North Korea: Wo bí orílẹ̀-èdè yí ṣé n ló oògùn ibilẹ láti fí tọjú ààrùn Covid-19

Oríṣun àwòrán, EPA
- Author, Rachel Schraer and Wanyuan Song
- Role, BBC Reality Check
Orileede North Korea n koju ajakalẹ aarun Covid-19 pẹlu bi ọpọ eeyan ko se gba abẹrẹ ajẹsara ti wọn ko si lanfaani oogun to n koju aarun yi.
Ni ibẹrẹ ọdun 2020 ni orileede naa ti ibode rẹ lati le dena kawọn eeyan ko aarun naa wọ ilẹ wọn.
Titi di asiko yi, awọn olori ilẹ naa ti lawọn ko fẹ iranwọ lati ọdọ araata.
Bẹẹ naa ni ileeṣẹ iroyin ilẹ naa ti daba kawọn eeyan maa lo oogun ibilẹ fi koju nkan ti wọn pe ni ''iba''
Wo awọn nkan ti wọn da laba faraalu lati fi koju aarun Covid-19.
Nkan gbigbona
Fun awọn to ba rẹ gidi gaan,ileeṣẹ iwe iroyin ilẹ naa Rodong Simnun daba pe ki wọn lo omi gbona pẹlu ginger,oyin tabi nkan mii.

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Lootọ mimu nkan gbigbona le dẹkun awọn apẹrẹ Covid-19 bi ikọ ọfun didun to si le jẹ ki omi pada si ara eeyan to ba ti padanu omi ara.
Ginger naa ati ewe kan ti wọn n pe orukọ rẹ ni willow leaf naa a maa di inira ku lara.
Ṣugbọn wọn kii ṣe oogun itọju aarun yi
Gbigbo Omi iyọ lẹnu
Ileeṣẹ iroyin ilẹ naa ba awọn tọkọtaya kan to da lilo omi ti wọn da iyọ sinu rẹ laarọ ati lalẹ.
Tori naa wọn tifi ẹgbẹgbrun tọọnuiyọ ranṣẹ si Pyonyang lati fi peelo oogun gẹgẹ bi ileeṣẹ iroyin ilẹ naa ṣe jabọ
Awọn iwadii kan fi han pe bi eeyan ba gbo omi iyọ jigi lọna ọfun eleyi le koju kokoro aifojuri to ba n fa ọfikin.
Amọ ko si ẹri to fihan pe eleyi le dẹwọ itankalẹ Covid-19.

Oríṣun àwòrán, Reuters
Omi ọsẹ abufọnu le pa awọn kokoro gẹgẹ bo ṣe fihan ninu laabu nigba ti wn fi ṣe iwadii kan.
Amọ eleyi ko daju pe yoo le koju kokoro yi lara awọn eeyan.
Awọn eeyan maa n ko aarun Covid-19 nipa fifa atẹgun wọ imu wọn tabi ẹnu.Tori naa gbigbo omi jigi le koju ọna kan ṣoṣo.
Ti kokoro yi ba si ti wọle, niṣe lo maa n rẹsi ni ti yoo si wọ inu awọn ẹya ara mii nibi ti gbigbo omi jigi lẹnu lo le de
Oogun ara riro,apakokoro
Ileeṣ iroyin ilẹ naa tun sọ pe kawọn eeyan maa lo oogun ara riro bi ibuprofen ati oogun apa kokoro bi amoxicillin ati awọn miran.

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Ibuprofen ati Paracetamol le mu ki ara to n gbona walẹ ti a si tun maa koju awọn apẹrẹ mii bi ori fifọ ati ọfun didun.
Amọ wọn ko le mu kokoro Covid-19 kuro tabi ki wọn kọdi idagbasoke rẹ.
Oogun to n pa kokoro wa fun awọn kokoro bakiteria kii se fun awọn kokoro virọọsi.












