Gomina.

Wọn ti pada tu silẹ lẹyin to gba oniduro amọ wọn ko gbe pali irina pasipọọti rẹ kalẹ fun.

Ahmed Idris

Lọjọ Aje ọjọ Kẹrindinlogun oṣu Karun ọdun 2022 ni ajọ to n gbogun ti iwa ajẹbanu lorileede Naijiria EFCC kede pe awọn ti mu oluṣiro owo agba ilẹ naa Ahmed Idris.

Wọn fẹsun kan an pe o ṣe owo ọba kumọkumọ.

Iye owo ti wọn ni o lu ni ponpo gẹgẹ bi atẹjade ti wọn fi sita loju opo wọn jẹ ọgọrin biliọnu Naira.

Bẹẹ wọn sọ pe o lo awọn ọrẹ,mọlẹbi ati alabaṣe miran lati dari owo yi sibo mii.

Lara ọna ti ajọ naa sọ pe o gba ko owo yi pamọ ni rira awọn ile ni ilu Abuja ati Kaduna.