Alaba Rago Market: Ìjọba Eko fún àwọn ọlọ́jà Alaba Rago ní gbèdéke láti fi ibẹ̀ sílẹ̀ fún àtúnṣe, wọ́n ní ó ti di ibùba àwọn ọ̀daràn

Oríṣun àwòrán, Jubril A. Gawat/ twitter
Nnkan n yan lọja Alaba Rago nipinlẹ Eko bẹẹni ọkan awọn ọlọja nibẹ ko balẹ lẹyin ti ijọba ipinlẹ Eko gbe gbedeke ọjọ mẹrinla le wọn lọwọ lati fi fi ọja naa silẹ.
Ijọba ipinlẹ Eko ni igbesẹ naa wa lati fi ṣe atunṣe ọja naa ki o le ba igba mu.
Ikọ amuṣẹya ti ijọba ipinlẹ Eko gbe kalẹ lori ọrọ abo, 'Lagos State task force' lo fi gbedeke naa to wọn leti lasiko to bẹ ọja naa wo pẹlu ajọ ọrọ ayika nipinlẹ Eko.
- Àwọn òṣìṣẹ́ DSS gbìyànjú láti dóòlà Deborah, àmọ́ ọ̀pọ̀ èèrò borí wọn - Gómìnà Tambuwal
- Kí ló ṣẹ̀lẹ̀ tí Lizzy Anjorin ń wọ́ ìdí ìjọ Celestial tuurutu?
- Ọmọ orílẹ̀-èdè Denmark pa ìyàwó rẹ̀ ọmọ Naijiria àti ọmọ wọn l'Eko, ìjọba dájọ́ ikú nípa yíyẹgi fún un
- Látilẹ̀ ni mo ti fẹ́ràn orin ìjọ Kérúbù àmọ́ ẹlẹ́sìn mùsùlùmí àti krìstẹ́nì ni mí - Qdot
Ikọ naa ni lẹyin ifikuluku pẹlu igbimọ iṣejọ ipinlẹ Eko atawọn aṣoju ọja ọhun ni gomina fi fọwọ si gbedeke naa.
Bakan naa naa ni ikọnaa tun jẹ ko di mimọ pe lara awọn ohun to n kọ ijọba ipinlẹ Eko lominu nipa ọja naa ni bi awọn iṣẹlẹ kan lọja naa ṣe n ṣe akoba fun ọrọ abo ni ipinlẹ Eko.
Wọn ni laipẹ yii lawọn ileeṣẹ agbofinro kẹẹfin pe pupọ awọn kọlọransi ọdaran to ṣọṣẹ kaakiri tibu toro ipinlẹ lo ti sọ ọja naa di ibuba wọn.
Amọṣa awọn ọlọja lọja Alaba Rago ko ṣai fi aidunu wọn han si igbesẹ naa eyi ti wọn ni ko ṣẹlẹ ri lati bi aadọta ọdun ti awọn ti wa ninu ọja naa.
Alaga awọn ọlọja lọja naa, Umaru Nagogo ṣalaye fun BBC pe iyalẹnu ni ikede naa jẹ fun awọn.
Ọja Alaba Rago gẹgẹ bi ipenija ọrọ abo

Oríṣun àwòrán, Jubril A. Gawat/ twitter
Oniruuru iroyin lo ti n waye nipa ọja yii fun igba pipẹ lori ọrọ abo ti ọpọ si n kan sara si ijọba Eko lori igbesẹ naa pe eyi to ti tọjọ ni.
Awọn ọlọpaa ni gbedeke naa waye lẹyin ọpọlọpọ ijiroro laarin igun gbogbo ti ọrọ kan.

Oríṣun àwòrán, Screnshot/ twitter

Oríṣun àwòrán, Screnshot/ twitter

Oríṣun àwòrán, Screnshot/ twitter
Laipẹ yii lawọn agbofinro ti fi panpẹ ofin mu ọpọlọpọ awọn ọdọ lagbegbe naa pẹlu ibọn atawọn ohun ija oloro loniran-an-ran lọja naa.
Awọn alaṣẹ si ti sọ pe lọja naa ni wọn n fi ṣe ibuba lati maa hu iwa ọdaran kiri.

Oríṣun àwòrán, Screnshot/ twitter
Ọkan lara awọn aṣiwaju lọja naa, Alaaji Adamu Katagum ṣalaye pe akoba diẹ kọ ni igbesẹ naa yoo mu ba owo wọn, paapaajulọ karakata wọn pẹlu awọn onibara lati awọn orilẹede miran bii Benin, Togo, Ghana ati bẹẹbẹẹ lọ.
O ni awọn ko tako igbesẹ lati ṣe atunṣe ati atunto ọja naa ṣugbọn o de ba awọn lojiji.















