Ekiti 2022: Alága ẹgbẹ́ òṣèlú ADP ní ìpínlẹ̀ Ekiti fi ẹgbẹ́ sílẹ̀

Oríṣun àwòrán, roundoffnews
Lẹyin ọjọ́ diẹ, ti oludije fun igbakeji gomina lati inu ẹgbẹ́ oselu Action Democratic Party (ADP), fun idibo gomina ti yoo waye ni Ekiti l'oṣu to n bọ fi ẹgbẹ silẹ, alaga ẹgbẹ́ naa ti fi ẹgbẹ́ silẹ pẹlu.
Ọjọ Iṣẹgun ni Ogbẹni Olakunle Abegunde kede igbesẹ rẹ fun awọn akọroyin, n'ilu Ado-Ekiti.
Abegunde fi ẹsun kan awọn adari ẹgbẹ́ ADP lapapọ pe, wọn hu iwakiwa, ti wọn ko si ni àfojúsùn to daju fun ẹgbẹ́ ni imurasilẹ fun idibo gomina.
- Ki láwọn olóṣèlú Nàìjíríà rí tí wọ́n fi ń ṣé àbẹ̀wò sí ìyá arúgbó yìí ní Katsina?
- Ikọ ajínigbé jí ìyàwó ọ̀sìngín gbé wọ́n f'ipá bá a lòpọ̀ làìmọye ìgbà, àṣírí tú!
- Ohun tó yẹ kí ìjọba ṣe nìyí bí wọ́n ṣe ń dá ẹ̀jọ́ ìkú Deborah Samuel- Agbẹjọrò Kayode Ajulo
- A bá òkú Akẹ́kọ̀ọ́ Poly Ibadan nílé ìyàgbẹ́ to ṣì dì ọ̀rẹ́bìnrin rẹ̀ mú - Aráàdúgbò
- Ìjọba ìpínlẹ̀ Eko fòfin de ọ̀kadà ní ìjọba ìbílẹ̀ mẹ́fà
- Ilé ẹjọ́ wọ́gilé àfikún ẹjọ́ tí ìjọba àpapọ̀ pè tako Nnamdi Kanu
- Wo àwọn èèkàn ìjọba márùn ùn tí wọ́n fẹ̀sùn àjẹbánu kàn lábẹ́ ààrẹ Buhari
- Ẹ kò gbọdọ̀ mu igbó àti sìgá lẹ́nu iṣẹ́ mọ́ – Makinde kìlọ̀ fáwọn ọmọ ẹgbẹ́ onímọ́tò
- Ẹ dákun, ẹ má jẹ̀ẹ́ kí ọkọ mi fi lílù pamí – Ìyàwó rawọ́ ẹ̀bẹ̀ sí ilé ẹjọ́
O ni owo ara oun ni oun fi n gbọ bukata ẹgbẹ́ naa nipinlẹ Ekiti, lati ọdun 2017 ti wọn ti da a silẹ.
Saaju ni Akọwe apapọ fun ẹgbẹ́ ADP, kede pe awọn ti yọ Ọgbẹni Abegunde kuro nipo.
"Ẹgbẹ́ naa ko yọnda owo kankan ri bo ti wu ko kere mọ, ninu gbogbo owo to n wọle lati ipinlẹ Ekiti ati àwọn ipinlẹ yooku ni Naijiria.
" Oṣù mẹta sẹ́yìn ni mi o ba ti kuro ninu ẹgbẹ́, sugbọn n kò ṣe bẹ́ẹ̀, ki igbesẹ mi ma ba akitiyan oludije ninu idibo gomina to n bọ, jẹ́."
Arabinrin Kemi Elebute-Halle, lo n soju ẹgbẹ́ naa.
Arakunrin Abegunde ni ṣùgbọ́n nitori bi awọn adari ẹgbẹ́ ṣe kede pe wọn da oun duro fun asiko kan," mo kuku fi asiko yii kede pe mi o ṣe ẹgbẹ́ oselu ADP mọ lati wakati yii lọ".
Bo tilẹ̀ jẹ́ pe ko kede ẹgbẹ́ oselu to fẹ darapọ mọ bayii, Ọgbẹni Abegunde sọ pe oun yoo ṣe ipade pẹlu ẹbi ati awọn alatilẹhin oun ni gbogbo ijọba ibilẹ to wa ni ipinlẹ Ekiti, lati sọ igbesẹ to kàn.
Ọjọ kejidinlogun, oṣu Kẹfa, ọdun 2022, ni idibo si ipo gomina yoo waye nipinlẹ Ekiti.














