Akọ̀ròyìn Zambia, Dingindaba Jonah Buyoya gbà àmì ẹ̀yẹ BBC Komla Dumor

Sọrọsọrọ lorilẹede Zambia Dingindaba Jonah Buyoya tí gba ami ẹyẹ BBC Komla Dumor.
Ẹni ọdun mẹedọgbọn lo di ẹni to kere julo to gba ami ẹyẹ naa lati igba ti wọn ti dasilẹ lọdun 2015.
O jẹ ẹni akọkọ tí yoo gba amí ẹyẹ lati guusu ile adulawọ.
Lọwọlowo o jẹ agbehonu si afẹfẹ lori Diamond telifisan lorilẹede Zambia níbi tí o ti bẹrẹ isẹ lọdun marun un sẹyin.
Ami ẹyẹ naa ni wọn dasilẹ lati fi ṣe iranti agbehonu safẹfẹ ile isẹ BBC, Komla Dumor, ẹni toku lọmọ ọdun mọkanlelogoji lọdun 2014.
Buyoya to tẹle awokọse Victoria Rubadiri, Solomon Serwanjja, Waihiga Mwaura, Amina Yuguda, Didi Akinyelure ati Nancy Kacungira.
Agbohunsafefe lati orilẹ-ede Ivory Coast Lindsay Aida Guei lo gba ipo kejì.
Akọroyin Zambia lo oṣu mẹta pẹlu ile ìsẹ BBC News ni London nibi ti yi o ti kẹkọọ kaakiri ẹka ileeṣẹ naa.
Lẹyin naa ni yoo lo ṣe idanilẹkọ lati ọdọ awọn aṣáájú Ọga agba ni ileeṣẹ BBC.
Buyoya lọ sí orilẹede adulawọ kan lati lọ ṣe isẹ royin tí yoo maa waye lori mohunmaworan BBC
"Gbigba ami ẹyẹ Komla Dumor lo jẹ ohun to dun mọ mi ninu pupọ.
Mọ ni i ọpọlọpọ iwuri lati ọdọ Komla nítorí lati kékeré ni mo ti fẹ di akọroyin.
"Mo maa wo awọn isẹ Komla lati tí fi ṣe muriwu fun mi."Inu mi dun lati darapọ mọ ilana ti Komla fi le lẹ.

Awọn adajọ gbe osuba fun Buyoya fun isẹ ribiribi to n ṣe ile adulawọ nipa ka gbe iroyin sori ayelujara. "A fi oju sọna lati ki Buyayo si arin wa ni BBC News
"inu wa dun si pupọ, ti a si nifẹ si ko tẹsiwaju lati ma ṣe idagbasoke pẹlu BBC News."
Ọga agba fun BBC Africa ni awọn iroyin ti ń Buyoya maa mu wa fun BBC lo jẹ awọn iroyin pataki ti awọn ololufẹ wa si nifẹ si pupọ















