Ẹ kò gbọdọ̀ mu igbó àti sìgá lẹ́nu iṣẹ́ mọ́ – Makinde kìlọ̀ fáwọn ọmọ ẹgbẹ́ onímọ́tò

Oríṣun àwòrán, Seyi Makinde
Ninu igbinyanju ijọba ipinlẹ Oyo lati ri pe alaafia jọba ní agbegbe ipinlẹ naa, Gomina Seyi Makinde ti kede awọn ilana ati ikilọ tuntun fun awọn ọmọ ẹgbẹ oni moto ni Ipinlẹ Oyo.
Makinde, to gba ẹnu komisona rẹ, Daud Sangodoyin sọrọ niluu Ibadan sọ pe ọpọlọpọ iwuwasi awọn ọmọ ẹgbẹ onimọto ati iwa orogun tí o da alaafia ilu laamu ni ko tẹ ìjọba ipinlẹ Oyo lọrun.
Ninu atesita kan tí akọroyin agba fun gomina Seyi Makinde buwọlu, o ni ajọṣepọ ìjọba ipinlẹ Oyo ati ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Oyo ni bii kí kede ilana tuntun fun awọn ọmọ ẹgbẹ oni moto.
- Ènìyàn mẹ́rin pàdánù ẹ̀mí wọn níbi ìbúgbàmù tó wáyé ní Kano
- Fásitì fọwọ́ òsì júwe ilé fún akẹ́kọ̀ọ́ tó gbọnsẹ̀ sórí ẹrù èkejì rẹ̀ nítorí ẹ̀yà
- Láí ṣẹ̀ láí rò, wọ́n jó Ṣọ́ọ́ṣì mi pátápátá ní Sokoto, ìrírí mi rèé - Pasitọ ìjọ Celestial
- Agbẹjọ́rò 34 táa tán nílé ẹjọ́, bí wọ́n ṣe sọ àwọn afurasí tó lọ́wọ́ nínú ikú Deborah Samuel sẹ́wọ̀n rèé
- Ta ni Ahmed Idris oluṣirò owó àgbà Nàìjíríà tó kò sí pampẹ́ àjọ EFCC lórí ẹsùn àjẹbánu N80bn
- Ìdajì ilé mi ni mo tà láti rán ọmọ mi nílé ẹ̀kọ́ àmọ́ wọ́n gbẹ̀mì rẹ̀ láìtọ́jọ́ - Bàbá Deborah Samuel
- A ò sọ pé ọmọ orílẹ̀ èdè Niger ni àwọn afurasí ta mú ní Sokoto - Iléeṣẹ́ Ọlọ́pàá
- Osun 2022: Kò sí ìjà mọ́, Adeleke àti Babayemi ṣetán láti jọ ṣiṣẹ́ papọ̀
- Odunlade Adekola fakọyọ níbi àmì èyẹ AMVCA, ohun tí akẹgbé rẹ̀ Bukunmi sọ rèé
Ilana tuntun naa ni ko fun awọn ọmọ ẹgbẹ oni mọto ni anfaani lati mu ida òfin lọwọ wọn, àti pe wọn gbọdọ tẹle eto ilana ofin orilẹ-ede Naijiria, ipinlẹ Oyo ati ti ajọ to n rí sì lilọbibọ ọkọ ni Ipinlẹ Oyo, OYRTMA.
Ilana tuntun naa ko faye gba àwọn ọmọ ẹgbẹ ònímọto lati mu siga, ọtí tabi lo ogun oloro lenu iṣẹ wọn.
Sangodoyin tẹsiwaju pe awọn ọmọ ẹgbẹ onimọto gbọdọ maa wọ aṣọ to ni ountẹ ìjọba lara lẹnu iṣẹ, wọn si gbọdọ ṣe iṣẹ wọn lai si jagidijagan pẹlu ara ilu.
Komisona olopaa ni ipinlẹ Oyo, Ngozi Onadeko wa ṣe ni ikilọ fún àwọn ọmọ ẹgbẹ òní moto lati ri pe wọn jina sì iwa ibajẹ ati iwa jagidijagan nítorí awọn eleto abo ni ipinlẹ Oyo o ni faye gba ẹnikẹni to ru iru iwa naa.
Ninu ọrọ rẹ, alaaga fun awon ọmọ ẹgbẹ oni mọto l'Oyo, Alh Mukaila Lamidi ṣe ileri pe gbogbo ofin ìjọba ni ọmọ ẹgbẹ awọn ṣetan lati tẹle.














