Musiliu Haruna Ishola: Ọmọ gbajúgbajà olórin Haruna Ishola mú BBC rìnrìnàjó sínú ìtàn ayé rẹ̀, ìbáṣepọ̀ òun àti bàbá rẹ̀

Àkọlé fídíò, Nígbà tí rẹ́kọ́ọ̀dù mí lókìkí kárí ayé, ẹ̀rù bà mí, mo ń ròó pé ọjọ́ ikú mi ti dé ni - Musiliu Haruna Isola

Odu ni Musiliu Ishola lagbo orin Apala oun si ni ọmọ bibi eekan ati agba olorin ti gbogbo aye mọ, Haruna Ishola.

Musiliu Ishola ba BBC Yoruba sọrọ, o ṣalaye iriri ati iyalẹnu rẹ pẹlu bi orin rẹ "Iṣẹ Oluwa" atawọn ọpọlọpọ mii ṣe jade sori igba to si burẹkẹ gidi gan.

O ni ẹru Ọlọrun ba oun koda, ko lee jade ninu ile. "Ṣe ni mo maa n woo pe emi kọ ni mo kọ orin naa, ẹru Ọlọrun ba mi koda mo tun roo pe abi ọjọ iku ti pe ni".

Musiliu tu kẹkẹ ọrọ nipa igbe aye rẹ, iṣẹ orin kikọ to yan laayo to fi mọ ibaṣepọ laarin oun ati baba rẹ to jẹ agba olorin ati awokọṣe rẹ.

Lafikun, Musiliu tun tan imọlẹ si awọn ahesọ ati awuyewuye to ni ṣe pẹlu boya oun lo ni aṣẹ fun awọn orin rẹ kan to kọ tabi oun kọ.

Musiliu Ishola, popular Apala musician and son of late legend of that music genre in Yorubaland, Haruna Ishola, "Kò sẹni to mọ mi, Haruna Ishola gangan ni wọn mọ amọ idi pataki tẹ o fi mọ mi, maa fun yin ni apẹlẹ mẹrin".

Musiliu ni oun kọ loun ṣagbekalẹ orukọ oun ti gbogbo aye mọ lonii bii awọn gbajumọ olorin mii.

"Èmí kọ́ ló ‘build’ orúkọ tí mò ń lò, wọ́n ti ṣé orúkọ yẹn sílẹ̀, iṣẹ tèmi níbẹ̀ ni pé mí ò jẹ́ kí orúkọ bàbá mi bàjẹ́".

Gbogbo agbaye ti mọ Musiliu Babatunde Haruna Ishola naa si Ọba orin Apala bayii ti Apala si ti di ẹka orin to wa da duro nitori iṣẹ takuntakun ti oun ati baba rẹ ṣe.

Lọdun 2020 ni orin rẹ to tan kari aye kari oko to tun gbilẹ kan "Soyoyo" jade.

Koda o ni orin Soyoyo ko kọkọ tẹ awọn lọrun ti awọn si ṣe atunṣe bii mẹrin amọ ko ṣi dara to ti akọkọ koda awọn to n ka orin silẹ ko fẹ baa ka a tori wọn ni ko sẹni to n kọ Apala mọ.

Musiliu ni awọn o mọ pe orin ọhun gaan ni Ọlọrun yoo jẹ ko burẹkẹ.