William Ruto: Raila Odinga nìyí olùdíje ipò ààrẹ tó ti lulẹ̀ ní ìgbá márùn ún ọ̀tọ̀tọ̀ ní Kenya

Oríṣun àwòrán, AFP
Ljọ Aje ni ajọ eleto idibo Kenya kede William Ruto gẹgẹ bi aarẹ tuntun ti wọn ṣẹṣẹ dibo yan ni Kenya.
Ruto fi ajulọ han Raila Odinga, ẹni to ṣe ipo keji pẹlu ida mọkandinlaadta din diẹ ibo, 48.85%.
Tani Raila Odinga yii gan an na?
Agboole to lamilaaka ni Raila Odinga ti jade lorilẹede Kenya. Gbogbo ilakaka rẹ lati di aarẹ ṣaaju asiko yii lo si ti ja si pabo gẹgẹbi ilakaka baba rẹ pẹlu to figba kan ri di ipo igbakeji aarẹ mu, ṣe ja si pabo lẹyin ti wọn gba ominra lọwọ Gẹẹsi.
Ẹni ọdun mẹtadinlọgọrin ni Ọgbẹni Odinga. Igba karun si niyi to n dije fun ipo aarẹ lorilẹede Kenya. Ọdun 2008 lo sun mọ ipo naa julọ nigba ti wọn yan an gẹgẹ bii olotu ijọba labẹ eto ijọba ajumọṣe to waye nigba naa.
- Wọ́n ti kéde Wiliam Ruto ni aarẹ Kenya, wo bí èsì ìdìbò náà ṣe lọ níbí....
- Mọ̀ síi nípa àwọn aláwàdá Yorùbá tó ti dolóògbé ṣùgbọ́n tí ayé ṣì n pariwo wọn
- Kí ni ìdí tí ìjọba Gẹ̀ẹ́sì fí yà India àti Pakistan lọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ ní ọdún márùndínlọ́gọ́rin sẹ́yìn?
- Mo gbọ́dọ̀ ríi pé ọwọ́ tẹ̀ àwọn tọ pá Happiness MAPOLY, o tó gẹ́ ní Ogun- Gomina Dapo Abiodun
Ọpọlọpọ awọn ololufẹ rẹ lo maa n pe e ni "Baba", awọn miran maa n pe e ni "Agwambo" to tumọ si "Ifẹ Ọlọrun"; bẹẹni awọn miran maa n pe e ni "Tinga" to tumọ si "Katakata" gẹgẹbi ami idanimọ ẹgbẹ oṣelu rẹ lasiko idibo apapọ ọdun 1997.
Ololufẹ ẹgbẹ agbabọọlu Arsenal lorilẹede England ni Ọgbẹni Odinga. Gbogbo asiko eto idibo kọọkan to ba waye ni Ọgbẹni Odinga maa n da ẹgbẹ oṣelu tuntun silẹ. Lọtẹ yii, labẹ aṣia ẹgbẹ oṣelu Azimio la Umoja, Swahili for Pledge of Unity lo ti dije.
Awọn oloṣelu mejeeji to n dije fun ipo aarẹ lọdun yii ko ṣẹṣẹ maa woju ara wọn. Lati ọdun 2017 lawọn mejeeji ti di alatako ara wọn lagbo oṣelu, amọṣa wọn pari aawọ naa lọdun to tẹlee lasiko ti wọn bọ ara wọn lọwọ ni ita gbangba, eyi to gba gbogbo ilu kan nigba naa.

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Ileri ti Odinga n ṣe bayii ni pe oun yoo tẹsiwaju lori awọn iṣẹ ti aarẹ Kenyatta to n fi ipo silẹ ṣe nipa fifun awọn eeyan to ku diẹ kaato fun lorilẹede naa ni ẹgbẹrun mẹfa ṣile owo ilẹ Kenya eyi to ja si aadọta dọla owo ilẹ amẹrika tabi ogoji pọun owo ilẹ Gẹẹsi ($50; £40) loṣu labẹ eto imayedẹrun tuntun bi o ba de ipo aarẹ.
Ko si ẹni to lee sọ boya eyi lopin fun ilakaka rẹ lati di aarẹ orilẹede Kenya nitori pe o ti fi igba kan ri kede lọdun 2017 pe oun o ni dije mọ lẹyin idibo ọdun naa.
Odinga tun pa ohun da pe "awọn ọmọ orilẹede Kenya lo ke pe oun lati wa dije fun ipo aarẹ lẹẹkan sii nitori igbagbọ ti wọn ni ninu oun."
Minisita feto idajọ tẹlẹ, arabinrin Martha Karua ni Odinga yan gẹgẹbii igbakeji rẹ. Igba akọkọ si niyi ti oludije lorilẹede naa yoo yan obinrin gẹgẹ bi igbakeji rẹ.

