Bauchi: Àwọn alákatakítí ẹ̀sìn dáná sun ilé mẹ́fà, ṣọ́ọ̀bù méje ní Bauchi lórí ẹ̀sùn sísọ̀rọ̀ òdì sí Islam

Aworan rogbodiyan kan

Oríṣun àwòrán, other

Ọrọ ija ẹsin tun gbẹnutan nipinlẹ Bauchi nibi ti awọn eeyan kan tun ti kọlu alaafia ilu lori ẹsun pe awọn kẹẹfin eeyan kan to sọrọ odi si ẹsin wọn.

Ọpọ ile ati ṣọọbu ni wọn da ina sun ti ọpọ eeyan si tun ṣeṣe lasiko ti awọn ọdọ alakatakiti ẹsin naa ṣọṣẹ ni ijọba ibilẹ Warji nipinlẹ Bauchi.

Alukoro fun ileeṣẹ ọlọpaa ni ipinlẹ Bauchi, SP Ahmed Mohammed Wakil ṣalaye ninu atẹjade kan lọjọ Abamẹta pe awọn ọdọ naa "dana sun ile mẹfa, ṣọbu meje" lasiko ti wọn fi ṣe ikọlu naa nitori ọrọ atẹjade kan ti wọn ni eeyan kan fi sori ayelujara ti wọn foju wo gẹgẹ bi ọrọ odi si anọbi Mohammed, aṣiwaju ẹsin Islam.

Bakan naa ni atẹjade naa fi kun un pe ọpọ eeyan lo fi ara pa lasiko ikọlu awọn ọdọ naa.

Ki ni lọpaa sọ nipa iṣẹlẹ yii?

Gẹgẹ bi awọn ọlọpaa ṣe sọ, arabinrin kan ti orukọ rẹ n jẹ Rhoda Jatau; ẹni ogoji ọdun to n ṣiṣẹ lẹka iwosan nijọba ibilẹ Warji nipinlẹ naa lo fi ọrọ atẹjade naa si ori ayelujara.

Nnkan bii agogo mẹfa ku diẹ lawọn ọdọ naa bẹrẹ ikọlu naa ti ọlọpaa si ti ko awọn ọlọpaa kogberegbe sita lati dawọ wahala naa duro.

Àkọlé fídíò, 'FUJI níkan ni ‘beat’ tó jẹ́ àṣà wa, ‘Highlife’ kìí ṣe tiwa, kò sóhun tó jọ pé àwọn ọmọ Sàtání ló ń kọ Fuji Gospel'

Kọmiṣọna ọlọpaa ni ipinlẹ naa ti ke sawọn olugbe ipinlẹ naa lati maa ba iṣẹ oojọ wọn laisi hilahilo bi o tilẹ jẹ pe ọpọ lo ti ko aya soke ni ipinlẹ naa pẹlu ero pe iṣẹlẹ naa lee tubọ da omi alaafia ru ni ipinlẹ naa.

"Kọmiṣọna ọlọpaa ni ipinlẹ Bauchi tun rọ awọn aṣiwaju ẹsin gbogbo, awọn olori ileto atawọn agba majẹobajẹ nibẹ lati maa ba awọn ọdọ wọn sọrọ lati jawọ kuro lawọn iwa to le da omi alaafia ru lagbegbe wọn.

Awọn eeyan kan ni agbegbe Warji ni eeyan mẹta ni wọn yinbọn fun lasiko laasigbo to waye naa.

Wahala ẹsin to waye nipinlẹ Bauchi yii n waye lẹyin ọjọ diẹ ti irufẹ wahala ẹlẹsinjẹsin bẹẹ waye nilu Sokoto nibi ti awọn ọdọ kan ti sọ oko pa akẹkọọbinrin onipele keji nile ẹkọ olukọni agba Shehu Shagari College of Education nilu Sokoto ti wọn si tun da ina sun un lori ẹsun pe o sọrọ odi si aṣiwaju ẹsin Islam, Mohammed ninu ọrọ kan to sọ sori ayelujara.

Iku Deborah ati iṣẹlẹ to waye lẹyin rẹ ninu eyi ti fifi panpẹ ofin mu meji lara awọn to ṣeku paa, mu ki laasigbo waye eyi to mu ki ijọba ipinlẹ naa gbe isede kalẹ nibẹ.