“Ojú mi kòró báyìí ni àwọn ọ̀rẹ́ mi mẹ́ta kú sínú odò”

One of di three friends wey die for river for Bichi Kano state

Ọjọ manigbagbe ni Ọjọ Kẹjidinlogun, Oṣu Karun un, ọdun 2022 ti ọfọ ṣe ni ilu Kano nibi ti awọn ọdọlangba mẹta ti ri sinu odo adagun ti wọn ti lọ wẹ.

Ọkan lara awọn ti iṣẹlẹ naa ṣoju wọn ni oun wa nibẹ nigbati awọn ọrẹ oun mẹtẹẹta si ku sinu omi.

Musa Abubakar, ẹni ọdun marundinlọgbọn, Isyaku Bashir, ẹni ọdun mẹtalelọgun ati Nazifi Ibrahim ni wọn sọ ẹmi wọn nu sinu adagun odo ni nkan bi aago mọkanla.

Awọn mẹtẹẹta ni wọn jọ wa fun Majisi, eleyii to tunmọ si pe wọn fẹ yin Muhammed, pẹlu igbagbọ pe wọn yoo gba oriyin ni aye to n bọ tabi alujanna.

''Awọn ara agbegbe Karaye lo pe wa si ibi ayẹyẹ naa, to si yẹ ka pada si Bishi ni ọjọ naa, amọ wọn bẹ wa pe ka sun mọju nitori ilẹ ti su ni Karaye.''

''Ni aarọ ọjọ naa bi awọn eniyan ṣe n pẹ ni baluwẹ ni agbegbe Karaye, ni ọkan lara wọn wa gba wọn niyanju pe ki wọn lọ si odo lọ wẹ.''

''A ko kọkọ fẹ lọ amọ ọkan lara wa to pẹlu awọn to ku sinu odo naa ni ko si ohun ti yoo ṣẹlẹ.''

Àkọlé fídíò, Tàá bá lè bá àwọn ọmọ tó pa Deborah ní Sokoto sọ̀rọ̀ pé ìwà ẹranko ni wọ́n hù, ó burú - Òṣèré Sokoti

Bi iṣẹlẹ naa ṣe ṣẹlẹ ni yii…

Ọna meji ni odo naa ni ti a si yago kuro ni apa ibi to jin,a tun ri awọn ọmọde ninu omi naa ti wọn n ṣere.

Isyaku lo kọkọ bọ aṣọ to kosi odo ki Nazifi to darapọ mọ wọn, amọ o ripe wọn ko luwẹ wa si oke lo ba ko si inu odo lati lọ ranwọnlọwo.

Amọ oun naa ko pada soke ni a ba ripe nkan buruku ti bẹrẹ si ni ṣẹlẹ, bi a ṣe pariwo fun iranwọ niyẹn.

Amọ iranwọ ko wa ni kiakia, nigba ti awọn eniyan de lati doola ẹmi wọn, oku wọn ni wọn ba.

Àkọlé fídíò, Wọ́n gbé Póò ìtọ̀ àti igbẹ́’ tó ti já nídìí lé mi lórí lọ dànù l’Eko, pẹ̀lú òúnjẹ́ mi lọ́wọ́ mi - Ajirebi

Idris to ṣalaye iṣẹlẹ naa ni oun ati ọrẹ oun ko lee wẹ ni awọn ko ṣe kosi odo lati doola ẹmi awọn ọrẹ oun.

Baba Musa lasiko to n sọrọ ni oun ko lee gbagbe bi ọmọ oun ṣe kuro ni ile, ki o to lọ si ilu Karaye.

O ni kii ṣe mọlẹbi nikan ni yoo ṣedaro Musa amọ gbogbo awọn ara adugbo ti wọn ma n wa gba owo ni ọwọ rẹ ni ṣọọbu POS rẹ.

Alukoro fun ileeṣẹ panapana ni Kano ni awọn ko gbọ nkankan ni kiakia amọ nigba ti wọn fi pe awọn, oku awọn ọmọ mẹta naa ni awọn yọ kuro ninu odo.

Bakan naa ni wọn kilọ fun awọn eniyan ki wọn ye ko wọ inu odo ti wọn ko bamọ nkankan nipa ẹ abi agbegbe naa.

Àkọlé fídíò, Títí ayé yóò fi parẹ́, wọ́n ó máa sọ̀rọ̀ sí Ànọ́bì ni, wọ́n ó sì máa bú Jésù ni, ẹ wá gbọ́ òótọ́ ohun tí Quaran sọ – Akeugbagold