Deborah Samuel: Àwọn òṣìṣẹ́ DSS gbìyànjú láti dóòlà Deborah, àmọ́ ọ̀pọ̀ èèrò borí wọn - Gómìnà Tambuwal

Oríṣun àwòrán, other
Gomina ipinlẹ Sokoto, Aminu Tambuwal, ti tan imọlẹ ọtun si iṣẹlẹ iku akẹkọọ ile ẹkọ giga imọ ẹkọ, Shehu Shaaari ti awọn kan dana sun ni ọsẹ to kọja.
Awọn akẹkọọ naa to jẹ ẹlẹsin Musulumi dana sun Deborah Samuel, to wa ni ipele keji, laaye, nitori pe "o sọrọ odi si Anọbi" ni ori ayelujara Whatsapp.
Gomina Tambuwal sọ pe tako igbagbọ ọpọ eeyan, o ni awọn oṣiṣẹ ajọ alaabo ọtẹlẹmuyẹ DSS gbiyanju lati doola Deborah, ṣugbọn awọn eero kapa wọn.
O sọ eyi fun awọn akọroyin lasiko to gbe ipolongo ibo aarẹ rẹ lọ si ipinlẹ Delta, lọjọ Ẹti.
Gẹgẹ bi iwe iroyin Daily Post ṣe sọ, Gomina Tambuwal sọ pe awọn oṣiṣẹ alaabo DSS de ibi iṣẹlẹ naa ki wọn o to pa Deborah.
"Wọn ti kọkọ gba a lọwọ awọn to n lu u, amọ nibi ti wọn ti n pè fun iranlọwọ lati awọn baraaki ologun, ni awọn eero naa kapa wọn."
- Ohun tó yẹ kí ìjọba ṣe nìyí bí wọ́n ṣe ń dá ẹ̀jọ́ ìkú Deborah Samuel- Agbẹjọrò Kayode Ajulo
- A bá òkú Akẹ́kọ̀ọ́ Poly Ibadan nílé ìyàgbẹ́ to ṣì dì ọ̀rẹ́bìnrin rẹ̀ mú - Aráàdúgbò
- Láí ṣẹ̀ láí rò, wọ́n jó Ṣọ́ọ́ṣì mi pátápátá ní Sokoto, ìrírí mi rèé - Pasitọ ìjọ Celestial
- Agbẹjọ́rò 34 táa tán nílé ẹjọ́, bí wọ́n ṣe sọ àwọn afurasí tó lọ́wọ́ nínú ikú Deborah Samuel sẹ́wọ̀n rèé
O ni lọwọlọwọ, meji lara awọn oṣiṣẹ DSS to gbiyanju lati doola Deborah, lo wa nileewosan, nitori ifapara ti wọn ni.
"Ori ẹnikan fọ́, apá ẹnikeji kán."
Gomina sọ pe awọn oṣiṣẹ alaabo naa duro yika yaara kan ti wọn kọkọ ti ọmọbinrin naa mọ, amọ ipa wọn ko ka ọpọ eero to yabo wọn.
"Kii ṣe pe wọn fi oloogbe silẹ l'oun nikan."
Iwọde waye lẹyin ti ọwọ ọlọpaa tẹ afurasi meji
Lẹyin ọjọ diẹ ti wọn pa Deborah, ni iwọde bẹrẹ ni Sokoto lori bi ileeṣẹ ọlọpaaa ṣe mu meji lara awọn afurasi to dana sun akẹkọọ naa.
Awọn olufẹhonuhan naa ni awọn n fẹ ki ileeṣẹ ọlọpaa Sokoto tu awọn meji ti wọn fi satimọle lori iku akẹkọọ naa silẹ.
Awọn ọdọ naa tilẹ tun gbiyanju lati kọlu aafin Emir Sokoto, Alhaji Sa'ad Abubakar kẹta, ti wọn si ba ọpọ dukia araalu jẹ, wọn tun dana sun ṣọọṣi ijọ Sẹlẹ kan.
Iwọde naa mu ki ijọba ipinlẹ Sokoto kede ofin konile-o-gbele oni wakati mẹrinlelogun.
Ile ẹjọ ni ki wọn ju awọn afurasi lori iku Deborah si ẹwọn
Ọjọ Aje, ọjọ kẹrindinlogun, oṣu Karun-un, ni ileeṣẹ ọlọpaa gbe awọn afurasi meji ti ọwọ tẹ lori iku Deborah Samuel, Bilyaminu Aliyu ati Aminu hukunci, lọ sile ẹjọ.
Lẹyin ifarahan nile ẹjọ, ile ẹjọ sun igbẹjọ naa si ọjọ mii ti wọn da lati ṣagbeyẹwo beeli awọn afurasi, ti awọn agbẹjọro wọn beere fun.
Nigba ti wọn pari ni adajọ paṣẹ pe ki wọn ko awọn afurasi naa lọ sẹwọn.
Wọn ti sin oku Deborah

Awọn mọlẹbi oloogbe naa ti sin oku rẹ ni ilu Tunga, to wa ni ijọba ibilẹ Rijau, ni ipinlẹ Niger pẹlu omije loju.
Baba Deborah Samuel, Ọgbẹni Emmanuel Garba sọ pe idaji ile oun lohun lu ni gbanjo lati ran ọmọ naa lọ sile ẹkọ, oun si ti n reti ọjọ ti yoo pari ẹkọ naa ki wọn to ge ẹmi rẹ kuru.















