Deborah Samuel: Sokoti Alagbede Orun ní bí Ànọ́bì bá lè fi ìfẹ́ hàn sẹ́ni tó ń ṣe aburú sí i, kí ni ti alágbàtà?

Àkọlé fídíò, Tàá bá lè bá àwọn ọmọ tó pa Deborah ní Sokoto sọ̀rọ̀ pé ìwà ẹranko ni wọ́n hù, ó burú - Òṣèré Sokoti

Gbajugbaja oṣere Tiata to tun jẹ agba oṣere Yoruba, Adewale Abdulrasak ti ọpọlọpọ mọ sí Sokoti Alagbẹdẹ Ọrun ti sọ ero tirẹ lori bi awọn kan ṣe ṣekupa Deborah Samuel ti wọn tun dana sun un ni ilu Sokoto.

Deborah jẹ ọdọbinrin ẹlẹsin Kristẹni kan ti awọn akẹgbẹ rẹ ni Kilaasi fi ẹsun kan pe o sọrọ abuku si Anọbi.

"Inu mi tilẹ dun pe lori ọrọ ọmọ ti wọn pa yẹn awọn adari ẹsin kan n bu ẹnu atẹ luu.

amọ mo ti ri lori ayelujara lori foonu mi ti awọn adari ẹsin mii n sọ pe ti ẹba ti ri ẹnikẹni to sọrọ abuku si Anọbi, ẹ pa a, haa eyi o daraa".

Lọgan ni ọkan rẹ lọ sibi ijijagbara fun Yoruba Nation ti awọn ọmọ Yoruba kan n ja fun.

O ni ṣe iru nkan to yẹ ko maa wọle sinu ọpọlọ awọn ọmọ wa niyẹn?

O ṣalaye pe Anọbi ko ni ki awọn eeyan lọ maa paayan. O ṣe apẹrẹ ọkunrin to maa n to ẹgun ati igbẹ soju ọna ti Anọbi ba fẹ gba kọja amọ o ṣaarẹ lọjọ kan, Anọbi si tun lọ wo o nile o fi ifẹ han sii.

Agba oṣere, okoti n pe fun irẹpọ laarin gbogbo eniyan to si ni iwa ẹranko ni awọn to pa Deborah hu.

O ni gbogbo eeyan lo rii bi awọn to ṣe iṣẹ aburu yii ṣe pọ to amọ eeyan meji pere ni ijọba ri mu latọjọ yii.