Nnamdi Kanu: Ilé ẹjọ́ wọ́gilé àfikún ẹjọ́ tí ìjọba àpapọ̀ pè tako olórí IPOB

"Nnamdi Kanu arrested today": Ipob 'Nnamdi Kanu extradition arrest', how Nigerians react

Oríṣun àwòrán, Other

Ile ẹjọ giga to n gbọ ẹsun ti ijọba apapọ fi kan adari ẹgbẹ IPOB, Nnamdi Kanu, ti da ẹsun mẹfa ti ijọba apapọ fi kun ẹsun afurasi naa nu lọjọru.

Adajọ Binta Nyako wọgille ẹjọ naa lẹyin ti ijọba apapaọ sọ pe oun ko ṣe afikun ẹjọ naa mọ.

Igbesẹ ijọba yi lo n waye lẹyin ti olori ikọ agbẹjọro Kanu, Mike Ozekhome sọ fun adajọ pe ikọ olupẹjọ n mọọmọ fa ẹṣe ẹjọ naa nilẹ latari bo ṣe n ṣe afiku ẹjọ gan to gbe wa siwaju rẹ lakọkọ.

Ozekhome sọ fun ile ẹjọ ọhun pe igba keje ree ti ikọ olupẹjo yoo ṣe afikun ẹjọ to pe tako onibara oun.

Lẹyin naa ni adajọ Nyako gba ẹbẹ agbẹjọro naa wọle, to si sọ pe Kanu ko le tii fesi si afikun ẹjọ tuntun naa lọwọ yii nitori o nilo lati ka iwe ẹjọ naa ko le ni oye ẹsun to wa ninu rẹ.

Bawo ni ọrọ beeli Nnamdi Kanu ṣe ri?

Ileẹjọ ko gba beeli Nnamdi Kanu lasiko igbẹjọ rẹ to waye lẹyin ti agbẹjọro rẹ beere fun ki wọn gba beeli rẹ.

Agbẹjọro rẹ, Mike Ozekhome ni lai ṣe pe ileẹjọ dajọ pe eniyan jẹbi ẹsun ti wọn fi kan an, ko yẹ ko wa ni atimọle.

Bakan naa loni ki ileejọ ranti pe afi igba ti wọn ba dajọ pe o jẹbi, ko ni ẹsẹ kankan lọrun.

Amọ Shuaibu Labaran to jẹ agbẹjọro ijọba rọ ileẹjọ ko da ibeere fun beeli naa nu.

Àkọlé fídíò, Wọ́n gbé Póò ìtọ̀ àti igbẹ́’ tó ti já nídìí lé mi lórí lọ dànù l’Eko, pẹ̀lú òúnjẹ́ mi lọ́wọ́ mi - Ajirebi

Ki lo ti ṣẹlẹ ṣaaju?

Ìgbẹ́jọ́ Nnamdi Kanu tẹ̀síwájú nílé ẹjọ́ lónìí

Igbẹjọ adari ikọ IPOB tẹsiwaju loni ni ileẹjọ giga ti ijọba apapọ ni ilu Abuja.

Agbẹjọro rẹ, Binta Nyako ti sun igbẹjọ naa siwaju di Ọjọ Kejidinlogun ati Ikẹrindinlọgbọn, Oṣu yii lati gbe yẹwo boya wọn le e gba beeli rẹ.

Adari ikọ IPOB naa n koju ẹsun iwa iditẹgbajọba ati iwa igbesunmọmi.

Nnamdi Kanu naa ni wọn fi si ahamọ ikọ ọtẹlẹmuyẹ DSS ni Naijiria lati Oṣu Kẹfa, ọdun 2021.

Àkọlé fídíò, Títí ayé yóò fi parẹ́, wọ́n ó máa sọ̀rọ̀ sí Ànọ́bì ni, wọ́n ó sì máa bú Jésù ni, ẹ wá gbọ́ òótọ́ ohun tí Quaran sọ – Akeugbagold

Awọn ẹsun ti wọn fi kan Kanu ree…

  • Akọkọ ni pe o jẹ adari ikọ agbesunmọmi IPOB to n ditẹ gba ijọba nitori oun gbohunsafẹfẹ to si n sọrọ tako ijọba Naijiria.
  • Ekeji nipe Nnamdi Kanu n dunkoko mọ ijọba Naijiria pẹlu ipolongo pe ki awọn eniyan joko si ile wọn lai jade.
  • Ikẹta ni pe Nnamdi Kanu kede pe oun ni adari ikọ IPOB ti ijọba orilẹede Naijiria fofin de.
  • Ikẹrin nipe Nnamdi Kanu ṣe igbohunsafẹfẹ to si sọ fun awọn ọmọ ẹgbẹ rẹ lati ṣe ijamba fun awọn ẹṣọ agbofinro ni Naijiria.
  • Ikarun nipe Nnamdi Kanu tun sọ fun awọn eniyan rẹ ki wọn ṣekọlu si awọn ileeṣẹ ọlọpaa ni Naijiria.
  • Ikẹtala nipe wọn kede nipase igbohunsafẹfẹ pe ki awọn araalu ma a jo ohun elo ijọba apapọ to wa ni ilu Eko, eleyii to jẹ atọkasi ninu eto idokowo pẹlu ileeṣẹ nla nla ni Naijiria.
  • Ikarundinlogun nipe Nnamdi Kanu gbe ẹrọ redio Tram 50L to si gbe pamọ si inu ''container'' ni agbegbe Ubulisiuzor, ni ijọba ibilẹ Ihiala, ni ipinlẹ Anambra.