India vs Pakistan: Kí ni ìdí tí ìjọba Gẹ̀ẹ́sì fí yà India àti Pakistan lọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ ní ọdún márùndínlọ́gọ́rin sẹyin?

Aala ibode Pakistan ati India ni Waghar wa.

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Loṣu kẹjọ ọdun 1947 ni ilẹ Gẹẹsi fun orileede India ni ominira.

Agbegbe ti wọn ṣe ijọba le lori tẹlẹ yi wa pin si India ati orileede tuntun mii ti wọn pe orukọ rẹ ni Pakistan.

Lara Pakistan yi kanna lati ri iwọ oorun Pakistan to pada wa di orileede mii Bangladesh.

Ipinya yi ṣokunfa wahala nla eleyi to mu ki awọn eeyan to le fẹ ẹ to miliọnu mẹẹdogun di alainile ti awọn eeyan miliọnu kan si padanu ẹmi wọn.

Titi di oni, India ati Pakistan ko ba ara wọn rẹ.

Aworan afihan India ati Pakistan

Ki lo mu ipinya yi wa?

Ni 1946 ni ilẹ Gẹẹsi kede pe awọn fẹ fun India lominira. Wọn lawọn ko ni le dari ilẹ naa mọ ati pe awọn f kangara kuro ni kiakia.

Adari to wa nipo kẹyin Lord Louis Mountbatten da ọjọ Kẹẹdogun oṣu Kẹjọ 1947.

Ni igba taa n wi yi, ida marundinlọgbọn eeyan ilẹ naa jẹ musulumi. Awọn to pọju ninu awọn to ṣku si jẹ ẹlẹsin Hindu.

Ninu wọn la tun ti ri awọn ẹlẹsin Sikh, Buddha ati awọn miran.

Awọn olori ilẹ mejeeji nigba naa Jawaharlal Nehru ati Mohandas Gandhi fẹ orileede kanti yoo faaye gba gbogbo ẹsin

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Ọjọgbọn Navtej Purewal to jẹ onimọ ni ẹka iwadii Arts and Humanities Research Council sọ pe "Ilẹ Gẹẹsi fi ẹsin pin awọn eeyan India si ipele ọtọọtọ''

''Bi apẹrẹ,wọn ṣe agbekalẹ iwe orukọ awọn oludibo musulumi ati Hindu lọtọọtọ fawọn idibo abẹle.Wọn ya awọn ipo kan sọtọ fawọn oloṣelu musulumi ati awọn Hindu.Wọn lo ẹsin fi ṣe oṣelu'

Aworan awọn agbegbe ti wọn gbero ko wa labẹ akoso Pakistan

Ninu ọrọ alaye rẹ, ọjọgbọn Gareth Price ti Chatam House sọ pe ''Nigba to jọ pe India yoo gba ominira, pupọ awn musulumi bẹrẹ si ni jaya lori bi wọn yoo ṣe gbe nilẹ tawọn Hindu pọ si''

O fi kun pe ''wọn ro pe wọn ko ni ribi ṣe iṣẹmi tara wọn'' tori naa,''wọ bẹrẹ si ni ṣatilyin fẹgbẹ oṣelu to n polongo idasilẹ orileede musulumi''

Mohandas Gandhi ati Jawaharlal Nehru,awọn olori ipe ominira nigba naa lawọn fẹ India ti yoo faramọ gbogbo ẹsin.

Aworan awọn olori ilẹ Pakistan ati India nigba naa lọhun

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Ṣugbọn Muhammad Ali Jinnah to jẹ olori All India Muslim League beere fun iyasọtọ gẹgẹ bi adehun ominira.

Onimọ Price sọ pe ''Ọjọ yoo pẹ ki adehun to fẹnuko lori India kan ti yoo gba gbogbo ẹlẹsin''

''Iyasọtọ dabi ọna abayọ ti ko pẹ ti ko si mu wahala wa.''

Aworan awọn eeyan lasiko ikọlu

Oríṣun àwòrán, Huw Evans picture agency

Iru inira wo ni iyasọtọ yi mu wa?

Oṣiṣẹ ijọba ilẹ Gẹẹsi kan Sir Cyril Radcliffe lo ya ibode tuntun laarin India ati Pakistan lọdun 1947.

O ya ilẹ India si apa Guusu ati apa ariwa. Ni Guusu lawọn Hindu pọ si, apa meji ni iwọ oorunariwa ati ila oorun ariwa si lawọn musulumi pọ si.

Ṣugbọn awọn ileto musulumi ati Hindu wa kaakiri ni India ni.Eyi tunmọ si pe lẹyin iyasọtọ, o kere tan eeyan miliọnu mẹẹdogun lo rin lati sọda lọ si ibode ti wọn ṣẹṣẹ la yi.

Lọpọ igba ikọlu waye tawọn eeyan si le awọn mii kuro ni ile wọn. Apẹrẹ akọkọ ni ti eleyi to waye ni Calcutta ti wọn pa o kere tan ẹgbẹrun meji eeyan lọdun 1946.

Ọmọwe Eleanor Newbigin sọ pe awọn musulumi ati Hindu da ikọ ọmọ ogun silẹ.

''Awọn adunkoko mọni ẹgbẹ yi lo n le awọn eeyan kuro labule wọn ki wọn ba le gbalẹ si ọdọ ti wọn''

Sikh refugees dey chop free food for di ground for relief camp for Amritsar for 1947/1948.

Oríṣun àwòrán, Getty Images

O kere tan eeyan bi ẹgbẹrun lọna igba si miliọnu kan ni wọn lo ku nipa aarun tabi lawọn ibudo ti wọn ko atipo si.

Ẹgbẹgbẹrun obinrin, Hindu ati Musulumi ni wọn fipa ba lopọ, ji wọn gbẹ tabi ti wọn si ba loju jẹ

Kini ipa ti iyasọtọ yi ni?

Lati igba ti wọn ṣe iyasọtọ yi tan India ati Kashmir ko sinmi lati maa ja si agbegbe taa n pe ni Kashmir.

Ogun meji ọtọọtọ ni wọn ti koju ara wọn nitori agbegbe yi, ọkan lọdun 1947-1948 ati omiran ni ọdun 1965.

Bẹẹ wọn tun kọlu ara wọn ni 1999 ni Kargil lori ọrọ Kashmir yi naa.

Orileede mejeeji n sọ pe awọn lawọn ni agbegbe yi ti wọn si n ṣakoso awọn apa kan nibẹ lọtọọtọ.

Aworan afihan India ati Pakistan

Bakan naa India kogun ja Pakistan lọdun 1971 nigba ti wọn tẹnu bọ ọrọ atilẹyin ominira fun East Pakistan to pada wa di Bangladesh ko yapa kuro lọdọ Pakistan.

Ko to da meji ninu ida ọgọrun awọn ọmọ ilẹ Pakistan to jẹ ẹlẹsin Hindu nisinyi.

Ọmọwe Price sọ pe ''Pakistan ti n fojojumọ fara jọ orileede musulumi ''eyi ko si ṣẹyin pe ''musulumi lo pọ nibẹ tawọn perete ninu wọn si jẹ Hindu''

Bẹẹ India naa si ti n di orileede India bọjọ ṣe n gun ori ọjọ.

Aworan afihan ikọlu to ṣẹlẹ ni Amritsar ni ọdun 1947

Oríṣun àwòrán, Getty Images