Deborah Killed in Sokoto: Olùṣọ́ ìjọ tí wọ́n jó ṣọ́ọ̀ṣì pátápátá ní Sokoto sòrò sókè!

Ṣọọṣi to jona ni Sokoto

Oríṣun àwòrán, Evangelist Adebiyi Olalekan

Oluṣọ Ṣọoṣi ti wọn jo ijọ rẹ guruguru lasiko ifẹhọnuhan awọn ọdọ ni Sokoto ti sọrọ soke.

Eyi ko ṣẹyin awọn iṣẹlẹ to waye lẹyin ti awọn akẹkọọ kan pa arabinrin Deborah Samuel lori ẹsun pe o sọrọ odi si Muhammed ti ẹsin Islam.

Olusọagutan ijọ Celestial Church of Christ, Ọna Ara Model Parish, Sokoto, Superior Evangelist Adebiyi Olalekan salaye bi iṣẹlẹ naa ṣe ṣẹlẹ.

Ṣọọṣi to jona ni Sokoto

Oríṣun àwòrán, CCC, Ona Ara Sokoto

Ninu alaye to ṣe lo ti ni ṣadede ni awọn ọdọ ni ọgọọrọ wọn ja wọ ile ijọsin naa to wa ni agbegbe Ilela, ni ilu Sokoto.

Àkọlé fídíò, Tàá bá lè bá àwọn ọmọ tó pa Deborah ní Sokoto sọ̀rọ̀ pé ìwà ẹranko ni wọ́n hù, ó burú - Òṣèré Sokoti
Àkọlé fídíò, Títí ayé yóò fi parẹ́, wọ́n ó máa sọ̀rọ̀ sí Ànọ́bì ni, wọ́n ó sì máa bú Jésù ni, ẹ wá gbọ́ òótọ́ ohun tí Quaran sọ – Akeugbagold

Olusoagutan naa ni oun ko ri oju wọn nitori oun nilo lati sapamọ, ki oun sa asala fun ẹmi oun.

''Ibi ti mo sapamọ si ni mo ti ri pe wọn ti fi ina si ile ijọsin mi.''

Olusoagutntan naa ni ko si ẹni ti awọn ni ija pẹlu ninu wọn, ti ko si ye wọn idi ti wọn fi jo ile ijọsin awọn.

''Mi o mọ Deborah ti gbogbo eleyii n ti itori rẹ ṣẹlẹ, ori ẹrọ ayelujara ni mo ti gbọ nipa iṣẹlẹ arabirin naa.''

''Ko si n nkan kan ti a ri mu kuro ninu ile ijọsin wa,gbogbo ẹ ni ina jo kanlẹ raurau, Ko si ibi ti a ti le ṣe ẹsin paapaa.''

Ṣọọṣi to jona ni Sokoto

Oríṣun àwòrán, Evangelist Adebiyi Olalekan

Sugbon ko si ẹni ti o farapa,emi nikan ni mo fi ẹsẹ rọ ni igba ti mo n sa kaakiri lati doola ẹmi arami.

Bakan naa ni o fikun pe awọn ti fi iṣẹlẹ naa to awọn ọlọpaa ti o wa nitosi leti, ''ti wọn si jẹ ka mọ wipe awọn a wa sibẹ sugbọn wọn o sọ akoko ti wọn bọ.''

Àkọlé fídíò, Wọ́n gbé Póò ìtọ̀ àti igbẹ́’ tó ti já nídìí lé mi lórí lọ dànù l’Eko, pẹ̀lú òúnjẹ́ mi lọ́wọ́ mi - Ajirebi
Àkọlé fídíò, 'Ọ̀pọ̀ ìgbà l'èmí gan fẹ́ du àwọn ipò òṣèlú kan, bíì '2015, 2019' àmọ́ mo tẹ 'slow' torí bàbà mi, Akala náà ń jáde'
Ṣọọṣi to jona ni Sokoto

Oríṣun àwòrán, Evangelist Adebiyi

Oluṣoaguntan naa fikun un pe wọn ṣẹṣẹ gbe oun wa si ori ijọ naa,amọ ti ou ba awọn CAN ṣe ipaade.

Lori iṣẹlẹ naa ni Oluṣoagutan naa ti ni ko yẹ ki Iru iṣẹlẹ ti o ṣẹlẹ si Arabinrin Deborah maa waye.

''o yẹ ki a jẹ ọrẹ ara wa, Bibeli si sọ fun wa wipe ki a maa lepa alaafia pẹlu gbogbo eniyan. Ohun ti ko daa rara ni. ko si yẹ ki o maa ṣẹlẹ.''