Lagos Okada ban: A kò fi ti gbèdéke June 1 ṣe, a ti fòfin de ọ̀kadà, kèké ni àwọn ojúpópó ni Eko

Sanwo-Olu

Oríṣun àwòrán, @Mr_JAGs

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 3

Gomina ipinlẹ Eko, Babjide Sanwo -Olu ṣapejuwe igbesẹ naa gẹgẹ bi ọna akọkọ lati da aabo bo awọn ara ilu.

Ijọba ti ni awọn ti bẹrẹ si ni gba kẹkẹ Maruwa ati Ọkada to ba ti kọja ala ti wọn fi de wọn.

Wọn ni bio tilẹ jẹ pe Ọjọ Kini, Oṣu Kẹfa ni gbedeke ti ijọba fi lede lati fofin de lilo ọkada ati maruwa ni awọn opopona ati ijọba ibilẹ, awọn ti bẹrẹ si ni gba awọn ọkada to ba ti rufin.

Wọn ni awọn ijọba ibilẹ mẹfa ti ofin naa de ni Eti-Osa, Ikeja, Lagos Island, Lagos Mainland, Apapa ati Surulere.

''Ọkada 238 ati kẹkẹ maruwa 195 ni a ti gba lọwọ awọn to n wa ni oju popo paapaa ni opopona Iba si Badagry''.

Àkọlé fídíò, Nígbà tí rẹ́kọ́ọ̀dù mí lókìkí kárí ayé, ẹ̀rù bà mí, mo ń ròó pé ọjọ́ ikú mi ti dé ni - Musiliu Haruna Isola

''Awọn olọkada ati Maruwa naa n wa ọkọ won ni oju popo, eleyii to lodi si ofin.''

''Wọn ti le e gba ọna ti wọn ko fi ofin de titi di Ọjọ Kini, Oṣu Kẹfa, nipinlẹ Eko.''

Adari ikọ amuṣẹya ni ipinlẹ Eko, CSP Shola Jejeloye ni gbedeke naa ko da ofin ọdun 2018 to fi ofin de lilo ọkada ni ipinlẹ naa.

Okada

Oríṣun àwòrán, OTHERS

Ofin naa ni ko gbọdọ si ẹnikẹni ti yoo ma wa ọkọ loju popo ati lori afara ni ipinlẹ Eko.

O ni biotilẹ jẹpe ofin naa ti wa lati ọdun 2018, ajakalẹ arun Covid-19 lo tun j̣e ki o falẹ amọ wọn ti bẹrẹ bayii.

Bakan naa ni ijọba gboriyin fun awọn ara Eko to buwọlu igbesẹ naa, ti wọn si ni awọn faramọ ki ọkada, maruwa ye rin loju popo mọ.

Gomina ipinlẹ Eko, Babjide Sanwo -Olu ṣapejuwe igbesẹ naa gẹgẹ bi ọna akọkọ lati da aabo bo awọn ara ilu.

Ìdí tí Ìjọba ìpínlẹ̀ Eko fòfin de ọ̀kadà ní ìjọba ìbílẹ̀ mẹ́fà

Ijọba ipinlẹ Eko ti fofin de awọn ọlọkada ni ijọba ibilẹ mẹfa ọtọtọ ni ipinlẹ naa nitori eto abo.

Ofin tuntun yii ni yoo bẹrẹ si n fẹsẹ mulẹ lati ọjọ kinni, oṣu Kẹfa, ọdun 2022 yii.

Awọn ijọba ibilẹ ti ọrọ naa kan ni Ikeja, Lagos Mainland, Lagos Island, Eti-Osa, Surulere, ati Apapa.

Àkọlé fídíò, Tàá bá lè bá àwọn ọmọ tó pa Deborah ní Sokoto sọ̀rọ̀ pé ìwà ẹranko ni wọ́n hù, ó burú - Òṣèré Sokoti

Sanwo-Olu lo fi ikeke naa sita lọjọbọ lasiko ipade kan pẹlu awọn agbofinro.

O ni "A ko fẹ ri ọkada kankan ni awọn agbegbe bii Ikeja, Lagos Mainland, Lagos Island, Eti-Osa, Surulere, ati Apapa mọ."

Skip X post
Allow X content?

This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.

Warning: Third party content may contain adverts

End of X post

"Ofin tuntun yii jẹ ibẹrẹ iru rẹ, ofin naa yoo si bẹrẹ si n mulẹ lati ọjọ kinni, oṣu Kẹfa, ọdun ti a wa yii."

"A fẹ ki awọn ọlọkada mọ pe kii ṣe awọn agbegbe ti a darukọ yii nikan ni ako ti fẹ ri wọn mọ, ki awọn to wa lagbegbe to ku tete lọ maa wa iṣẹ mii ṣe."

Àkọlé fídíò, Wọ́n gbé Póò ìtọ̀ àti igbẹ́’ tó ti já nídìí lé mi lórí lọ dànù l’Eko, pẹ̀lú òúnjẹ́ mi lọ́wọ́ mi - Ajirebi

Lara awọn to wa nibi ipade ti ikede naa ti jade ni awọn ọga ọlọpaa kaakiri ipinlẹ Eko, to fi mọ awọn mii ti ọrọ eto eto abo kan.

Sanwo-Olu sọ siwaju nibi ipade naa pe "A ti n bu yin gbọ bayii, pe lati ọjọ kinnu, oṣu Kẹfa, a ko fẹ ri awọn ọlọkada kankan laarin igboro awọn ibi ti a durukọ yii mọ."

Àkọlé fídíò, 'Ọ̀pọ̀ ìgbà l'èmí gan fẹ́ du àwọn ipò òṣèlú kan, bíì '2015, 2019' àmọ́ mo tẹ 'slow' torí bàbà mi, Akala náà ń jáde'

'Sound Engineer' ti awọn afurasi ọlọkada pa nitori N100

Bo tilẹ jẹ pe kii ṣe igba akọkọ ree ti ijọba ipinlẹ Eko yoo fofin de ọlọkada, iroyin ni igbesẹ tuntun yii ko ṣẹyin iku okunrin kan ti orukọ rẹ n jẹ David Imoh ti awọn afurasi ọlọkada kan pa.

Awọn afurasi naa tu ologbe ọhun si ihoho, wọn lu niluu bara, wọn si tun dana sun Lekki, eyii to wa ni ijọba ibilẹ Eti Osa.

Ṣaaju ikede yii lọjọ Aje ni ijọba Eko ti kọkọ gbẹsẹle awọn ọkada ti iye rẹ ko din ni mẹtalelọgọfa ni Eti Osa yii kan naa, ti wọn si tun fi ṣikun mu awọn to n wa awọn ọkada ọhun.

Àkọlé fídíò, Títí ayé yóò fi parẹ́, wọ́n ó máa sọ̀rọ̀ sí Ànọ́bì ni, wọ́n ó sì máa bú Jésù ni, ẹ wá gbọ́ òótọ́ ohun tí Quaran sọ – Akeugbagold