Police Parade Kidnap syndicates:Wo bí ọwọ́ ọlọ́pàá ṣé tẹ́ àwọn ìkọ ajínigbé tó jí akẹ́kọ̀ọ́ fásítì, ìyàwó tuntun gbé

Oríṣun àwòrán, NIGERIA POLICE
Ileeṣẹ ọlọpaa orileede Naijriia ti ṣafihan awọn afurasi ọdaran lori oriṣi ẹsun to fi mọ ijinigbe ati ifipabanilopọ.
Ninu awọn ti wọn ṣafihan wọn la ti ri awọn afurasi ajinigbe to wa nidi iṣẹlẹ ijingbe awọn akẹkọọ ile ẹkọ fasiti Greenfield ni Kaduna.
Bẹẹ naa ni wọn tun ṣafihan awọn afurasi ajinigbe to wa nidi ijinigbe awọn akẹkọọ ile ẹkọ Bethel ni ọdun 2021.
Alukoro ọlọpaa Naijiria Olumuyiwa Adejobi lo ṣafihan awọn afurasi yii fawọn akọroyin nilu Abuja.
- Bàbá ọlọ́mọ méjì fi ipá bá ọmọ ọdún mẹ́rin lò pọ̀; Adájọ́ rán an ní ẹ̀wọ̀n gbére
- Ìjọba ìpínlẹ̀ Eko fòfin de ọ̀kadà ní ìjọba ìbílẹ̀ mẹ́fà
- Ilé ẹjọ́ wọ́gilé àfikún ẹjọ́ tí ìjọba àpapọ̀ pè tako Nnamdi Kanu
- A bá òkú Akẹ́kọ̀ọ́ Poly Ibadan nílé ìyàgbẹ́ to ṣì dì ọ̀rẹ́bìnrin rẹ̀ mú - Aráàdúgbò
- Wo àwọn èèkàn ìjọba márùn ùn tí wọ́n fẹ̀sùn àjẹbánu kàn lábẹ́ ààrẹ Buhari
O ni lapapọ awọn ri nkan ija mọkanlelọgọta, ọta ibọn ọgọrinlelọọdunrun din mẹrin ati owo to to miliọnu meji Naira gba lọwọ awọn afurasi yi.
Adejobi sọ pe ọdaran mọkalelọgbọn lawọn si ri mu nipa iṣẹ ẹka ọtẹlẹmuyẹ ileeṣẹ ọlọpaa.
Ni ti tawọn ajinigbe o sọ pe awọn ri afurasi meji kan Aminu Lawal ati Murtala Dawu ti wọn ṣiṣẹ pọ pẹlu baba isalẹ ajinigbe Yellow Ashana mu.
Wọn jẹwọ pe awọn lọwọ ninu ijinigbe ati iṣekupani ọlọpaa meji ati fijilante kan lọdun 2021.

Oríṣun àwòrán, NIGERIA POLICE
O ni wọn tun jẹwọ pe iṣẹlẹ ijinigbe awọn akẹkọọ fasiti Gtreenfield ni Kaduna ati papa eeyan marun un ninu wọn lẹyin ti wọn san owo idoola ko ṣẹyin awọn.
Alukoro ọlọpaa ni iwadii awọn fi han pe agbegbe Dan Hunu, Kekebi, Dan Busha Rido, Maraban Rido, ati Kumi Sata ni wọn ti n ṣiṣẹ aburu wọn.
Bakan naa ni awọn agbofinro kede pe awọn ri ikọ ajinigbe ẹlẹni marun un mii ti wọn n ṣọṣẹ lagbegbe Adamawa ni Naijiria si Burha Fituha ati Kesu ni Cameroun.

Oríṣun àwòrán, NIGERIA POLICE
Gbogbo awọn ọmọ ikọ ajinigbe yi jẹ ọmọ ilu Mubi ti wọn a si maa foju sun awọn to ba ni ile ati ọkọ to rẹwa.
Wọn jẹwọ pe awọn lawọn ji iyawo tuntun kan gbe ti wọn si ba lopọ laimọye igba ni ijọba ibilẹ Askira Uba.
Koda wọn tun gba miliọnu kan Naira ki wọn totu arabinrin naa silẹ.
Igba ti wọn fẹ gba owo idoola miliọnu meji Naira lọwọ AlhajiMoni ni abule Buladega lọjọ kọkanla oṣu yi ni ọwọ awọn agbofinro tẹ.
















