Tani ọkùnrin ọlọ́dẹ orí tí ayé ń pariwo kiri pé ó gba ìwòsàn ní Akure ni àná?

Akure iwosan okunrin to ni arun ọpọlọ

Iṣẹlẹ kayefi kan ṣẹlẹ nilu Akurẹ lọjọ Iṣẹgun nigba ti okiki kan pe arakunrin alaarun ọpọlọ kan gba iwosan nigba ti ojiṣẹ Ọlọrun kan gbọwọ le e.

Iṣẹlẹ naa, gẹgẹ bi akọroyin BBC ṣe fidi rẹ mu, waye lagbegbe Old Garage nilu Akurẹ.

Gẹgẹbi wọn ṣe fi to wa leti, arakunrin pasitọ naa ni ilu Eko ni oun ti wa ati pe oun ko mọ ẹnikẹni ri nilu Akurẹ.

Ta ni Arakunrin ọlọdẹ ori naa?

Ninu ọrọ to ba BBC News Yoruba sọ, arakunrin ọlọdẹ ori ti wọn ni o gba iwosan naa ṣalaye pe Dada ni orukọ oun, bẹẹni oun kẹkọgboye ijinlẹ ninu imọ nipa ẹrọ ayarabiaṣa Kọmputa ni fasiti imọẹrọ FUTA lọdun 2009.

Àkọlé fídíò, Ifọrọwerọ pẹlu obinrin Naijiria to n gbe Morocco

O ṣalaye siwaju sii pe ọmọ ilu Igbotako, lagbegbe Okitipupa loun amọ ko lee sọ ohun to ṣee to fi di ọlọdẹ ori.

Àkọlé fídíò, Emeritus Ayo Bamgbose: Ibánújẹ́ ni ojú yẹpẹrẹ tí ìjọba fi n wo olùkọ́ báyìí jẹ́ fún mi

Ki lawọn eeyan agbegbe naa sọ?

Nigba ti awọn kan ninu wọn n ba BBC sọrọ, awọn olugbe agbegbe naa ni o ti to ọdun diẹ ti arakunrin naa ti n rin gberegbere lagbegbe naa to si jẹ pe ninu ojo ati oorun ni yoo maa rin kiri ni ihoho lọpọ igba.

Àkọlé fídíò, Oba Francis Olusola Alao: Agbófinró, Fijilanté àti Amotekun ń gbìyànjú ṣùgbọ́n...

Awọn miran ni iyalẹnu lo jẹ fun awọn nitori pe lootọ ni arakunrin naa jẹ alanganna ti awọn si ti maa n rii lati ọpọ ọdun sẹyin.