Ondo Comedian Prank: Wo àwàdà tí Eyinatayo Iluyomade, adẹ́rìnpòṣónú ṣé tí Adájọ fí ní kí wọn sọ ọ́ sí àhámọ́

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Adẹrinposonukan, Eyinatayo Iluyomade ti dero atimọle lẹyin ti o ṣe erekere kan gẹgẹ bi awọn ọlọpaa ipinlẹ Ondo ṣe sọ.
Wọn lo ṣe awada k'awada kan nipa ikọlu si ile ifowo pamọ kan.
Majistereeti Mosunmola Ikujuni lo paṣẹ ki wọn fi alawada naa si atimọle lọgba ẹwọn.
Iluyomade ẹni ọdun mọkandinlogun la gbọ pe wọn fsun kan pe o halẹ mọ ile ifowopamọ naa nipa kikọ iwe to si sọ sori kanta pe ikọlu fẹ waye nibẹ.
- Mọ̀ síi nípa àwọn aláwàdá Yorùbá tó ti dolóògbé ṣùgbọ́n tí ayé ṣì n pariwo wọn
- Dapo Abiodun faraya lẹ́yìn tí wọ́n ri Ireoluwa ti wọn jigbe l’Ogun
- Raila Odinga nìyí olùdíje ipò ààrẹ tó ti lulẹ̀ ní ìgbá márùn ún ọ̀tọ̀tọ̀ ní Kenya
- Mo pàṣẹ̀ ètò aàbò tó gbóòrìn ní gbogbo iléẹ̀kọ́, iléèwòsàn lásìkò yìí- Alkali olórí ọlọ́pàá Nàìjíríà
Ki lawọn ọlọpaa sọ?
Ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Ondo sọ pe ere gele ni nkan ti arakunrin yi ṣe.
Funmilayo Odunlami-Omisanya to gbẹnusọ fun ọlọpaa ni iṣẹlẹ naa waye lọjọ kọkandinlogun oṣu Keje ti Iluyomade kọwe si ile ifowopamọ.
''Arakunrin naa ju iwe to kọ si ile ifowopamọ naa to wa ladugbo Sabo wipe awọn adigunjale n bọwa si ibẹ''
O ni ''Iru erekere wo ni yẹn.Ni naa ni wọn ti gbe l si agọ ọlọpaa''
Titi pa lawọn ile ifowopamọ wa ni ọjọ naa
Ẹjọ naa waye nile ẹjọ lọjọ kẹẹdogun, oṣu Kẹjọ nibi ti wọn ti gbe lọ si ile ẹjọ majistireeti.
Olupẹjọ ọlọpaa Akao Moremi sọ fadajọ pe afurasi naa ju iwe to kọ silẹ ni ile ifowopamọ to si kọ sinu rẹ pe''laago kan lawọn adigunjale yoo wa si banki yi''
Moremi sọ pe iwe yi jẹ idunkoko mọ ile ifowopamọ naa ti eyi si mu ki awọn baki miran lagbegbe naa palẹmọ ẹru wọn lọjọ naa
Ṣugbọn agbẹjọro Iluyomade, Hawkins Akinnugba kọwe beere beeli fun alabara rẹ to si ni ko jẹbi sun ti wọn fi kan an.
O sọ pe '' igba akọkọ ree ti mo maa ṣe iru awada yi ni Ondo. Ko si ikọ adigunjale kankan to n bọ. Iwe lasan ni mo kọ''
Adajọ Mosunmola Ikujuni sunjọ siwaju lati gbẹjọ beeli ti arakunrin naa kọwe beere.














