Adebayo Adelabu: Mo ti ṣetán láti gba ìjọba lọ́wọ́ Makinde lọ́dún 2023

Adebayo Adelabu

Oríṣun àwòrán, SR

Ọkan lara awọn to fẹ dije du ipo gomina ipinlẹ Oyo lọ́dún 2023 lábẹ́ ẹgbẹ oselu APC, Adebayo Adelabu ti fọwọ ìdánilójú sọ yà Ọlọrun ti yan òun láti wa tukọ ìṣàkóso ipinlẹ náà.

Adelabu, ẹni to ti kọkọ díje nínú ẹgbẹ oselu APC l'ọdun 2019 fún ipo gomina ṣàlàyé síwájú sí pe Ọlọrun ni pe asiko oun tito lati di gomina ipinle Oyo nígbà náà lọ un, sugbọn ó ti tó àkókò bayii lati gba ijọba kúrò lọ́wọ́ gomina ipinle Ọ̀yọ́, Ṣeyi Makinde tori pe o kuna lati ṣe awọn ohun idagbasoke to peye si ipinlẹ Oyo.

Adelabu sọ̀rọ̀ yìí nigba to u kede erongba rẹ lati dupo gomina ipinlẹ Oyo nin ọọfisi APC to n bẹ lágbègbè oke Ado, niluu ibadan.

Adelabu ni "Awọn ọmọ ipinlẹ Ọyọ lati apa Oke Ogun, Ibarapa, Ọyọ ati Ibadan ni wọn wa pẹ̀lú mi lati di gomina ipinlẹ Ọ̀yọ́ lọ́dún to n bọ ati pe, ẹgbẹ oṣelu APC náà tí ṣe tan lati gba ogo wọn pada lọwọ ẹgbẹ òṣèlú PDP."

"Ẹ lọ wo awọn ile ẹ̀kọ́, ile wosan wa ati ọrọ eto ẹ̀kọ́ wá, gẹgẹ bii ara ọpọlọpọ nnkan ta le tọka si pe idagbasoke ti yẹ kó de ba, lati igba tí ijọba to wa lóde ń ipinlẹ Oyo tí bẹ̀rẹ̀.

Àkọlé fídíò, Nígbà tí rẹ́kọ́ọ̀dù mí lókìkí kárí ayé, ẹ̀rù bà mí, mo ń ròó pé ọjọ́ ikú mi ti dé ni - Musiliu Haruna Isola

"Eto abo mẹhẹ, ọpọlọpọ eeyan lọ padanu ẹ̀mí toun ti dúkìá wọn nítorí aisi eto abo to muna doko fun awọn ọmọ ipinlẹ Oyo, ṣugbọn asiko ti to lati gba ijọba padà lọwọ awọn ẹgbẹ oselu PDP ati Seyi Makinde."

Adelabu ni yoo figagbaga pẹlu aṣọfin to n ṣoju aringbungbun Oyo nílé aṣọfin àgbà, Teslim Folarin, Akeem Alao, Oloye Niyi Akintola, pẹlu aṣofin Fatai Buhari, lati di ọmọ oye ti ẹgbẹ oselu APC yoo fà kalẹ ni eto ìdibo gomina ipinlẹ Oyo lọ́dún ọdun 2023.

Àkọlé fídíò, Tàá bá lè bá àwọn ọmọ tó pa Deborah ní Sokoto sọ̀rọ̀ pé ìwà ẹranko ni wọ́n hù, ó burú - Òṣèré Sokoti