Iléeṣẹ́ ọlọ́pàá Bornu tú àgùtàn tó ji ẹja díndín jẹ sílẹ̀

Agutan kan ti wọn gbe dani

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Ileeṣẹ ọlọpaa Bornu ti tu agutan ati ewure ti wọn mu si atimole tẹlẹ silẹ bayii.

Saaju ni wọn ko eranko yii lataari pe won ji ẹja dindin onisowo Yusuf Ibrahim ni Maiduguri to jẹ olu ilu ipinle Bornu.

Won ni pe wọn tu agutan naa sile leyin ti Yussuf sọ pe oun ti dariji i.

To si sọ pe ki agọ ọlọpaa Bulabulin tu agutan naa sile fun olowo rẹ.

Saaju ni iroyin kan sọ pe ogbeni Hussain Monguno to je ọkan lara awọn ikọ olupolongo ẹgbẹ APc ti fun oniṣowo naa ni aadọta egbẹrun naira pe o kuu suuru fun ọdun marun un to ti n wo awọn agutan to n ji ẹja didndin rẹ jẹ niran.

Bakan naa lo parọwa fun awọn to n sin ẹran ọsin lati maa bọ wọn daadaa ki wọn ma baa maa ba nkan awọn eeyan mi jẹ ni adugbo.

Àgùtàn di èrò àtímọ́lé ọlọ́pàá lẹ́yìn tó jẹ ẹja díndín lórí igbá onígbá

Ileeṣẹ ọlọpaa nipinlẹ Borno ti fi àgùtàn kan ati ọmọ rẹ meji si ahamọ, fun ẹsun pe wọn jẹ ẹja dindin ti oniṣowo kan fẹ ẹ ta nilu Bulabulin.

Iroyin sọ pe awọn ọlọpaa mu awọn agutan naa lẹyin ti oniṣowo ọhun, Yusuf Ibrahim, fi ẹjọ sun ni agọ ọlọpaa.

Ọgbẹni Ibrahim n ta ẹja dindin ni opopona nla kan ni ilu naa ti ko fi bẹẹ jina si ilu Maiduguri.

Iwe iroyin The Cable jabọ pe Ọgbẹni Ibrahim sọ fun awọn ọlọpaa pe fun ọpọlọpọ ọdun ni awọn agutan naa ti n pa oun lara, pẹlu bi wọn ṣe ma n gbe ẹja oun jẹ lori igbá.

“Awọn agutan yii ma n duro si kọrọ lati ṣọ́ igba ti ma a gboju kuro lara ọja mi. Ni kete ti wọn ba si ti ri pe mi o wo ibẹ ni wọn o sare gbe ẹja.

“O di igba ti oju mi ba to pada sibi ẹja tabi ti ẹni to n kọja lọ tabi duro nitosi ba le wọn ki wọn o to o kuro.”

Ibrahim ṣalaye pe fun ọdun marun-un ni oun ti n fi ara da iwa ọdaran ti agutan naa n hu, amọ eyi to ṣe ni ọjọ Satide ko oun si gbese nla, ti oun ko le fi oju fò.

O ni ọpọ igba ni oun ti bẹ ẹni to ni agutan naa pe ko so ẹran rẹ mọlẹ, ko si ma a fun ni ounjẹ, “amọ ko gbe igbesẹ kankan”.

Ẹni to ni agutan naa, Luba Mohammed sọ fun awọn akọroyin pe iyalẹnu lo jẹ, nigba ti agutan oun deede bẹrẹ si ni fẹran ẹja dindin.

Arabinrin Mohammed sọ pe lootọ ni Ibrahim ẹlẹja ti fi ẹjọ sun oun ni ọpọ igba, nipa bi agutan oun ṣe n ko o si gbese.

“Mo ma n bẹbẹ ni gbogbo igba naa, pẹlu ileri fun pe ma a wa nkan ṣe si – boya ki n pa a, so o mọlẹ, tabi ki n ta a .”

Amọ agbẹnusọ ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Borno, Kamiludeen Sani ko tii sọ ohunkohun lori iṣẹlẹ naa.