Corpse Found on MMIA Lagos Runway: Àjọ ìrìnnà òfurufú ní Nàìjíríà, FAAN bẹ̀rẹ̀ ìwádìí láti mọ bí òkú ènìyàn se dé pápákọ̀ òfúrufú Muritala Muhammed l'Ekoo

Oríṣun àwòrán, Screenshot
Àjọ tó ń rí sí ètò ìrìnnà òfurufú ní Nàìjíríàní, FAAN, ní àwọn kò tíì le sọ pàtó tàbí mọ ohunkóhun nípa òkú ènìyàn tí wọ́n ṣàwárí níbi ojú ọ̀nà tí àwọn ọkọ̀ òfurufú máa ń gbà ní pápákọ̀ òfurufú Muritala Muhammed, ìpínlẹ̀ Eko.
Àtẹ̀jáde kan látọwọ́ FAAN ní ọjọ́ Ẹtì, ogúnjọ́, oṣù karùn-ún, ọdún 2022 fi ìdí rẹ̀ múlẹ̀ wí pé lóòótọ́ ni àwọn rí òkú ọkùnrin kan níbẹ̀ tí àwọn sì ti bẹ̀rẹ̀ ìwádìí lórí òkú náà.
Lẹ́yìn wákàtí mẹ́rìnlélógún, bí ọkùnrin náà ṣe rí àyè wọ inú ọgbà ọ̀hún àti ohun tó ṣokùnfà ikú rẹ̀ ṣì ṣókùnkùn sí àjọ FAAN tí wọ́n sì ń ṣèwádìí ṣùgbọ́n tí kò tíì sí ohun kan pàtó tí wọ́n le sọ lórí ìṣẹ̀lẹ̀ náà.
- Àwọn alákatakítí ẹ̀sìn pa èèyàn mẹ́fa, dáná sun ṣọ́ọ̀bù méje ní Bauchi lórí ẹ̀sùn sísọ̀rọ̀ òdì sí Islam
- Iléeṣẹ́ ọlọ́pàá nawọ́ gán afurasí mẹ́fà lórí ikú "Sound Engineer"
- Ìjọba Eko fún àwọn ọlọ́jà Alaba Rago ní gbèdéke láti fi ibẹ̀ sílẹ̀ fún àtúnṣe
- Àjọ tó ń mójútó iléeṣẹ́ Reluwé fagilé ìwọlé ìgbòkègbodò lójú irin Abuja-Kaduna
- Ọmọ orílẹ̀-èdè Denmark pa ìyàwó rẹ̀ ọmọ Naijiria àti ọmọ wọn l'Eko, ìjọba dájọ́ ikú nípa yíyẹgi fún un
- Látilẹ̀ ni mo ti fẹ́ràn orin ìjọ Kérúbù àmọ́ ẹlẹ́sìn mùsùlùmí àti krìstẹ́nì ni mí - Qdot
- A kò fẹ́ kí Kumuyi wá ṣe ìsọjí ìta gbangba nílùú Abia – IPOB
- Lẹ́yìn wákàtí díẹ̀ tí wọ́n sin òkú n'Ibadan, àwọn afurasí olóogùn owó gé orí rẹ̀ lọ
- Mo ti ṣetán láti gba ìjọba lọ́wọ́ Makinde lọ́dún 2023 - Adebayo Adelabu
- "Láti àkókò yìí lọ, àwọn obìnrin gbọ́dọ̀ máa bo ojú wọn lórí tẹlifíṣọ̀nù"
- Tea àti omi iyọ̀ ni èròjà tí orílẹ̀-èdè yìí fí n kojú ààrùn COVID-19
Ní nǹkan bí aago kan òwúrọ̀ ní àwọn aláṣẹ pápákọ̀ òfurufú náà gbé ẹ̀ka ojú ọ̀nà náà tì pa fún ìgbà díẹ̀ ní ọjọ́bọ̀ nítorí ìṣẹ̀lẹ̀ yìí.
Alaye lóri bi wọn ṣe ri oku naa
Agbẹnusọ fun FAAN, Faithful Hope-Ivbaze nínú àtẹ̀jáde kan ní àwọn ti bẹ̀rẹ̀ ìwádìí lórí ìṣẹ̀lẹ̀ náà.
Ó ṣàlàyé wí pé nígbà tí àwọn òṣìṣẹ́ pápákọ̀ òfurufú fẹ́ ṣe ìtọ́jú ibi ojú ọ̀nà náà ni wọ́n rí òkú ọkùnrin náà nílẹ̀ tí wọ́n sì fi tó àwọn aláṣẹ tí ọ̀rọ̀ kan létí lẹ́yẹ ò sọkà.
Bákan náà ló ní àwọn ti fi ọ̀rọ̀ náà tó àgọ́ ọlọ́pàá tí pápákọ̀ náà létí tí wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ lórí rẹ̀.
Nígbà tó ń sọ̀rọ̀, onímọ̀ nípa ètò ààbò, tó tún ti fìgbà kan rí jẹ́ òṣìṣẹ́ ọmọ ogun tẹ́ka pápákọ̀ òfurufú Muritala Muhammed, John Ojikutu ní ó pọn dandan láti ṣe àwárí bí ẹni náà ṣe le dé irú inẹ̀ yẹn ní pápákọ̀ náà.
Ojikutu ni ọkùnrin náà ṣe rí àyè dé irú àyè tó ṣe pàtàkì ní pápákọ̀ òfurufú náà nílò àmojútó tó péye àti wí pé ó fihàn wí pé ètò ààbò pápákọ̀ òfurufú ọ̀hún kò múná dóko tó.
Ó ní òdì tí wọ́n mọ yíká pápákọ̀ òfurufú náà k]o dára tó fún ààbò pẹ̀lú pé onírúurú ewu ló ń kó ọgbà náà sí.
Ó fi kun pé láìpẹ́ yìí ni ìjàmbá kan kò bá wáyé nígbà tí ọkọ̀ ayọ́kẹ́lẹ́ kan fẹ́ lọ forí sọ ọkọ̀ òfurufú Dana nígbà tó fẹ́ gbéra kúrò nílẹ̀ ní nǹkan bí oṣù mélòó sẹ́yìn.
Bákan náà ló ní lọ́dún 2019 ní ènìyàn kan rí àyè wọ ibẹ̀ tó sì lọ gun orí ọkọ̀ òfurufú Air Peace tó ti gbéra nílẹ̀ àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ.
Ó wá pè fún àmójútó pápákọ̀ náà ju ti àtẹ̀yìn wá lọ.
