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Raila Odinga ti ṣe ẹwọn ri gẹgẹbi baba rẹ Jaramogi Odinga toun pẹlu ṣẹwọn ọdun kan abọ ki wọn to da a silẹ lọdun 1971.
Raila Odinga ṣi ni ẹlẹwọn to pẹ julọ latimọle.
Ijijangbara rẹ tako eto iṣejọba ẹgbẹ oṣelu kan sọ ọ di ero atimọle laarin ọdun 1982 si 1988 ati lati ọdun 1989 si 1991 lasiko iṣejọba Aarẹ Daniel arap Moi to gba ijọba lẹyin Jomo Kenyatta.
Wọn ti kọkọ ran an lọ si ẹwọn lọdun 1982 lori ẹsun pe o gbiyanju lati ditẹ gba ijọba. Eyi gan lo fi i han fun agbaye, to si sọ ọ di ilumọọka.

Oríṣun àwòrán, AFP
Lọdun 2017, o padanu idibo aarẹ lorilẹede naa, eleyii ti Ọgbẹni Kenyatta ti bori. Amọṣa nigba to gbe ẹjọ naa lọsile ẹjọ, ile ẹjọ to ga julọ lorilẹede naa ile ẹjọ naa da esi ibo naa nu lori ẹsun pe aṣemaṣe pupọ waye.
Amọṣa lọdun 2018, ija pari laarin Odinga ati Ọgbẹni Kenyatta.
Ọgbẹni Odinga ni Aarẹ Kenyatta n ti lẹyin ninu idibo naa dipo William Ruto to jẹ igbakeji rẹ.
Odinga fẹ Mama Ida niyawo, wọn si bi ọmọ mẹrin , Fidel (to ti dagbere faye) Rosemary, Junior ati Winnie.
Ọmọ ìgbìmọ̀ ètò ìdìbò IEBC mẹ́rin yọwọ́ nínú ìkéde èsì ìbò ààrẹ lórílẹ̀èdè Kenya

Ọrọ di wọlukọlu nibudo esi idibo sipo aarẹ lorilẹede Kenya lọjọ Aje lẹyin ti awọn mẹrin ninu awọn ọmọ igbimọ eleto idibo orilẹede Kenya, IEBC sọ fun awọn akọroyin pe awọn ko lọwọ ninu esi idibo ti igbimọ naa fẹ kede faye.
Awọn Ọmọ igbimọ alamojuto idibo ilẹ Kenya, IEBC mẹrin ni wọn ti fariga pe awn ko le lọw si esi ibo aarẹ ti ajọ naa fẹ kede.

Ninu ipade kan ti wn ṣe pẹlu awọn oniroyin, awọn mẹrẹrin naa ọna bojuboju ti wọn gba n mojuto esi ibo naa lo fa igbesẹ awọn.
Ni bayii, awọn ọlọpaa kogberegbe ti wa ni ikalẹ kaakiri awọn ibi to ṣe koko lorilẹede naa bayii, paapaajulọ ilu Kisumu to jẹ agbegbe ti awọn ololufẹ Odinga pọ si julọ lorilẹede naa.
Awọn ọlọpaa naa ti n gbiyanju lati pẹtu si awọn araalu to ti n gbaradi lati ṣe iwde nibẹ lọkan.

Awọn eeyan naa fọn sigboro lẹyin ti awọn ẹgbẹ oṣelu to fọwọsowọpọ pẹlu Odinga sọ pe awọn n kẹẹfin pe awọn kan fẹ doju ibo naa ru.
Ọpọ awọn oluwde lo n wọde lagbegbe Kondele pẹlu patako alakọle pe awọn fẹ












