Nàíjíríà: ‘Civil Defence’ yóò kún ológun lọ́wọ́ ní Zamfara

Ọmọogun Naijiria

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Àkọlé àwòrán, Awọn ọmọ ogun setan lati jẹwọ ara wọn nipinlẹ Zamfara

Ìjọba orílẹ̀-èdè Nàìjíríà tí kéde pé àwọn yóò ràn ikọ ọmọ ẹgbẹrun kan lọ sí ipinlẹ Zamfara láti kojú ìpeníjà awọn janduku agbebon.

Ìkéde ìgbésẹ náà jáde láti ilé iṣẹ Ààrẹ fikun pé àwọn ọmọ ogun orilẹ, ti òfurufú, ọlọpàá àti àjọ ojú lalakà fí n sọri yóò k'ọwọ rìn láti kojú awọn agbebon lagbegbe òun.

Garba Shehu to je agbẹnusọ fún Ààrẹ Buhari ṣàlàyé pé papakó òfurufú Katsina to súnmọ́ Zamfara ni àwọn ọmọ ogun òfurufú yóò ti má gbéra lọ si Zamfara.

Ìpeníjà àwọn agbebon nipinlẹ Zamfara jẹ òun ipaya fún àwọn èèyàn ibẹ pẹlú bí wọn ti ṣe n pá èèyàn tí wọn sì n ji dukia ati èèyàn gbe.

Lójó ẹtì ni awọn janduku agbebon òhun yà lù awọn abúlé kan ni ìpínlẹ̀ Zamfara, ti wọn sì pa èèyàn mejilelogoji nigba tí wọn kọlù abúlé méjìdínlógún láwọn ìjọba ìbílẹ̀ kan nipinlẹ naa.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ sí: