Ìjóba Taliban ní òun kò fẹ́ kí àwọn obìrin máa ṣí ojú wọn sílẹ̀ mọ́ lórí tẹlifíṣọ̀nù

Oríṣun àwòrán, AFP
Ikọ Taliban ti paṣẹ fun awọn akọroyin lori ẹrọ amohunmaworan, lati ri pe wọn bo oju wọn lori afẹfẹ.
Agbẹnusọ ọlọpaa lori ọrọ ẹsin lo fi ikilọ naa lede fun awọn akọroyin.
Eyi n waye lẹyin ọsẹ meji ti wọn ti kọkọ paṣẹ pe gbogbo awọn obinrin gbọdọ maa wọ iboju ni ita gbangba abi ki wọn fi iya jẹ wọn.
- Mo ti ṣetán láti gba ìjọba lọ́wọ́ Makinde lọ́dún 2023 - Adebayo Adelabu
- Tea àti omi iyọ̀ ni èròjà tí orílẹ̀-èdè yìí fí n kojú ààrùn COVID-19
- A kò fi ti gbèdéke June 1 ṣe, a ti fòfin de ọ̀kadà, kèké ní Eko
- Oṣù mẹ́fà péré ni mo máa fi kojú Boko Haram bí mó bá dì ààrẹ Nàìjíríà - Hamza Al Mustapha
- "₦20,000 ló kàn mí lẹ́yìn tí a ja Iléeṣẹ́ rédíò Yinka Ayefele lólè ní Ibadan"
- Ki láwọn olóṣèlú Nàìjíríà rí tí wọ́n fi ń ṣé àbẹ̀wò sí ìyá arúgbó yìí ní Katsina?
- Alága ẹgbẹ́ ADP l’Ekiti ní òun kò ṣe ẹgbẹ́ mọ́ ṣáájú ìbò gómìnà l'óṣù Kẹfà
- “Ojú mi kòró báyìí ni àwọn ọ̀rẹ́ mi mẹ́ta kú sínú odò”
- Ikọ ajínigbé jí ìyàwó ọ̀sìngín gbé wọ́n f'ipá bá a lòpọ̀ làìmọye ìgbà, àṣírí tú!
Oriṣiriṣi ofin ni wọn fi de awọn obinrin to fi mọ pe wọn ko lee rin irinajo lai si ọkunrin ti yoo tẹle wọn, ti wọn ko si gba awọn obinrin laaye lati lọ sile ẹkọ.
Arabinrin akọroyin kan ti ko fẹ ki wọn darukọ rẹ ni ipaya ni eleyii jẹ fun awọn.
O ni "Ohun ti wọn n sọ ni pe ki a ma ṣiṣẹ ni oju ẹrọ amohunmaworan mọ''
''Nitori bawo ni mo ṣe fẹ ka iroyin pẹlu ẹnu mi ti wọn bo.''
''Mi o mọ ohun ti mo fẹ ṣ- nitori mo gbọdọ ṣiṣẹ, ẹmi ni mo n pese fun awọn ẹbi mi.''
Ọjọ kọkanlelogun, Oṣu Karun un, ni aṣẹ naa yoo gberasọ ni orilẹede naa.
Agbẹnusọ ileeṣẹ Taliban to paṣẹ naa ni imọran ni oun gba wọn, amọ ti ko si ẹni to mọ nkan to lee ṣẹlẹ si ẹni ti ko ba pa aṣẹ naa mọ.
Amọ awọn eniyan ti n bu ẹnu atẹ lu igbesẹ naa, ti awọn ajafẹtọ si n sọ wi pe iboju ti awọn eniyan n lo lati dẹkun ajakalẹ arun ni awọn Taliban n lo lati fofin de awọn eniyan pe wọn ko gbọdọ ṣe iṣẹ wọn bi iṣẹ, afi ki wọn boju wọn.
Igba akọkọ ti wọn kọkọ gbe igbeṣẹ naa ni ọdun 1990 ti wọn gba ijọba, ti wọn si paṣẹ pe gbogbo obinrin gbọdọ bo oju ati gbogbo ara wọn, eleyii ti wọn n pe ni Burka, ni gbangba.
Ọdun 2001 ni orilẹede Amẹrika le ikọ Taliban jade kuro lori oye , ti awọn aṣẹ wọn si rọlẹ diẹ ati awọn obinrin si bẹrẹ si ni ṣiṣẹ lori ẹrọ amohunmaworan.












